You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
JAMB post UTME screening: UNN, MAPOLY, Auchi poly, AKSU àtàwọn míì ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àtiwọlé ní Naijiria
Awọn ileewe giga kọọkan lorilẹ-ede Naijiria ti bẹrẹ si ni ta fọọmu idanwo Post UTME fun awọn akẹkọọ ṣẹṣẹ fẹ wọ ileewe giga.
Àjọ tó ń ṣètò ìdánwò àṣe wọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, JAMB ṣẹṣẹ kéde pe awọn ileewe to ba fẹ ṣe idanwo Post UTME ko gbọdọ bẹrẹ titi di Ọjọ Keje, Oṣu Kẹsan an, ọdun yii.
Ajọ naa ni idi ti awọn fi ṣe alakalẹ naa ni lati ri wi pe awọn akẹkọọ to ṣi n reti esi idanwo asekagba nileewe girama naa oo ni anfaani lati kọ idanwo Post UTME naa.
- Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka
- Joe Biden kéde Kamala Harris, obìnrin aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀ nínú ìdíje sípò Ààrẹ Amẹrika
- Wo ìdí tí Risikat Moromoke Azeez n'Ilorin fi ní "Blue Eyes" - Dókítà
- NCDC kéde èèyàn 423 míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà, 263 gbàwòsàn
Awọn ileewe to ti bẹrẹ si ni ta fọọmu re e:
- Bayero University, Kano ni iforukọsilẹ idanwo Post UTME ti saa 2020/2021 yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.
- Awọn alaṣẹ ileewe giga Moshood Abiola Polytechnic, Abeokuta ni awọn yoo bẹrẹ si ni ta fọọmu Post-UTME fun awọn to fẹ wọlẹ si ileẹkọ wọn.
- Awọn akẹkọọ to ba gba maaki 160 soke ninu esi idibo JAMB 2020 ni anfaani lati ra fọọmu post UTME ti ileewe Akwa Ibom State University (AKSU) ati awọn akẹkọọ Direct Entry (DE) naa.
- Fasiti orilẹ-ede Naijiria, Nsukka naa ti kesi awọn akẹkọọ ti o mu ileewe wọn gẹgẹ bi ileewe giga akọkọ ti wọn fẹran lati lọ, ti wọn si gba maaki to to 180 tabi ju bẹẹ lọ ni asiko idanwo JAMB ni anfaani lati lo ṣe iforukọsilẹ fun idanwo Post UTME.
- Bakan naa ni ileewe Auchi Polytechnic naa ti bẹrẹ lati ma a ta fọọmu post-UTME.
Àjọ JAMB kéde ìlànà ìgbà ni wọlé tuntun fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga
Ajọ to ṣe eto idanwo aṣewọle si awọn ile ẹ̀kọ́ giga ni Naijiria, JAMB, ti pàṣẹ pe ki eto igbani wọle o bẹrẹ ni ọjọ keje, oṣu Kẹsàn-án.
Agbẹnusọ fun ajọ JAMB to ba BBC sọrọ, sọ pe àṣẹ tuntun naa waye lati le fun gbogbo akẹkọọ, to fi mọ awọn to fẹ ẹ lo esi idanwo WAEC tabi NECO ti wọn ko ti i gbà, ni anfaani lati ṣe idanwo Post-UTME, ti
awọn ileewe giga ma n ṣe lẹyin idanwo Jamb.
Ọjọ Aje ni ajọ JAMB fi ẹnu ko si igbesẹ tuntun yii.
Lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn Ọga Agba Fasiti, Ọga Agba ile ẹ̀kọ́ gbogbo ni ṣe (polytechnic), ati awọn Ọga Agba awọn ile ẹ̀kọ́ gíga to kù.
Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni ajọ JAMB ti kọkọ dari awọn ile ẹ̀kọ́ giga lati bẹrẹ eto igbani wọle.
Agbenusọ fún ajọ JAMB sọ pe "abajade ipade ti a ṣe ni pe eto igbani wọle kankan ko gbọdọ waye ṣaaju ọjọ keje, oṣu Kẹsàn-án si ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwàá."
Bakan naa ni eto igbani wọle miran tun gbọdọ bẹrẹ ni ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, nitori awọn ti yoo ṣe idanwo NABTEB.
- Wo ìdí tí Risikat Moromoke Azeez n'Ilorin fi ní "Blue Eyes" - Dókítà
- Àjọ JAMB kéde ìlànà ìgbà ni wọlé tuntun fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200
- Dẹ́rẹ́bà kẹ̀kẹ́ Maruwa rí ẹ̀wọ̀n gbére he lẹ̀yìn tó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀
O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti yoo ba fi to awọn asiko tuntun ti wọn kede, gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ yoo ti gba esi idanwo ti wọn ṣe silẹ.
