You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ibudo ikepo si bu gbamu nipinlẹ eko
Ibudo ipamọ epo bẹtiroo kan ti o ni awọn agba ikepopamọsi nlanla marun (PMS) ti gba ina jẹ ni agbegbe Ijegun nilu Eko lọjọọru.
Ile-iṣẹ Isakoso ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko (LASEMA) sọ fun BBC pe ijamba ibugbamu ina yii sẹlẹ ni ileesẹ epo Stallionaire Oil ni nkan bii agogo mẹta ọsan.
Oludari ile isẹ LASEMA, Ọgbẹni Adesina Tiamiyu sọ pe awọn osisẹ rẹ gbiyanju lati pa ina naa ni kiakia ti wọn ti fi to wọn leti, ti wọn si dẹkun ibugbamu ina yi fun awọn agba ikepopamọsi yooku ni ile isẹ naa.
O wi pe iwadi ti o peye yoo waye lori isẹlẹ naa, nigbati o tẹnumọ iwulo fun awọn onile-epo ati afẹfẹ gaasi lati rii daju wipe eto wa fun awọn ohun eelo idojukọ isẹlẹ pajawiri lẹnu isẹ ati ni ibudo ikepopamọsi gbogbo.
Ko si ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ.