You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Auxiliary: Alága àjọ Park Management System, gbé àwọn tó ń ja ìjọba lólè ní ibùdókọ̀ lọ sí ilèẹjọ́
Alaga ajọ to n mojuto awọn ibudokọ nipinlẹ Oyo, Park Management System, Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ mọ si Auxiliary ti gbe eeyan mẹfa to n jawee ayederu fawọn awakọ lọ sile ẹjọ.
Bakan naa lo tun fi ẹsun pe wọn n gba ju owo ti ijọba ipinlẹ Oyo ni ki wọn maa gba lọwọ awọn awakọ lọ.
Auxiliary gan an lo sọrọ yii fawọn akọroyin l'Ọjọru niluu Ibadan.
O ṣalaye pe ọdọmọkunrin ọdun mọkandinlogun kan to ṣẹṣẹ pari ileewe girama wa lara awon mẹfa ọhun ti igba iwa ibajẹ lawọn ibudokọ ti ṣi mọ lori bayii.
Auxiliary sọ pe gbogbo awọn ọbayejẹ ẹda to ba fẹ ma ja ijọba lole nipa gbigba owo lọna aitọ ni yoo foju wina ofin nipinlẹ Oyo.
Bakan naa ni Auxilliary rọ awọn ẹgbẹ onimọto, RTEAN at'awọn ẹgbẹ ọlọkada lati bọwọ fun ofin ijọba nipa sisanwo wọn deedee ti awọn oṣiṣẹ ajọ PMS ba ti n jawe fun wọn ni ibudokọ.
O ni ọna kan gbogii niyii lati pawo sí apo ijọba ki wọn le pèse ohun amayedẹrun fun araalu
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ laarin NURTW ati Auxilliary funra rẹ ni Ibadan?
Ara ló ń ta àwọn ẹgbẹ́ NURTW tó ń pariwo mi kiri, APC ni wọ́n bá lọ nígbà náà l'Oyo- Auxiliary
NURTW: Auxiliary ní ara ló ń ta àwọn ẹgbẹ́ NURTW tó ń pariwo òun kiri, APC ni wọ́n bá lọ l'Oyo
Ẹgbẹ awakọ NURTW ẹka ti ipinlẹ Oyo ti ke gbajare lori iwa ipa ti wọn ni Alhaji Lamidi Mukaila ti inagijẹ rẹ n jẹ Auxiliary to n hu sawọn ọmọ ẹgbẹ ajọ naa.
Auxiliary ni alaga ajọ, Park Management System (PMS) to n ṣe akoso awọn ibudọ kaakiri ipoinlẹ Oyo lati igba ti Gomina Seyi Makinde wọgile ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo.
Ajọ NURTW ṣalaye pe niṣe ni Auxiliary n kaakiri gbogbo ọfiisi ajọ naa ti o si n ko ohun ini ẹgbẹ lọ si ibi tawọn ko mọ.
Kini Ejiogbe NURTW sọ?
Eekan inu ẹgbẹ NURTW, Alhaji Abideen Olajide (Ejiogbe) to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ohun ti ijọba ko ran Auxiliary n ṣe kaakiri ipinlẹ Oyo.
Ejiogbe ni kete ti wọn bura tan fun Alhaji Mukaila lo bẹrẹ si ni pa orukọ NURTW rẹ lara awọn ọfiisi ajọ naa to n si yi pada si PMS.
O ni iṣẹ ti ẹgbẹ NURTW n ṣe ni ijọba gbẹsẹ le l'Oyo kii ṣe ẹgbẹ NURTW.
Ejiogbe ni owo ẹgbẹ NURTW lawọn fi kọ ile ẹgbẹ NURTW ti ti Auxiliary n yi ọrukọ pada si PMS.
O ni ''gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW to wa ni ipo kan tabi omiiran ni Auxiliary ti yọ nipo tan ti o si fawọn eeyan tiẹ sibẹ.
Alhaji Olajide ni awọn si n rawọ ẹbẹ si ijọba Gomina Makinde lati gbẹsẹ kuro lori ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo.
Ejogbe ni ohun ti ijọba ni ki Auxiliary maa ṣe ni pe ko maa pa owo si apo ijọba, ko si maa jawe fawọn awakọ lawọn ibudokọ.
O ni Auxiliary ko mọ iyatọ to wa laarin NURTW ati PMS.
Kini Auxilliary sọ ni tirẹ?
Ṣugbọn ninu ọrọ ti ẹ, Auxiliary sọ fun BBC Yoruba irọ nla lawọn ọmọ ẹgbẹ NURTW n pa mọ oun pe oun n gbe ohun ini ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ Oyo.
O ni ''lati ọjọ ki Gomina Makinde ti ti ọfiisi NURTW to wa ni Aduloju pa, oun atawọn ọmọlẹyin ou ko de ibẹ.''
Alhaji Mukaila ni awọn ara awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW gan an ti bẹrẹ si ni darapọ mọ awọn ọmọlẹyin oun.
O ni ko si si ohun to jọ ọ pe oun tun n yi orukọ NURTW pada si PMS.
Alhaji Mukaila ni ọwọ to ba ṣẹ ẹkusi lo maa n jẹ ẹ, o ni iyẹn tumọ si pe oun ti ṣiṣẹ silẹ de ongbẹ lasiko yii nitori ẹgbẹ oṣelu PDP loun tẹ le lasiko ibo gbogbogbo to lọ.
''Ẹgbẹ oṣelu APC lawọn to to gba NURTW ipinlẹ Oyo tẹ le, wọn o si ke si mi nigba ti wọn lo ọdun mẹjọ ti wọn naa lasiko ti APC wa ni ijọba,'' Auxiliary lo ṣalaye bẹẹ.
Auxiliary sọ pe ara lo n ta awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ti wọn n pariwo ohun kaakiri.
Alhaji Mukaila ko ṣai fikun ọrọ rẹ pe oun naa lẹtọ si ohun ini ẹgbẹ NURTW nitori ọkan lara ọmọ ẹgbẹ naa loun n ṣe tẹlẹ.
- Daniel Prude: Ìbòjú tí àwọn ọlọ́pàá New York fi bo ọkunrin ọhun ló ṣe ikú pà á
- Mo ṣetán láti fi ẹ̀ṣẹ́ dín dòdò ìyà fún Anthony Joshua- Efe Ajagba
- A kú oríire! Oró agbọ́n leè wo àìsàn jẹjẹrẹ ọmú sàn, wo ohun tí wàá lò pọ̀ mọ́ra wọn
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá