You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wunmi Toriola: Ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ rẹ̀ kò fẹ́ kó bá Seyi Edun ṣe ọ̀rẹ́ mọ́.
Ni agbo ere tiata Yoruba, odu ni Wunmi Toriola ati Seyi Edun jẹ, wọn kii si ṣe aimọ fun oloko. Bakan naa, ọrẹ timọ-timọ ni awọn eeyan tun mọ awọn osere mejeeji si, nitori bi wọn ṣe maa n ṣe wọle wọde, ti wọn si maa n jọ ya fọto pọ ni ori ayelujara.
- Ìyàwó mi ló ṣì ń dáná, bu oúnjẹ mi, gé èékáná fún mi - Pásítọ̀ Adeboye
- Kò sí ìfòyà, ọkọ̀ bààlù wà tí ìjọba ba ti afárá 3rd Mainland lósù yìí
- Ẹ wo Daniel tí wọ́n fẹ́ yẹgi fún lẹ́yìn tí US kò ṣe irú ẹ̀ fún odidi ọdún 17
- Àwọn dókítà Eko bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lórí owó oṣù àti ètò adójútòfò fún ìtọ́jú coronavirus
- Taló pa olórí àwọn ''One Million Boys'' Ebila n'Ibadan?
Koda, ninu ifọrọwerọ kan ti Wunmi Toriola ṣe pẹlu BBC Yoruba nigba kan, o sisọ loju rẹ pe, ọrẹ minu oun ni Seyi Edun, tii ṣe iyawo osere tiata miran, Adeniyi Johnson, tii ṣe ọkọ Toyin Abraham tẹlẹ. "Bi Seyi Edun si ṣe fẹ Adeniyi Johnson lo da aawọ silẹ laarin emi ati Toyin Abraham, nitori o gbagbọ pe lati ipasẹ mi ni Adeniyi Johnson fi fẹ Seyi Edun."Ọrọ naa di yanpọnyanrin fun ọpọ ọdun, ti ori ayelujara si n gbona fun aawọ wọn ọhun.
Amọ laipẹ yii la gbọ pe ija ti tan, ogun si ti dopin laarin Toyin Abraham ati Wunmi Toriola, bẹẹ ni Wunmi gan fi idi ọrọ naa mulẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii. Ṣugbọn ipẹyinda iṣẹlẹ yii ni pe, awọn ololufẹ Wunmi Toriola ati Seyi Edun sakiyesi pe aawọ abẹnu ti n waye laarin awọn oṣere tiata mejeeji, eyi to si fi idi mulẹ lasiko ti Seyi Edun ṣe ọjọ ibi.
Lootọ ni Wunmi Toriola ki Seyi ku ọjọ ibi amọ ọpọ ololufẹ Seyi ni ikinni naa ko dabi ti tẹlẹ, ti wọn si n fura pe ejo ti gba aarin awọn oṣere mejeeji kọja. Bakan naa, nigba ti Wunmi Toriola ṣe ọjọ ibi ni ọjọ kọkanla osu keje ọdun 2020, Seyi Edun kan ki i ranpẹ ni, eyi to mu ki awọn eeyan kan bẹrẹ ẹjọ lori ayelujara.
Ṣugbọn awọn ọrọ naa pọ to bẹẹ gẹ eyi to mu Wunmi bọ sori ayelujara lati ṣe afihan bi Seyi ṣe ki lasiko ọjọ ibi rẹ, to si ni ohun ko fa wahala mọ rara lori ayelujara nitori oun ti kọgbọn.
Ohun ti Wunmi kọ yii lo fidi rẹ mulẹ pe aarin oun ati ọrẹ rẹ naa, Seyi Edun ko gun rara, ti aawọ si wa laarin wọn gẹgẹ bi ẹnu ṣe n kun wọn. Lọwọ lọwọ bayii, Seyi Edun ko tii fesi si ọrọ Wunmi yii, amọ a lero pe ija naa yoo wa sopin laipẹ laijinna.