Rivers court and Anti Piracy 2019 law: Ilé ẹjọ́ ju olè orí omi mẹ́ta sí ẹ̀wọ̀n, ó tún ní kí wọ́n san 60 miliọ̀nù

Onidajọ I. M Sani to ṣe idajọ naa sọ pe awọn mẹtẹẹta; ọmọ ilẹ okeere meji, ati ọmọ Naijiria kan, jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan wọn.

Adajọ tun pasẹ fun wọn lati san miliọnu mẹwaa Naira fun ikọọkan awọn ẹsun naa, lẹyin ti wọn gbà pe awọn jẹbi àwọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Eyi tumọ si pe ogún miliọnu Naira ni ẹni kọọkan wọn yoo san.

Oludari awọn agbẹjọro to ṣoju ijọba, Labaran Magaji, sọ pe àṣeyọrí nla ni idajọ naa jẹ, nitori pe oun ni idajọ akọkọ to waye nipa ofin ọdun 2019 to de ole jija ati ijinigbe lori omi.

Bakan naa lo sọ pe yoo tun jẹ ẹ̀kọ́ fun ẹnikẹni to ba fẹ ẹ hu iwa ọdaran to jọ idigunjale ati ijinigbe lori omi.

Idajọ naa ati ofin Anti-Piracy ti ọdun 2019 tun ti mu ki o rọrun lati fi oju awọn ole ori omi wina ofin ni Naijiria.

Ọjọ ti pẹ ti awọn ileesẹ ọkọ oju omi ti awọn olookowo maa n lo, ti n kesi ijọba Naijiria lati gbe igbesẹ, paapaa lati igba ti ajọ International Maritime Bureau ti sọ pe Naijiria lo ko ìdá aadọrun ninu ijinigbe to n waye lori omi, paapaa lori okun Gulf of Guinea.

Awọn eeyan mẹta naa wa lara awon mẹsan an ti wọn ti kọkọ fi ẹsun ijinigbe ati igbesunmọmi kan, fun ipa ti wọn ko lori bi awọn kan ṣe gba ẹgbẹrun lọna igba Dọla ($200,000), ki wọn o to tú awọn oṣiṣẹ ọkọ oju omi akẹru kan, to jẹ ti orilẹ-ede Equatorial Guinea, Vessel MV ELOBEY VI.

Agbejọro fun awọn mẹtẹẹta, Abimbola Akeredolu, sọ pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun, nitori owó itanran naa.Ile ẹjọ dá awọn mẹfa yooku silẹ, nitori pe ko si ẹri to tako wọn.