Sugbọn o, awọn ileewe to jẹ pe esi idanwo JAMB nìkan ni wọn fẹ ẹ fi gba awọn akẹ́kọ̀ọ́ wọle si ile ẹ̀kọ́ ti wọn le bẹrẹ igbani wọle, bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa ko ni i pari di oṣu Kọkanla ti ijọba yoo kede pe ki
gbogbo eto igbani wọle wa si opin.
- Ìdí tí ìjóba ìpínlẹ̀ Eko fí ṣí àwọn ilé ìwé kan padà
- Èèyàn 290 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ fara káásá àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà, 160 gbàwòsàn
- Baba Obasanjọ kò ní àrùn Coronavirus- NCDC
- Ìdí rèé tí igbákejì Gómìnà Ondo Agboola Ajayi tún ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀
- Wọ́n ti sún ọjọ́ ìjà Mike Tyson pẹ̀lú Roy Jones Jr síwájú
Saaju ni ijọba ti kọkọ sọ eyi ṣugbọn ohun gbogbo ti yipàda, idanwo WAEC di ṣiṣe.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀ ìjọba láti ṣ'íléèwé fún ìdánwò WAEC, ìpinnu ìjọba ilẹ̀ Yorùbá rèé
Ọrọ ṣiṣi ileewe ni orilẹede Naijiria ti fa ariyanjiyan nitori awọn ijọba ko fi ọjọ ti awọn akẹkọọ yoo pada si ileewe lede.
Lẹyin ti ijọba apapọ kede pe awọn ileewe girama rẹ ko ni le kopa ninu idanwo aṣejade iwe mẹwaa, WAEC eyi ti yoo bẹrẹ ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2020 nitori coronavirus, awọn ipinlẹ Yoruba naa ti sọ ero wọn lori igbesẹ ijọba apapọ.
Minisita fun eto ẹkọ ni Niajiria, Mallam Adamu Adamu ṣalye ninu iwe atẹjade kan to sita pe awọn ipinlẹ lominira lati ṣe ohun to ba wu wọn lori ọrọ naa.
Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori ago, Kọmiṣọnna eto ẹkọ nipinlẹ Osun, Folorunso Oladoyin ṣalaye pe ọrọ ṣiṣi ileewe lasiko yii gba ero nitori ajakalẹ aarun covid-19.
- Sotitobire: Ẹlẹ́rìí mẹ́rìn ló tẹ̀lé Alfa Babatunde wá síwájú ilé ẹjọ́ lonìí
- Ọlọ́pàá tún dé o! Wọ́n fún obìnrin kan lọrùn pa, awuyewuye ti ń wáyé
- Ààrẹ Muhammadu Buhari gbè sẹ́yìn Keyamo lórí ètò ìṣẹ́ 774,000
- Ìyàwó mi ló ṣì ń dáná, bu oúnjẹ mi, gé èékáná fún mi - Pásítọ̀ Adeboye
- Ìjọba fí ìlànà tuntun lédé lórí àti ṣí iléèwé káàkiri Nàíjíríà láì fí ọjọ́ tí wọn yóò ṣí iléèwé sí bẹ̀
- Kí ló fa ìjà láàrin Wunmi Toriola àti Seyi Edun?
Amọ Ọgbẹni Oladoyin fidi rẹ mulẹ pe ijọba ipinlẹ Osun yoo kọwe si ajọ WAEC lati sun idanwo naa siwaju pẹlu ọsẹ meji ki awọn le gbaradi daadaa fun idanwo naa.
O ni ijọba Osun ṣetan lati tẹle gbogbo awọn ilana ti ijọba apapọ la kalẹ lori ṣiṣi ileewe lasiko yii.
Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣọnna eto ẹkọ nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Foluso Daramola, sọ pe ipinlẹ Ekiti yoo gba kawọn akẹkọọ ṣe idanwo WAEC ṣugbọn eyi yoo da lori igbesẹ awọn ijọba ilẹ Yoruba.
Kọmiṣọnna eto ẹkọ l'Ekiti sọ pe gbogbo awọn kọmiṣọnna eto ẹkọ kaakiri ilẹ Yoruba lo ṣepade lọjọ Iṣẹgun lori ọrọ idanwo WAEC.
