You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sowore: olùdíje Ààrẹ tó loun fẹ gbà Nàìjíríà padà fún àwọn ọdọ
Ṣaṣa ni ọmọ Naijiria ti on fi ọkan tele awọn isẹlẹ lori ẹrọ ayelujara ti ko ti gbọ nipa Sahara Reporters.
Ile isẹ iroyin naa ti wọn da silẹ ninu iyara kolobo kan ni ilu Manhattan lọdun 2006 wa lati koju awọn iwa ibaje ni eto isejọba Naijiria.
Omoyele Sowore, ọmọ ọdun mẹ́tàdínláàdọ́ta to n du ipo Aarẹ lorileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu African Action Congress (AAC) ni oludasilẹ ile iṣẹ iroyin naa.
Ọjọ kẹẹdọgbọn, Oṣu keji, 2018 ni o kede erongba rẹ lati du ipo Aarẹ orileede Naijiria ṣugbọn saaju igba naa ni o ti n dasi oselu Naijiria.
Lati kekere ni aisedede ti o n waye lawujọ ti jẹ nnkan to n kan ni ominu.
Nitori pe o wa lati idile olorogun,titiraka lati pese ijẹ imu jẹ ohun ti o ti n ba finra tipe ti eyi si mu ki o pinu lati ri wi pe ohun lo gbogbo ọna lati mu iyipada ba awujọ.
Lọdun 1989 o kopa ninu iwọde awọn akẹkọ fasiti ilu Eko(Unilag) eleyi ti awọn akẹkọ ṣe lati tako awọn gbedeke to rọmọ owo iya ọgọfa miliọnu ti ijọba fẹ gba lọwọ ile ifowopamọ agbaye nii IMF.
Lara ohun to rọ mọ owo iya yi ni ki ijọba mu adinku ba iye ile ẹko fasiti to wa ni Naijiria lati mejidinlọgbọ si maarun.
Awọn to mọ Soworẹ ni bi ọrọ ba niiṣe pẹlu jija fun ẹtọ omoniyan,Sowore kii gbeyin.
Awọn to wa lori alefa nigba ti Naijiria wa labẹ Ijọba ologun mọ Sowore bi ẹ ni mọ owo fun bi o ti ṣe ma n le iwaju ninu awọn iwọde to n tako isejọba ologun.
Bo je ni ọdun 1992 ti wọn fi si ahamọ fun pe o kopa ninu iwọde ti awọn ọlọpa ti yinbọn pa eeyan meje tabi lodun 1993 to lewaju nigba iwode idibo June 12,Sowore kii ṣe ẹran rirọ ti awọn alaṣẹ le fọwọrọ sẹgbẹ.
Ilakaka rẹ ninu jija fun ẹtọ ọmọniyan wa lara awọn ohun to mu ki awọn eeyan Naijiria lero wi pe yoo jẹ Aare ti o le ni aanu mẹkunu loju.
Ẹnu lasan ati akatakiti ko to ṣe oselu Naijiria
Agbẹjọro Gani Fawehinmi ati Fela Anikulapo Kuti jẹ awọn to ti saaju gbe iru igbese ti Sowore n gbe yi sugbọn ti wọn ko ribi ruu ja.
Ọrọ naa le koro leti ṣugbọn ootọ ibẹ ni wi pe: oselu Naijiria ko dẹrun lati kopa fun ẹni ti ko ba ni Baba isalẹ lẹyin tabi ti ko ni owo ti yoo fi du ipo.
Koda a ti ri awọn to lowo ti gbogbo aye si gba ti wọn bi MKO Abiola ti ko ri bi de ipo Aarẹ.
Ki wa ni Sowore n sọ to le mu ki awọn ara ilu gba ti ẹ?
Ọpọ nnkan ti Sowore n sọ ninu awọn ifọrowanilẹnuwọ jọ bi ẹ ni wi pe ti oba de ori alefa,yoo gba gbogbo awọn agbagba oloselu si ẹgbẹ kan ti yoo si fi isejọba ọdọ rinlẹ.
Ohun ti awọn kan fẹ ni iru erongba yi sugbọn gẹgẹ bi a ti ṣe sọ saaju, ẹnu lasan ko ni le ṣe ni orileede Naijiria nibi ti awọn ẹgbẹ oselu bi PDP ati APC ti fẹsẹ rinlẹ gidigba.
Sowore ati awọn alatilẹyin rẹ ko sọ ireti nuu ti wọ́n si gbagbo wi pe ọ́dun 2019 yoo jẹ ọdun ti awọn ọdọ Naijiria yoo kopa ribiribi ni isejọba.
Awọn nnkan marun miran ti ẹ ko mọ nipa Sowore
-O ti sa ere ọlọgbọnrangandan (Marathon) mẹjọ lẹnu igba ti o daye
-Sowore gbagbo wi pe ẹtọ gbogbo obinrin ni ki wọn di ipo oselu mu.
-O ni ohun yoo sapa bi Naijiria yoo ti ṣe ma ta igbo lọ si ilẹ okere lati le mu ọrọ aje Naijiria gboro si.
-Ẹgberun lọna ọgorun Naira lo ni ohun yoo ma san fun awọn agunbanirọ ti wọn ba yan ohun gẹgẹ bi Aarẹ