You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NEMA: Ìjọba ìbílẹ̀ 102, ní ìpínlẹ̀ 28 ni ẹ̀kún omi ń bọ̀, ẹ múra
Igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere la ti n lọ.
Eyi lo mu ki ajọ to n mojuto isẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA tete ma fi ikilọ sita fawọn Gomina Naijiria, lori ewu omiyale ti o n bọ lọna.
Ajọ naa sọ pe, awọn ijọba ibilẹ mejilelọgọrun ni ipinlẹ mejidinlọgbọn lo wa ninu ewu omiyale lọdun yi.
Ki awọn Gomina yii ba le tete maa mura kalẹ, ajọ naa sọ pe, awọn ti kọ iwe sawọn Gomina ti ọrọ yii kan .
Ọga patapata fajọ naa, AVM Muhammadu Muhammed, lo fidi ọrọ naa mulẹ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l'Abuja, nipa ipalẹmọ ati igbesẹ tawọn n gbe lati koju omiyale, to le sẹlẹ lọdun yii.
''Omiyale le se akoba ti ko lonka, ti o si le fa ki awọn eeyan padanu ẹmi ati dukia, to fi mọ awọn nkan amayedẹrun ti ijọba pese fara ilu''
Muhammed ni o ṣeni laanu pe ọdun 2020 jẹ ọdun to lamilaaka pẹlu bi orileede Naijiria ti ṣe n koju ipenija ajakalẹ Covid-19.
''Pẹlu bi a ti ṣe n koju Covid-19, ijamba omiyale naa to ba ṣẹlẹ ko ni jẹ ki nkan rọrun rara''
Ọga NEMA wa salaye pe awọn ti bẹrẹ si ni ko ounjẹ pamọ de asiko omiyale nitori awọn ko mi iru akoba ti o le ṣe fara ilu.
Ninu alaye rẹ to ṣe, o ni awọn onimọ nipa bi oju ọjọ ti ṣe ri sọ pe, omiyale agbara ya ṣọbu yoo waye ni awọn ijọba ibilẹ mejilelọgọrun ni ipinlẹ mejidinlọgbọn Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?
- Mo gba àṣẹ lọ́wọ́ ọkọ, kí ń tó má ṣeré ìfẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ - Àlè kan jẹ́wọ́
- Wọ́n fi ikú Tunde Braimoh dá wa lóró ni o - Ẹbí pariwo
- Ẹ̀yin ọmọ ìta tó ní Funke Akindele ra ilé fún mi, irọ́ ni o - Ajirebi
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Báwo ni Coronavirus ṣe n tànkálẹ̀ l'Afrika?
Lọwọlọwọ bayii, awọn ipinlẹ bii Ogun, Oyo ati awọn apa kan Kwara ati Eko ti n koju ipenija omiyale, ti ọpọ dukia si ti ṣofo ninu rẹ.
Yatọ si awọn ipinlẹ wọn yii, awọn ijọba ibilẹ kan lawọn ipinlẹ miran bi Osun, Ondo, Kogi, Jigawa, Enugu, Ekiti ati Kebbi naa wa ninu ewu omiyale lọdun yii.
Ìbẹ̀rùbojo gba ọkàn àwọn olùgbé Eko àti Ogun nítorí adágún omi Ọ̀yan tí yóò di ṣíṣí láìpẹ́
Inu ibẹrubojo ọkan lawọn olugbe agbegbe eti omi ni ipinlẹ Eko atawọn agbegbe miran ni ipinlẹ Ogun wa bayii ni ireti pe adagun omi Oyan yoo di ṣiṣi laipẹ.
Ọdọọdun ni wọn ma n ṣi daamu naa ti ileeṣẹ Ogun-Osun River Basin Development Authority (ORBDA) n ṣakoso rẹ.
Lọdun 2019, awọn agbegbe bii Mile 12, Ketu, Owode, Oworoshoki ati Bariga ni ipinlẹ Eko lo kun fun ẹkun omi, ti ọpọ dukia si ṣofo lẹyin ti wọn ṣi daamu ọhun.
Bakan naa ni ọpọ dukia ati ile ba omi lọ ni marosẹ Eko si Ibadan lawọn agbegbe bii Isheri, Warewa, Arepo, Magboro ati Ibafo ni ipinlẹ Ogun.
Lara awọn olugbe agbegbe naa to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye ohun toju wọn ri nigba ti wọn ṣi daamu naa lọdun 2019.
Yatọ si pe wọn padanu ọpọ dukia, pupọ lara awọn eeyan naa lo n lo ọkọ oju omi lati de ile wọn nitori omi pe gba gbogbo opopona ti wọn lee gba kọja.
Ni bayii, wọn ni ọkan wọn ko balẹ lori idojukọ ti yoo tẹle ṣiṣi daamu Ọyan naa, papa lasiko ajakalẹ arun Covid-19 yii.
Ṣaaju ni Kọmiṣọna to n risi ọrọ ayika ati ipese omi ni ipinlẹ Eko, Tunju Bello ti kilọ pe ki awọn eeyan mura silẹ fun ojo arọrọda to ṣeṣe ko yọri si ikun omi lọdun yii.
Bello tun sọ pe ki awọn eeyan ma mura silẹ fun ṣiṣi daamu ọhun, nibi ti wọn yoo ti ṣi omi silẹ ni Oṣu Keje, Oṣu Kẹjọ, Oṣu Kẹsan an ati Oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
O ni daamu naa ti kere ju iye omi to lee gba lasiko ti wọn ṣẹṣẹ kọ lọ.
O tẹsiwaju pe ohun to fa iṣẹlẹ omiyale to n waye lagbegbe idi Oro, Mushin atawọn agbegbe miran nilu Eko ko ṣẹyin bi awọn eeyan ṣe ma n da idọti soju gọta.
Bello pari ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Eko ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe ọrọ omiyale dohun igbagbe ni ipinlẹ ọhun.