O fikun ọrọ rẹ ijọba Ekiti yoo pade kede ipinnu rẹ lori ọrọ naa lẹyin ti gbogbo ipinlẹ Yoruba ba ti fẹnuko tan.
- Mo ti buwọ́lu àdínkù owó orí nítorí ìrọ̀rùn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun lásìkò Covid 19- Dapo Abiodun
- Iná sọ nínú ilé Big Brother tó ń lọ lọ́wọ́ ní Cameroon
- Buruji Kashamu jẹ́ ènìyàn tó nífẹ̀ aráàlú- Gómínà Dapo Abiodun
- Iná jó àwọn ènìyàn 10 tó ń gbà ìwòsàn arùn Coronavirus níbùdó ìtọ́jú
- Baba Obasanjọ kò ní àrùn Coronavirus- NCDC
Bakan naa lo sọ pe ijọba ti gbaradi lati tẹle gbogbo ilana ti ijọba apapọ la kalẹ lori ṣiṣi ileewe pada lasiko idanwo naa.
Ẹwẹ, Toyosi Kolawole ati Tofunmi Bello ti wọn jẹ akẹkọọ naa sọrọ lori ilana ijọba to da lori kikọ idanwo WAEC loṣu kẹjọ ọdun 2020.
Tofunmi Bello ni tiẹ sọ pe ọrọ naa ti toju su oun, o ni oun ko tiẹ le kawe mọ nitori oun ko mọ igba ti idanwo naa yo ya.
Tofunmi ni o ṣeni laanu pe ijọba n gbaradi fun eto idibo, ṣugbọn ijọba o fẹ kawọn akẹkọọ ṣe idanwo.
O ni idanwo ohun to maa buru jai ni ti ijọba ba le sun idanwo WAEC awọn ti ọdun 2021.
Awọn mejeeji naa panu pọ lati bẹ ijọba pe ko ṣi ileewe pada nitori ọjọ iwaju awọn niyẹn.
Ìjọba fí ìlànà tuntun lédé lórí àti ṣí iléèwé káàkiri Nàíjíríà láì fí ọjọ́ tí wọn yóò ṣí iléèwé sí bẹ̀
Igbesẹ ijọba lati fi ilana ofin ti awọn olukọ ati akẹkọọ gbọdọ tẹlẹ lai fi ọjọ ti wọn yoo ṣi ileewe lede ti fa ariyanjiyan.
Ilana ofin ati ṣi ileewe naa wa ninu atẹjade ti ijọba fi le de ti wọn pe ni 'Guidelines for schools and learning facilities reopening after COVID-19 pandemic closures: Taking responsibility for safe schools and quality learning.'
Minisita fun eto ẹkọ ni Niajiria, Mallam Adamu Adamu lo buwọlu iwe atẹjade naa.
Ilana ofin naa fi lede pe awọn akẹkọọ gbọdọ tẹle ofin ijinasiraẹni pẹlu mita meji ni gbogbo ileewe kaakiri Naijiria.
Amọ, wọn fikun pe, ti ko ba ṣeeṣe nitori awọn ọmọ to ni ipenija ẹkọ, ki wọn tẹlẹ gbogbo ofin to ku bi lilo oogun apakoko kaakiri agbeegbe naa, ki wọn si maa fọ ọwọ wọn loore-koore.
Wọn fikun wi pe ijọba yoo pese owo fun awọn ileewe lati le fi awọn eto yii lele ni awọn ileewe kaakiri Naijiria lati da abo bo awọn akẹẹkọ lọwọ aarun Coronavirus.
Bakan naa ni Minisita fun eto ẹkọ naa fikun pe lilo eto ẹkọ lori ẹrọ ayelujara naa yoo ṣeranwọ fun awọn eniyan lati koju ipenija itankalẹ arun Coronavirus.
- Ààrùn Coronavirus tún ti ran ènìyàn 595 l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá kọ́ lo pa olórí àwọn ''One Million Boys'' Ebila n'Ibadan- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Kí ló fa ìjà láàrin Wunmi Toriola àti Seyi Edun?
- Bí òṣìṣẹ́ Amotekun bá fi orúkọ sílẹ̀ lórí ayélujára, àwọn ọ̀daràn yóò tètè fojú hàn - Oludari Amotekun l'Oyo
- Ǹjẹ́ o mọ iye ẹ̀bùn owó tí olúborí BBNaija yóò gbà lọ́dún yìí?
- Àwọn dókítà Eko bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lórí owó oṣù àti ètò adójútòfò fún ìtọ́jú Coronavirus
Alaga ẹgbẹ awọn to ni ileewe aladani ni Naijiria, National Association of Private school Owners, ti fidirẹmulẹ pe lootọ ni ijọba apapọ fẹ ẹ san owó oṣù awọn oṣiṣẹ wọn.
