You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Brazil police brutality: Awuyewuye ti n wáyé lórí bí ọlọ́pàá ṣe fún obìnrin kan ní ọrùn pa
Ọlọpaa meji ni yóò koju ẹsun iwa ọ̀daràn lẹyin ti aworan to safihan wọn nibi ti wọn ti n fun obinrin aláwọ̀ dúdú kan ni ọrùn mọ́lẹ̀.
Ninu àwòrán naa, ọkan lara awọn ọlọpaa naa ti wọn ko dárúkọ, n gun ọrùn obìnrin naa to jẹ olookowo ọtí mọlẹ.
Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si ni fi ṣẹ́kẹ́-ṣẹké wọ́ obìnrin ọhun nilẹ.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa to waye l'oṣu Karun, lo ya fidio naa.
Gomina ipinlẹ naa, João Doria, sọ pe oun ko ni i faaye gba ìwà palapala bẹẹ, ati pe iṣẹ́ ti bọ lọwọ ọlọpaa mejeeji.
Gomina fi kún un pe ẹgbẹrun meji ọlọpaa ni São Paulo, ni yoo ma fi ẹrọ ayaworan si ara bayii.
Aworan naa si ti fa awuyewuye ni orilẹ-ede Brazil, paapa nitori pe iru iṣẹlẹ naa ti waye ri nilẹ America lasiko ti ọlọpaa fi orunkun fun ọkùnrin aláwọ̀ dúdú kan, George Floyd, lọrun pa l'oṣu Karun un.
Ikú Floyd fa iwọde jakejado America.
- Ọlọ́pàá kọ́ lo pa olórí àwọn ''One Million Boys'' Ebila n'Ibadan- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Ẹ wo ọ̀nà tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ gbà san owó àwọn olùkọ́ iléèwé aládàni tí kò rówó oṣù gbà
- Bí òṣìṣẹ́ Amotekun bá fi orúkọ sílẹ̀ lórí ayélujára, àwọn ọ̀daràn yóò tètè fojú hàn - Oludari Amotekun l'Oyo
- Kí ló fa ìjà láàrin Wunmi Toriola àti Seyi Edun?