Ondo rape apologist: Olùkọ́ kan di èrò ọgbà ẹ̀wọ̀n fún fífipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá lòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ile ẹjọ giga kan ni ilu Akure nipinlẹ Ondo, ti dajọ ẹwọn gbere fun olukọ kan, Omotayo Adanlawo fun ẹsun ifipabanilopọ.

Wọn fi ẹsun kan Adanlawo pe o fi ipa ba ọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹwaa, to jẹ ti oludasilẹ ṣọọṣi to n lọ lopọ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2018 ni ile awọn obi rẹ ni Iju, nipinlẹ Ọndo.

Iroyin sọ pe Adanlawọ lọ si ile awọn obi ọmọ naa, lasiko ti awọn ẹgbọn rẹ ati obi rẹ ti lọ si oko, to si fi tipatipa ba a lopọ.

Lẹyin naa lo kilọ fun un pe ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni, ti ko ba fẹ ẹ ku.

A gbọ pe inu rirun ati bi ọmọ naa ko ṣe le rin daadaa, lo mu ki iya rẹ gbe e lọ sileewosan fun ayẹwo, ki aṣiri o to o tu pe wọn fi ipa ba lopọ ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Adanlawo ti kọkọ kọ ọ silẹ ni agọ ọlọpaa to wa nilu Iju-Itaogbolu ti wọn gbe e lọ pe ọmọdebinrin naa sọ fun oun pe ki oun sun le e lori, lẹyin to beere fun aadọta Naira ati nkan ipanu.

Ṣugbọn ọrọ rẹ tako eyi niwaju ile ẹjọ, to si sọ pe ile oun ni oun wa lasiko ti wọn ni oun ṣẹ ẹṣẹ naa.

Bakan naa lo tun sọ pe aarun ìpá n ba oun finra, eyi to tumọ si pe oun ko le ba ẹnikẹni ni ibalopọ.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Samuel Bola sọ pe ẹri ọmọdebinrin naa niwaju ile ẹjọ mudadoko, lai fi ọjọ ori rẹ ṣe, amọ ti Adanlawọ ko ri ẹri mu wa sile ẹjọ pe lootọ ni o ni aarun , tabi pe ile ara rẹ lo wa lasiko iṣẹlẹ naa.

Yatọ si ọmọdebinrin naa, iya rẹ, dokita to ṣe ayẹwo fun ati ọlọpaa meji, lo tun jẹri tako Adanlawọ nile ẹjọ.

Amofin Agba to tun jẹ kọmisanna fun eto idajọ nipinlẹ Ondo, Adekola Olawoye sọ pe idajọ na fihan pe ìlú ko ni fi ara rọ fun awọn to n fi ipa ba ọmọde lopọ nipinlẹ naa

Iru idajọ yii ni ikeji to waye laarin ọsẹ kan ni ipinlẹ Ondo.

Ṣaaju ni eyi ti kọkọ ṣẹlẹ ni Ondo:

Dẹ́rẹ́bà kẹ̀kẹ́ Maruwa rí ẹ̀wọ̀n gbére he lẹ̀yìn tó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀

Ile ẹjọ giga to wa nilu Akure ti sọ awakọ Kẹkẹ Maruwa kan ṣewọn gbere lẹyin to jẹbi ẹsun fifi ipa ba ọmọ ọdun mẹrinla lopọ, to si tun fun ni arun jẹdọjẹdọ.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Bode Adegbehingbe ṣe idajọ ọkunrin naa lẹyin ọdun mẹji ti ẹjọ ọhun ti wa niwaju rẹ.

Iroyin ni ọmọ ọdun mẹrinla naa n bọ lati ile iya-iya rẹ lọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2018 ni ilu Ondo nigba to pade ọdanran ọhun, Blessing Kingsley, to jẹ alabagbe wọn.

Kingsley ni oun yoo gbe ọmọ naa lọ sile awọn obi rẹ, ṣugbọn kaka ko ṣe bẹẹ ile ara rẹ lo gbe e lọ nibi to ti fi ipa ba lopọ.

Ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn ẹbi ọmọ ọhun fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti ni agọ ọlọpaa to wa ni Funmbi Fagun ni ilu Ondo, ti iwadii si fihan pe, wọn ti ba ọmọ naa lo, ati pe o ti fara kasa arun jẹdọjẹdọ.

Lẹyin naa ni wọn fi panpẹ ofin mu Kingsley, to si foju bale ẹjọ labẹ ofin to rọ mọ iwa ọdaran ti wọn gbe kalẹ lọdun 2006.

Ọdaran naa lo ṣe ẹlẹrii ara rẹ nile ẹjọ, nigba ti awọn olupẹjọ gbe ẹlẹrii mẹrin kalẹ.

Bẹẹ naa ni awọn olupẹjọ tun mu awọtẹlẹ ọmọ naa ti ẹjẹ wa lara rẹ, atawọn nnkan miran wa siwaju adajọ fun ẹri.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ Bode Adegbehingbe ni ẹri fi han pe Kingsley jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, lẹyin naa lo ni ko lọ faṣọ penpe roko ọba titi lai.