UK, Europe, US, Canada: Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọkọ̀ ayókẹ́lẹ́ ló ti rì sàbẹ̀ yìnyín

O kere tan eniyan mọkanlelogun lo ti gbe ẹmi mi latari otutu ati yinyin arọọrọda, iru eleyi ti wọn ko ti ri ri lati bi ogun ọdun sẹhin to gbalẹ kan ni ilẹ Amerika.

Ile iwosan kaakiri ni wọn ti n toju awọn ti otutu ati yinyin ti fa aisan si lara bayii.

Bakan naa, ni Ilẹ Gẹẹsi, ni se ni yinyin bo gbogbo ọkọ ayọkẹlẹ, ti ko si ẹni ti o le jade sita ju igba diẹ lọ.

Oju ọjọ naa ti fa ki wọn da ọkọ ofurufu duro lati ma se isẹ, bẹẹ si ni wọn ti ọgọọrọ ile iwe pa, eleyii ti o dina awọn eniyan lati ma le e lọ lati ibi kan si ibomiran.

Iroyin ni ọsẹẹsẹ ki otutu yii posi, nitori idinwọn fun bi oju ọjọ yoo se ri fihan wi pe, yoo ma tutu si ni lasiko ti awa yii.