SayNotoRape: Àlùfá tọ ba ọmọ ọdún méje sùn, wẹ̀wọ́n ọdún Márùn-un ni ìpínlẹ̀ Ekiti

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tí dí àkọ́kọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ láti maa dárukọ ọ̀daran afipa banilòpọ̀ han àti láti maa doju ti wọ́n.

Gómìnà ìpínlẹ̀ náà Kayode Fayemi gbé jáde lóju opo twitter rẹ̀ lọ́sàn òní pé àsìkò ti tó láti máa fi oju hàn lásìkò to gbé àwòrán ẹni ọwọ Asateru Gabriel ti ìjọ St Andrew Anglican Ifinsin -Ekiti nígbà kan.

Gabriel ti fọjú ba ilé ẹjọ ó si jẹ̀bi ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan, nítori ìdí èyí yóò maa ṣẹ̀wsn ọdún márun ní ọgbà ẹwọ̀n ijọba ni Ado Ekiti fún ẹ̀sùn ìfipá bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀.

Ní bayiì orúkọ rẹ̀ ti wọ ìwé akọsílẹ̀ àwọn olùfipabanilòpọ ní ilé ìṣẹ́ ìdajọ́.

Èyí jẹ́ ìpínlẹ̀ Guus- ìwọ̀ -òorun akọkọ tí yóò gbé ìgbesẹ̀ yìí.