Helicopter crash in Lagos: Àbájáde ìwádìí ẹlikọ́pítà to já ni Opebi laipẹ yii ti jáde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ìgbìmọ̀ ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmba ti fi abájáde ìwádìí wọ́n síta lórí ẹlikọpítà to já ni Opebi nílùú Eko lọ́jọ́ kejìlélógójì, oṣù kẹjọ, ọdún 2020.

Iṣẹ̀lẹ̀ náà tó kan ẹlikọ́pítà Bell 206B lll pẹlu nọ́mba ìdánimọ 5N-BQW tí ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Quorum Aviation Limited ni wọ́n ti sàlàyè gbogbo ǹkan tó fa ìṣẹ̀ll ńlá ibi náà.

Ìwádìí fi han pé ẹlikọ́pítà náà ni ìwé to pé pérépéré ti o si yẹ láti má a rin lójú òfurufú ti o si múlẹ̀ títí di ọjọ́ kẹfa ọsù kẹjọ ọdún 2020.

Bákan náà ni kò si ẹ̀rí láti fi hàn pé ilé iṣẹ́ ẹlikọ́pítà náà kọ ìwé fún àjọ NCAA lati yọnda ọkọ ọ̀hun fún ìrìnàjò lẹ́yìn ti àsìkò to le rìn ti parí.

Kò tún sí ààyè epo tó tó fún ọkọ òfurufú ọ̀hun.

"Àbájáde ìwádìí náà lọ báyìí, pé " Wọ́n rọ epo kúnú ọkọ òfurufú náà lọ́jọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹjọ, ọdún, 2020, wọ́n ẹnjínì rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá fún àyẹ̀wò, bákan náà ni wọ́n tún wàá wò fún ogún ìṣẹ́jú ní ìlú Port Harcourt"

Wákàtí mẹ́tà àti ìṣẹ́ju mẹ́ẹ̀dógún ni ẹlikapítà náà le farada iṣẹ́ mọ, sùgbọ́n ó ìrìnàjò wákàti méjì àti iṣẹ́jú mọ́runlélógójì ni wọn rán.

Wọ́n taná si ẹ́njìnì rẹ̀ ní ààgo mẹ́sàn kọjá ìṣẹ́ju mẹ́ẹ̀dógún, ó sì gbéra ni aago mẹ́sàn kọjá ogún ìṣẹ́jú. Ó já ni aago méjìlá kọ́já ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá.

" Ko si epo kankan ninu ọkọ náà ńgbà ti ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe, bákan náà ni abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ dúró déédé lásìkò àbẹ̀wò lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Helicopter crash in Lagos: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti bẹ̀rẹ̀ àtúnkọ́ ilé tí bàlúù agbéra pá tó jábọ́ bàjẹ́ ní Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti bẹrẹ atunkọ agbegbe Opebi ti ọkọ baalu ẹlikọpita jabọ si ni ọsẹ to kọja.

Oluranlọwọ pataki fun gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile fi lede ni ori opo ikansiraẹni Twitter wọn.

Ninu atẹjade to fi lede naa sọ wi pe Gomina Sanwo Olu gbe igbesẹ naa lẹyin wakati mejidinlaadọta to jẹjẹ lati tun agbegbe Opebi ti baalu naa jabọ ṣe pada.

Aarin ile ni agbegbe Salvation road ni Opebi naa ni ọkọ ofurufu hẹlikọpita wo si, to si ṣe ọpọlọpọ ipalara fun awọn to wa ni agbegbe naa.

Eniyan mẹtẹẹta to wa ninu ọkọ baluu naa lo ti ku bayii, amọ eniyan meji lo kọkọ ku lẹsẹkẹsẹ ti iṣẹlẹ naa waye.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo Olu jẹjẹ lati ri wi pe awọn ogiri to wo naa di titun kọ pada.

Bakan naa lo ba awọn ẹbi ati ara ti ajalu naa ṣẹlẹ si kẹdun, pẹlu adura wi pe wọn ko ni rogun ibanujẹ mọ, ati wi pe Olorun yoo tu wọn ninu.

Helicopter crash in Lagos: Gbogbo arìnrìnàjò inú ẹlíkọ́pítà tó já ní Opebi ti tẹ́rí gbaṣọ!

