You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
WASSCE time table 2020: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ da ìdánwò WAEC rú ni Ghana, wọn gún infijilátọ̀
Ajọ to n ri si idanwo aṣekagba ileewe girama lẹkun Iwọ Oorun Afirika, WAEC, lorilẹ-ede Ghana ti bẹrẹ iwadii lori ohun to mu ki awọn akẹkọọ Bright Senior High, SHS, kọlu awọn to wa ṣakoso idanwo naa nile iwe wọn.
O le ni ẹẹdẹgbẹta awọn ọmọ ile iwe to kọ lati kọ idanwo naa, ṣugbọn ti wọn kọju ija si awọn infijilatọ ti ko jẹ ki wọn gbe iwe wọle si gbọgan idanwo.
Ọkan lara awọn oluṣakoso idanwo ọhun to ba BBC sọrọ, Jerry Alfred sọ pe awọn ọmọ ile iwe naa ṣe mẹrin leṣe ninu awọn mẹfa to lọ ṣakoso idanwo ọhun nile iwe naa.
- Irinwó lé méje èèyàn ló gbàwòsàn lọ́wọ́ Covid-19 lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, 453 míì tún lùgbàdì rẹ̀
- Wo ǹkan méjìlá nípa Buruji Kasamu tí Covid 19 mú lọ
- Wo iye àwọn ilé ìjọsin ìlú Eko ti wọ ko ni ṣí ìlẹ̀kùn ilé ìjọisin wọ́n lẹ́yìn ti ìjọba ti ni wọ́n le máa jọ́sìn
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
Jerry ṣlaaye pe: "Ọkan lara awọn infijilatọ naa ka ọkan lara awọn akẹkọọ ọhun to gbiyanju lati gbe iwe wọle, o si fi ẹrọ ibanisọrọ rẹ ka a silẹ, ni wahala ba bẹrẹ."
Alfred ṣalaye pe awọn akẹkọọ ọhun gun lara awọn infijilatọ naa ni 'compass' lẹyin ọrun.
Nigba ti ìkọlu naa n waye, awọn akẹkọọ tun fọ ẹrọ ibanisọrọ awọn alakoso naa mọlẹ nitori fidio bi wọn ṣe n gbe iwe wọle to wa lori rẹ.
Alfred fi ẹsun kan adari ile iwe Bright SHS pe o ṣegbe lẹyin awọn ọmọ ile iwe naa lati ṣakọlu si awọn oṣiṣẹ WAEC to wa mojuto idanwo nibẹ.
O ni oun kabamọ pe oun jẹ ọmọ orilẹ-ede Ghana, nitori ni ṣe ni oun n ṣe ojuṣe oun lati rii pe ọjọ ọla awọn akẹkọọ naa dara, ṣugbọn ẹmi oun ti wa ninu ewu.
Ẹwẹ, ajọ WAEC ti sọ pe oun ti bẹrẹ iwadii lati mọ idi ti awọn ọmọ ile iwe naa ṣe ṣakọlu si awọn eeyan ọhun.
Bẹẹ naa lo ni oun yoo gbe igbeṣẹ ti ri pe iru nnka nbẹẹ ko waye mọ.
WAEC 2020 timetable: Àlàkalẹ̀ fún ìdánwò ti ọdun 2020 rèé
Ajọ to n ri si idanwo aṣekagba ileewe girama lẹkun Iwọ Oorun Afirika ti gbe atẹ alakalẹ bi idanwo WAEC yoo ṣe lọ fun ọdun 2020 jade.
Ijọba apapọ Naijiria ti ṣaaju kede pe ki awọn akẹkọ to wa ni ipele ikẹkọgboye nileewe girama wọle pada sẹnu ẹkọ wọn lọjọ kẹrin oṣu kẹjọ.
Bakan naa, wọn kede pe idanwo WASSCE yoo bẹrẹ lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ titi di ọjọ kejila oṣu kẹsan ọdun 2020.
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀ ìjọba láti ṣ'íléèwé fún ìdánwò WAEC, ìpinnu ìjọba ilẹ̀ Yorùbá rèé
- Ìkéde ìjọba àpapọ̀ pé àkẹ́kọ̀ọ́ kò ní ṣe ìdánwò WAEC yàtọ̀ sí àdéhùn wa - ANCOPSS
- Èmi àti Sanyeri ti tọrọ oúnjẹ jẹ rí nílé oninawo torí ebi, ká tó di gbajumọ oṣere
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ tí ìdánwò NECO, NABTEB àti BECE yóò bẹ̀rẹ̀
Gẹgẹ bi at alakalẹ naa ṣe ri eyi ti ileeṣẹ BBC Yoruba ri, bayii ni gbogbo eto idanwo naa yoo ṣe lọ:
Ajọ WAEC wa gba awọn aṣedanwo nimọran pe ki wọn tẹle ofin ati alakalẹ fun idanwo naa nipa yiyọwọ kuro lawo magomago lasiko idanwo ati pe ki wọn tẹle gbogbo ofin to rọ mọ Covid-19 eyi ti awn ibudo idanwo wọn ti fi silẹ.