Lebanon Explosion: Ibùdó tí igba èèyàn ti kú lóṣù kẹjọ ní iná míràn ti jó

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ijamba ina alagbara miran tun ti waye ni papakọ oju omi to wa nilu Beirut lorilẹede Lebanon.

Isẹlẹ ina naa, ti wọn ko tii sọ ohun to fa a, lo waye lẹyin ina alagbara to sẹlẹ nibẹ lọjọ kẹrin osu Kẹjọ ọdun 2020.

Ikọ alagbelebu pupa tilu Beirut ni ko sẹni to fara pa tabi ku ninu ijamba ina naa amọ awọn eeyan kan, to sun mọ ina naa, ko le mi daadaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijamba ina ọhun lo tun waye ni ibudo yii kannaa, ti ẹmi to to mọkanlelaadọwa ti bọ losu to kọja nigba ti ibugbamu kan waye ni ibudokọ oju omi naa.

'Àwa ọmọ Nàìjíríà tó farapa fẹ́ wálé láti Lebanon, ìjọba kó wa pamọ́'

Awọn alaṣẹ ijọba Lebanon ti da ọmọ Naijiria marun un pada ki wọn ma lee ririnajo jade pẹlu ọkọ ofurufu ti ijọba Naijiria pese pe ko lọ gbe wọn ni ọjọ kejila, oṣu kẹj,ọ ọdun 2020.

Ọkan lara wọn, Nkiru Obasi to wa lati ipinlẹ Ebonyi nila oorun guusu lorilẹ-ede Naijiria to n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ ni Lebanon.

"Ibugbamu nla to waye ni Lebanon sọ mi soke janto, mo ri ọpọlọpọ oku nilẹ", ohun ti ọmọ Naijiria kan to moribọ sọ ree.

Ninu ọrọ to fi ranṣẹ si BBC, Nkiru to farapa ninu ibugbamu Beirut eyi to mu ẹmi awọn to le lọgọrun un lọ sọ pe ṣe ni wọn ti oun atawọn mẹrin mii mọ inu yara kan ti wọn ko jẹ kawọn ba ọkọ baalu wa si Naijiria toripe wọn ni ọga Madaamu awọn wa fi ẹjọ awọn sun.

Nkiru ni: "Bi a ṣe de papakọ ofurufu lati lọ wọ baalu ti ijọba ṣeto ni wọn ni awọn ko ni faaye gba wa, awa marun, wọn ni Madaamu wa wa fi ẹjọ wa sun toripe a kuro nile.

Ni wọn ba ni awọn ko ni gba wa laaye ti wọn si n ju ẹru wa nu."

O fi ohun aro ranṣẹ pe: "Bi ẹ ko ba gburoo mi mọ ki ẹ mọ pe wọn ti sọ mi sẹwọn, bi ẹ ko ba gburo mi mọ, ki ọ mọ pe wọn ti gba gbogbo nkan lọwọ mi ti wọn si ti ti mi pẹlu gbogbo bi mọ ṣe farapa mọ atimọle".

Nkiru ni oun kuro nilee Madaamu toripe ko san owo oṣu oun latọjọ yii ni.

Ẹwẹ, aṣoju Naijiria ni Lebanon, Goni Modu sọ fun BBC pe awọn mọ nipa iṣẹlẹ naa awọn si n gbiyanju lati yanju ẹ.

Ambasadọ Goni to ni eyi kii ṣe igba akọkọ ti iru iṣẹlẹ ki Ọga Madaamu wọn wa maa fi ẹjọ sun.

Iṣẹlẹ Ibugbamu Beirut yii waye lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kogba wọle lọ yii ti o si le leeyan igba to ku ati o le lọgọrun to sọnu to fi mọ ẹgbẹgbẹrun to di alairilegbe.

Awọn onimọ sọ pe ibugbamu yii yoo ṣi fun Lebanon, orilẹede to ṣi n tiraka pẹlu ọrọ aje mọ ẹgbẹ kan ti awọn ọmọ ọdọ yoo si ni lati fara mọ atunbọtan rẹ.

Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200

Awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Lebanon ti kọwe fipo silẹ laarin ọpọlọpọ irunu ati ibinu awọn araalu nitori bugbamu nla to waye lọjọ iṣẹgun ọsẹ to kọja eyi to ba nkan jẹ kọja afẹnusọ ni ilẹ Beirut to si tun mu ẹmi eniyan to le nigba lọ.

Ikede pe wọn fiṣẹ silẹ yii jade lorii tẹlifisan apapọ orilẹede naa nirọlẹ ọjọ aje.