Yomi Otubela, to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa sọ pe igbesẹ ijọba yoo fun awọn ni itura diẹ kuro ninu inira ti itankalẹ aarun Coronavirus mu ba wọn.
Oṣu Kẹta, ọdun 2020, ni ijọba ti ti gbogbo ileewe pa. Otubela sọ ninu atẹjade kan to fi ránṣẹ si BBC pe awọn ileewe aladani naa yoo pin ninu 2.3 biliọnu, owo iranwọ ti ijọba kede lọsẹ to kọja.
Ẹgbẹ NAPS sọ pe awọn fi ọrọ lọ ijọba apapọ, nipasẹ igbimọ to wa fun fifi ẹsẹ eto ọrọ aje mulẹ ni Naijiria, ti igbimọ alasẹ naa si ti buwọlu u.
Igbakeji aare, Yemi Osinbajo, lo n dari igbimọ naa.
Ẹwẹ, ile aṣofin agba Naijiria paapa fi si ori itakun agbaye rẹ pe awọn ileewe aladani wà lara awọn ti ijọba yoo ran lọwọ.
Lori iye oṣu ti ijọba yoo ran wọn lọwọ lati san, Ọgbẹni Otubela sọ pe oun ko ti i le sọ, nitori pe ko si ẹni to mọ igba ti Coronavirus yoo to o wa si opin.
Bakan naa ni ko le sọ igba ti ijọba yoo bẹrẹ si ni san owo naa, nitori pe eto ṣi n lọ.
Ọgbẹ́ni Otubela sọ pe oni ọna ti awọn yoo gba lati mọ àwọn ileewe to jẹ oṣiṣẹ wọn lowo oṣu, nitori pe akọsilẹ wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ NAPS.
Óṣeéṣe kí ìjọba yí ètò ẹ̀kọ́ sí ẹ̀kọ́ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ láti ṣí iléèwé padà ní Nàìjíríà
Minisita kekere fun eto ẹkọ ni Naijiria, Emeka Nwajiuba, sọ pe orilẹ-ede Naijiria ko ṣetan lati fi ilera awọn ọmọde sinu ewu nitori pe wọn fẹ ẹ ṣi ileewe pada.
Ọgbẹni Nwajiuba ti ko sọ pato ọjọ ti awọn ọmọ yoo wọle pada, sọ pe "O di igba ti a ba to o ni idaniloju pe awọn ọmọde le lọ sileewe, pada sile laalafia, lai ko aarun Covid-19 pada sile, la to o ṣetan".
Minisita sọ ọrọ yii lasiko ti igbimọ to n mojuto itankalẹ aarun Covid-19 n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta.
Ọrọ to sọ yii waye gẹgẹ bi esi fun awọn obi kan ni Naijiria, to n beere pe nigba wo ni ijọba yoo ṣi ileewe pada.
Ọgbẹni Nwajiuba sọ pe ileeṣẹ eto ẹkọ yoo gbe ilana jade lori bi nkan yoo ṣe lọ, ti awọn akẹkọọ ba pada sileewe.
"Fun awọn ileewe girama, awọn akẹkọọ wọn le pada sileewe, lati le pari idanwo wọn, ki wọn o si tun pada lọ ọ joko sile.
"Bakan naa ni ao mu adinku ba iye akẹkọọ ti yoo wa ni kilaasi kọọkan. Eyi ṣeeṣe ko tumọ si pe eto ẹkọ yoo wa ni owurọ ati ọsan, lati le tẹle ilana titakete siraẹni."
Minisita tun sọ pe awọn n gbeero lati fin oogun apakokoro si awọn ileewe ṣaaju iwọle pada.
Ninu ọrọ tiẹ, Alaga igbimọ amuṣẹya fun aarun Covid-19, Boss Mustapha, sọ pe "ki awọn ipinlẹ, ati ijọba ibilẹ o ṣe gbogbo eto to yẹ", ki eto ẹkọ le tete bẹrẹ pada ninu ilera pipe.
O sọ pe ijọba "ko ṣetan lati fi awọn ọmọ wa tọrẹ fun aarun yii".
Kini awọn ipinlẹ sọ ṣaaju ikede minisita eto ẹkọ?