Ìṣẹ́jú méjì péré tó máa fi bàlẹ̀ ni pápákọ̀ òfurufú ni ẹlikọ́pítà Quarom aviation já lulẹ̀ ní Opebi, Ikeja

Arinrinajo kẹta to wa ninu ẹlikọpita to ja lulẹ ni Opebi, Ikeja niluu Eko ko pada ye e, o ti rekọja s'alakeji.

Ajọ LASEMA ati agbẹnusọ ajọ to maa n wadii ọrọ to ni ṣe pẹlu ijamba lorilẹede Naijiria, Accident Investigation Bureau lo fidi ọrọ naa mulẹ.

Bakan naa, iroyin ti a ri ko jọ ni pe iṣẹju meji pere lo ku ki ẹlikọpita naa balẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed ti Eko lo di wọ̀ọ̀ nilẹ̀.

Nibayii, o tumọ si pe gbogbo awọn mẹtẹẹta to wa ninu ẹlikọpita naa lo ti ku.

Ajọ to ma n wadii ijamba ni Naijiria lo ṣawari apoti dudu, to wa ninu ẹlikọpita, to ja lulẹ ni agbegbe Ikeja, nipinlẹ Eko.

Awọn oṣiṣẹ ajọ AIB sọ pe ni nkan bi aago mẹta ọsan ni wọn ri apoti naa.

Alukoro ajọ naa, Tunji Oketunbi, sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii ohun to fa ijamba naa.

Ẹlikọpita naa, Bell 206, to ni nọmba idanimọ 5N BQW, jẹ ti ileeṣẹ Quorum Aviation lo ja lulẹ lati inu ofurufu wọ inu ogiri to la ile meji ni nọmba 16A Salvation Road, Opebi Ikeja ni Eko ni nkan bii agogo mejila abọ ọsan ọjọ ẹti.

Ilu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers, lo ti gbera, to si n bọ nipinlẹ Eko.

Awakọ baalu kan, oṣiṣẹ baalu kan, ati ero kan lo wa ninu rẹ.

Oludari ajọ apapọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, Ibrahim Farinloye, sọ fun BBC pe lati ibi idanilẹkọ kan nilu Port Harcourt ni ẹlikọpita naa ti n bọ.

Bakan naa lo sọ pe awọn olugbe inu ile ti ẹlikọpita naa ja lulẹ si, ti pada sile wọn.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ naa, LASEMA, Nosa Okubo sọ fun BBC pe eeyan meji lo ba iṣẹlẹ naa lọ ti ẹnikan si farapa.

Iṣẹlẹ ọhun waye lọsan ọjọ Ẹti ni ile to wa ni nọmba 16, Salvation, ni Opebi to wa ni Ikeja.

Kọmiṣọna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu sọ fun BBC lojuko iṣẹlẹ ọhun pe ni kete ti iroyin naa tẹ awón ọlọpaa leti ni awọn oṣiṣẹ rẹ tẹkọ leti lọ sojuko ọhun.

LASEMA sọ pe ọkunrin ni gbogbo awọn eeyan to ninu ọkọ ofurufu ọhun to jẹ ti ileeṣẹ Quorun Aviation ni ilu Eko.

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Olusunmade Olubunmi Damola sọ pe "iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni dede aago mejila kọja iṣẹju mẹrinla, a gbọ ariwo nla kan ninu ọfiisi wa to dun bi iro ibugbamu."

"Igba ti a sa jade ni a to ri pe ọkọ ofurufu ẹlikọpita lo ja lulẹ."

Damola sọ pe oun atawọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ yọ eeyan meji jade ninu ọkọ ofuru naa ṣugbọ ko ri aye yọ ẹnikan to ku tititi awọn adoola ẹmi fi de.

Awọn asọju ileeṣẹ ijọba ijọba to n ri si iṣẹlẹ pajawiri to wa lojuko ti iṣẹlẹ naa ti waye ni iwadii ti bẹrẹ lati ohun gan pato to fa iṣẹlẹ'naa.

Wọn ni wọn ko tii le sọ ibi ti ọkọ ofurufu na ti n bọ tabgi ibi to n lọ, ṣugbọn gbogbo eyii ni yoo di mimọ lẹyin iwadii.