Dubai fire Outbreak: iná ṣẹ́yọ lọ́jà Ajman, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Obitibiti ina nla kan ti ṣe akoba fun ọpọ dukia ni agbegbe ọja nla Ajman lorileede UAE, Dubai lọjọru.

Ọ́pọ awọn panapana ni wọn sare lọ sibẹ lati pa ina naa ti eefin rẹ gba gbogbo oju ọjọ.

Awọn alaṣẹ ilẹ naa ko ti sọ ohun to fa ina ọhun.

Ṣugbọn ninu ohun taa ri gbọ, nkan bi ago mẹfa abọ irọlẹ ni ina naa ṣaadede ṣẹyọ ni agbegbe katakara tuntun ni Ajman to jina si Dubai ni iwọn aadọta kilomita.

A ko tii ribi fidi ọrọ mulẹ boya awọn to farapa wa ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ọja Ajman taa n sọrọ rẹ yi jẹ ibi ti wọn ti maa n ta eso ati awọn nkan jijẹ mii.

Awọn eeyan ti fi aworan ati fidio nipa iṣẹlẹ yii soju opo ayelujara

Ajman si Dubai, bawo ni wọn ṣe jina si?

Olu ilu Emirate Ajman ni ilu Ajman jẹ ti o si wa ninu United Arab Emirate.