Ilé isẹ́ tó n rí sí ètò ẹ̀kọ́ ni Nàìjíríà ni àwọn kò tíì dá ọjọ́ kankan fún ìwọlé ilé ẹ̀kọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Agbenusọ ilé isẹ́ náà, Ben Gong ṣàlàyé fún BBC pé àsìkò tí ilé isẹ́ ètò ìlera ba sọ pé kò séwu mọ ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ yóò tó padà di ṣíṣí.
Gbogbo ilé ẹ̀kọ́ jákèjádò orílẹ̀ èdè yìí ni ìjọba tìpa láti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀, gírámà títí dé Fáṣítì láti ọjọ́ kẹrindinlọ́gbọ̀n oṣù kẹ̀ta ọdún yìí.
- Mọ síi nípa ohun tó ṣẹlẹ ní àwọn ibi tí wọn ti ṣilẹkùn ilé ìwé padà lẹyìn Covid 19
- Aláàfin gbé àṣẹ kalẹ̀ láti dènà àtúnṣẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 'Soka'nílùú Ọ̀yọ̀
- Lagos Lockdown: Ìgbésẹ̀ ìjọba lórí Twitter tì mí lójú- Jimi Disu
- Èsì àyẹ̀wò tí àjọ NCDC gbé síta fihàn pé ènìyàn 265 ló tún ti ní ààrùn Covid-19 ní Nàìjíríà
- Ṣọ́ọ́ṣì kan sí ìlẹ̀kùn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí láti kírun Jímọ̀ ní Germany
Gong ni ojúṣe ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera, àjọ tó ń gbógun ti àjà kálẹ̀ ààrùn ni Nàìjíríà (NCDC) àti ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ya Covid-19 tí Ààrẹ yàn ni àti pé àwọn ni ọ̀rọ̀ kù sí lọ́wọ́ nítorí àwọn ni wọ́n ń léwéjú lórí ọ̀rọ̀ Coronavirus àwọn sì ló mọ àsìkò tó yẹ láti ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́."
Ó ní ní kété ti àwọn ba ti mọ àsìkò tí tí ilé ìwé yóò wọlé padà làwọn yoo ti fi àwọn ìlànà tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ yóò maa tẹ̀lé síta.
Ẹ̀wẹ̀ Kọmísọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ni Ìpínlẹ̀ Kano Muhammad Sansi Sa'ad sọ fún BBC pé kò tíì sí ìfojúsùn ọjọ́ tí àwọn yóò ṣí ilé ẹ̀kọ́ tó ti wà ní títì pa láti oṣù méjì sẹ́yìn.
"ìpàdé ní wọ́n ó ti pinnu àsìkò tí ilé ẹ̀kọ́ yóò wọlé padà àti ìlànà ti àwọn olùkọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò tọ̀ ti wọ́n bá wọlé "
Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ni Ìpínlẹ̀ Kano lo tí n káyà sókè pé àwọn ọmọ ti pẹ́ nílé láì lọ sí ilé ìwé àti pé àwọn ilé ìwé péréte lo ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ orí ayélujára fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn.
Nípìnlẹ̀ Rivers Kọmísọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ níbẹ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n Kaniye Ebeku sọ fún BBC pé àwọn ò fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ṣeré rárá ìdí nìyí tí àwọn fi n ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àpapọ̀ lórí redio àti telefísọ̀n fún akẹ́kọ̀ọ́ ipele kẹwàá àti àwọn tó fẹ́ kọ WAEC pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Covid-19 ò ní pẹ́ kásẹ̀ nílẹ̀.
"Ṣùgbọ́n bi ǹkan ṣe ń lọ báyìí à ń wo bí yóò ṣe kan àwọn kíláàsì to ku, èyí sì ni à ń ṣètò lọ́wọ́"
"Àwọn nkan míràn ti a tún n ṣe ni láti máa fún àwọn olùkọ́ wa ní ìmọ̀ nípa bí a ṣe n kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní orí ayélujára àti láti mú kí àyíká ilé ẹ̀kọ́ ṣeé lò, ti gbogbo àwọn ǹkan wọ̀nyí bá ti délẹ̀ a ó jẹ́ kí ará ilú mọ̀. "
Ẹ̀wẹ̀, Kọmísọ́nà ṣàlàyé pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga n se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ orí ayélujára nítorí pé ọ̀pọ̀ kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìdánwò lórí ayélujára pẹ̀lú.
Bákan náà ni Ìpínlẹ̀ Èkó to jẹ́ orírun ààrùn Coronavirus ni Nàìjíríà náà ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ orí redio àti telefísọ̀n, ṣùgbọ́n wọn ò sọ àsìkò tí ilé ẹ̀kọ́ yóò wọlé.