Ọpọlọpọ eniyan lo ti n da ẹbi iṣẹlẹ naa ru awọn adari orilẹede ọhun pe wọn ko kọbiara si ilu ati pe iwa ọbayejẹ wọ wọn lẹwu.Awọn afẹhonu han ti tu sigboro fun odidi ọjọ meji bayii lai simi nitori ibugbamu naa.Aarẹ Lebanon ti ṣaaju sọ pe ohun to fa sababi ibugbamu ọhun ni ibugbamu nkan oloro toonu ammonium nitrate to fẹrẹẹ to ẹgbẹrun mẹta (2,750) ti wọn ko pamọ lọna aitọ fun ọpọlọpọ ọdun.

Ó lé ní ìgbà ènìyàn lo ti ṣe ódìgbà ó ṣe sí dúníyàn lẹ́yìn ìbúgbàmù Beruit.

Gómìnà Beruit lo fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ pé ìbúgbàmù ọjọ́ Iṣẹ́gun tó kọjá ti pa ènìyàn igba.

Marwan Abboud sọ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n ko tilẹ̀ rí mọ́ títí di àsìkò yìí, ti ọ̀pọ̀ sì jẹ́ àwọn àjòjì tó wá ṣiṣẹ́ ni Lebanon.

Alẹ́ ọjọ́ Àìkú ní àwọn ọmọ Lebanon tún bẹ́rẹ̀ ìfẹ̀hhónú hàn míràn ní olúùlùú Beruit tí àwọn àti ọlọ́pàá sì ń kojú ara wọ́n.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ń bínu sí ìhà ti àwọn ìjọba ń kọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ to wáyé náà.

Síbẹ̀, bí mínísítà fún ètò ìdájọ tó jẹ́ mínísítà kẹ̀ta ṣe tún kọ̀wé fipò sílẹ̀, kò mú àdínkù bá ìbínú àwọn ará ìlú.

Ní báyìí, wọ́n tún ti kéde pé kí àwọn ènìyàn jáde láti ní ọ̀sán òní ọjọ́ Ajé lásìkò ti aṣojú ìjọba ilọ̀ Lebanon, Hassan Diab yóò máá pe ìpàdè ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba Lebanon.

Ọ̀gbẹ́ni Diab ti sàlàyé pé ìbígbàmù náà wáye nítori àwọn èròjà tó dín díẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún méjì tóònù ti wọ́n kó pamọ si ibùdókọ̀ ojú omi fún ọdún mẹ́fàá ló fàá.

Ìyàlẹ́nu ló jọ́ fún ọ̀pọ̀ ọmọ Lebanon pé ìjọba kó àwọn èròjà olóró sí ìgboro Beruit, bótilẹ̀ jẹ́ pé, o ti pẹ́ ti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà ti ń nànka àláebù sí àwọn olóṣèlú, fún ìwà àjẹbánu, àìbìkítà àti síṣẹ́ ǹkan ìlú báṣubàṣu tí wọ́n tí ń ṣe látẹ̀yìn wá.

Beirut Port Explosion: Àwọn adarí lágbàyé ṣèpàdé láti ṣèrànwọ́ fún Lebanon lẹ́yìn ìbúgbàmù tó pa ènìyàn 158

Awọn adari lagbaye yoo ṣe ipade loni lati jiroro lori bi wọn yoo ṣe da owo jọ fun orilẹ-ede Lẹbanon ti ibugbamu ba ọpọlọpọ nkan jẹ nibẹ.

Ipade naa ti yoo waye ni aago mejila ọsan oni lori ẹrọ ayelujara ni Ajọ Iṣọkan Agbaye, (UN ) gbe kalẹ.

Aarẹ orilẹ-ede Faranse, Emmanuel Macron lo kọkọ ṣe ipolongo rẹ pe ipade yoo waye lati da owo iranwọ fun orilẹ-ede Lebanon.

Awọn asoju lati Ajọ Isọkan ilẹ Yuroopu EU, China, Russia, Egypt, Jordan ati Ilẹ Gẹẹsi, UK ni yoo darapọ mọ ipade naa.

Aarẹ orilẹ-ede America, Donald Trump ti ṣeleri lati darapọ mọ ipade naa.

Bakan naa ni Aarẹ Trump ni awọn ti ran awọn dokita lati ilẹ America pẹlu iranwọ ounjẹ, omi mimu ati oogun oyinbo lati ran orilẹ-ede Lebanon lọwọ lasiko yii.

Ijọba Lebanon fi lede pe iye nkan ti ibugbamu to waye ni ibi ile ti wọn ko ado oloro ammonium nitrate naa bajẹ yoo lẹ ni iye owo biliọnu marundinlogun lọ.

Eniyan 158 lo ku ninu iṣẹlẹ ibugbamu naa, ti èniyan 5,000 si farapa nigba ti èniyan 3000 ko ri ile gbe nitori iṣẹlẹ ohun.

Ni Ọjọ Satide lorilẹ-ede Lẹbanon, ẹgbẹlẹgbẹ eniyan lo korajọ lati fẹhonuhan takọ aibikita ijọba si iṣẹlẹ to waye naa.

Awọn ọlọpaa da ifẹhọnuhan naa ru, ti wọn si fẹ afẹfẹ gaasi tajutaju si awọn eniyan to n fẹhọnuhan naa.

Ninu ọrọ tirẹ, Olotu Ijọba orilẹ-ede Lebanon, Hassan Diab ti ni oun yoo pe fun eto idibo ni kiakia, gẹgẹ bi ọna abayọ si rogbodiyan ti ibugbamu naa da silẹ.

Orilẹede Lebanon lo ṣi n koju ọrọ aje to dẹnukọlẹ ati arun Coronavirus to n ba wọn finra ki ibugbamu naa to waye.

Ẹ wo ìrírí aláboyún tó ń rọbí lọ́wọ́ lásìkò ìbúgbàmù tó wáyé ní Lebanon

Arabinrin Emmanuelle n gbaradi lati bi ọmọ tuntun ni ile iwosan St George's ni ilu Beirut nigba ti ibugbamu naa ṣẹlẹ.

O le ni ọgọrun eniyan to ku ninu iṣẹlẹ naa, ti eniyan to le ni ẹgbẹrun mẹrin si farapa.

Ọkọ arabinrin to n rọbi naa, Edmond sọ iriri rẹ fun Ileeṣẹ Iroyin BBC ati bi o ṣe ṣẹlẹ.

'Wọn n gbe iyawo mi lọ si yara irọbi lọwọ ni, ti awọn dokita ati nọọsi si n pese ibusun rẹ lọwọ ni awọn gbọ irọ igbugbamu to rin ilẹ.'

'Bi ibugbamu naa ṣe ṣẹlẹ, ti gbogbo gilaasi ferese ati ti orule si fọ, ni mo bẹrẹ si ni wa iyawo mi to n rọbi lọwọ.'

'Ẹru bami, nitori mo ro wi pe iyawo mi ti farapa tabi ọmọ jojolo naa.'

'Ohun gbogbo to wa ni bẹ lo danu ati ohun elo wọn, ko si si ohun kankan to ku mọ.'

'Ohun ti mo kọkọ ṣe ni lati gbe ibusun iyawo mi sita, ti mo si bẹrẹ si ni ran awọn dokita ati nọọsi lọwọ.'

'Iru ba iyawo mi to n rọbi lọwọ, bẹẹ si ni ko si oogun fun un.

'Ọna aye atijọ ni wọn gba lati gbẹbi iyawo mi nitori ko si ohun elo kankan lati lo.'

Ọḳ iyawo naa fikun pe lẹyin wakati kan abo ti ibugbamu naa waye ni iyawo rẹ, Emmanuelle bi ọmọ tuntun, George.

Bẹẹ si ni o dupẹ pẹ iya ati ọmọ tuntun naa wa ni alaafia, ti ara wọn si mokun.

Ẹ kó àwọn aláṣẹ ibùdó ìkẹ́rùsí Beirut tó búgbàmù sáhàámọ́ - Ìjọba Lebanon pàṣẹ

Awọn alaṣẹ ibudo ikẹru si ti ibugbamu ti waye ni Beirut ti wa ni ahamọ.

Gẹgẹ bi ohun ti BBC ri ko jọ, wọn ni ki wọn maa wa ni ahamọ nile wọn titi di igba ti iwadii yoo fi bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa ibugbamu ọjọ Iṣẹgun.

O kere tan eeyan marundinlogoje lo ti ku ninu iṣẹlẹ naa ti awọn to le ni ẹgbẹrun mẹrin si ti farapa.

Aarẹ Michel Aoun sọ pe, tọọnu nkan abugbamu ammonium nitrate to le l'ẹgbẹrun meji (2,750), ti wọn ko pamọ lọna ti ko tọ si ibudo ikẹru si, lati bi ọdun mẹfa, lo fa ibugbamu naa.

Ọga agba awọn oṣiṣẹ aṣọbode Badri Daher sọ pe awọn ti ke gbajare ki wọn wa gbe kẹmika to bu gbamu naa kuro laimọye igba ''ṣugbọn wọn ko wa''

O ni awọn yoo ma reti ababọ awọn onimọ nipa ohun to ṣẹlẹ gaan.

Lasiko to n dari ipade pajawiri kan lorileede naa, aarẹ Aoun ni ''eeyan ko le ṣe apejuwe iru ajalu nla to rọlu ilu Beirut eyi to ti da ibẹrubojo silẹ nibẹ''

Awọn onimọ ni fasiti Sheffield nilẹ Gẹẹsi sọ pe bi eeyan ba foju sun, ibugbamu Beirut lagbara ni iwọn igba ida mẹwa ninu ọgọrun ibugbamu Atomic Bomb ti orileede Japan ju lu Hiroshima.

Àlàyé rèé lórí ohun tó ṣe okùnfà ibugbamu ní Beirut

Inu ọfọ nla ni awọn eeyan orilẹ-ede Lebanon wa lẹyin ibugbamu nla to waye ni olu ilu orilẹ-ede naa, Beirut lọjọ Iṣẹgun.

Eeyan bi ọgọrun lo ku, awọn to le ni ẹgbẹrun mẹrin si fi ara pa.

N ṣe ni gbogbo ilu naa mi titi nitori ibugbamu ọhun, to bẹrẹ pẹlu ina ni ebute okun kan.

Ki i gan ni eroja ammonium nitrate to fa ilẹ ya bẹ ẹ?

Oriṣiriṣi iwulo ni ammonium nitrate ni, ṣugbọn meji to wọpọ julọ ni pe, wọn ma n lo o lati fi ṣe eroja Ajilẹ fun iṣẹ agbẹ, ati bii eroja abugbamu.

Oro inu rẹ l'agbara pupọ, to si ma n bugbamu to ba fi ara kan ina - to ba si ti bugbamu tan, ammonium nitrate ma n fọn afẹfẹ gaasi oloro nitrogen oxides ati ammonia gas sita.

Nitori eyi lo ṣe ni awọn ilana to yẹ ki ẹnikẹni to ba fẹ ẹ ko pamọ tẹle.

Lara awọn ilana naa ni pe, wọn gbọdọ fi eroja ti ko le jona kọ ibi ti wọn ba fẹ ẹ ko si, ko si gbọdọ si nkan to jọ gọta, ọpa to n gbe nkan, tabi awọn ọna miran ti o le ṣan si.

Iroyin sọ pe, ẹgbẹrun meji le díẹ̀ tọọnu ammonium nitrate to gbana yii jẹ ti ẹnikan, to fẹ ẹ ko ranṣẹ si ilẹ okeere lọdun 2014, ṣugbọn tí ijọba gbẹsẹ le e.

Wọn gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ, ẹjọ naa si wa ni kootu titi di asiko ti ibugbamu waye ni nnkan bi aago mẹta ọsan lọjọ Iṣẹgun.

Èèyàn 78 kú ó lé ní 4000 tó farapa níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Beirut, Lebanon

Eniyan to to mejidinlọgọrin ni ijọba Lebanon ti kede pe wọn padanu ẹmi wọn ti awọn to le ni ẹgbẹrun mẹrin si farapa ninu ibugbamu to waye ni Beirut lọjọ Iṣegun.

Orileede naa ti bẹrẹ si ni ṣe ọfọ iku awọn to lọ ti ọpọ eeyan jakejado agbaye naa si ti n bawọn ṣe idaro iṣẹlẹ laabi yi.

Ni aaye iko nkan pamọ si ni ibudoko ọkọ oju omi to wa ni Beirut ni ibugbamu yi ti ṣẹlẹ.

Aaarẹ Michel Aoun sọ pe nkan bi ẹgbẹrun mẹta tọọnu ammonium nitrate ti o ti wa ni ile iko nkan pamọ si yi fun bi odun mẹfa lawọn funra si pe o ṣokunfa ibugbamu naa.

Bẹrẹ lati ọjọru aarẹ ni awọn yoo la ọjọ mẹta kalẹ lati se idaro lorileede naa.

Iṣẹlẹ yi n waye saaju abọ igbẹjọ ẹsun pipa Olootu ijọba tẹlẹ, Rafik Hariri lọdun 2005.

Fidio kan to n ja ranin-ranin lori ayelujara ṣe afihan ofurufu to su jọ ati bi ibugbamu ọhun ṣe ba nnkan jẹ si.

Igbimọ olugbejọ kan labẹ ajọ isọkan agbaye ni yoo gbe idajọ kalẹ laipẹ ninu igbẹjọ afurasi mẹrin ti wọn lo lọwọ ninu iwa isekupani lati ipasẹ Ado oloro naa.