You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayere Imam's wife murdered: Alayere dá sọ́rọ̀ ìyàwó Ìmáàmù àgbà tí wọ́n pa sínú ilé
Alayere ti ilu Ayere nijọba ibilẹ Ijumu, ipinlẹ Kogi ti sọrọ lori bi awọn afurasi oniṣegun ibilẹ kan ṣe pa iyawo Imaamu agba ilu Ayere, arabinrin Yemisi Baderu.
Iroyin taa gbọ ni wipe inu ile arabinrin naa to jẹ iya to n tọ ọmọ oṣu marun kan lọwọ ni wọn ti pa a loju ọkọ rẹ atawọn ọmọ wọn to dagba pẹlu ada.
Awọn akọroyin n sọ wipe ohun ti awọn ri ko jọ ni pe awọn oniṣegun ibilẹ ọhun ti n fa Imaamu naa leti lori iru awọn waasi to maa n ṣe ṣugbọn Alayere ko lee fidi eyi mulẹ.
Nigba ti BBC Yoruba ba Ọba ilu naa, Oba Jo Olubo sọ̀rọ̀, o ni "bi nka ba ṣẹlẹ keeyan fi ro ara rẹ wo, gẹgẹ bi ọba ko tii ṣẹlẹ ri lati bii ọgbọn ọdun, torinaa inu mi ko dun rara".
- Ọ̀fíìsì ni mo wà tí mo rí Hẹlikọ́ptà tó ń yí bírí bírí lójú òfurufú, àfi tí a gbọ́ gbàà! - Olùgbé Opebi l'Eko
- Wo ojú àwọn afurasí tó fipá bá Uwaila, akẹ́kọ̀ọ́ Uniben sùn tí wọ́n tún pa á sínúu ṣọ́ọ̀ṣì
- Ọlọ́pàá Funso ló fi ààyè sílẹ̀ fún mi láti sá kúrò ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Mokola - Sunday Shodipe
- Ìyàwó ilé lu ọmọ ọkọ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ogun
O fi kun un wipe ninu itan ilu Ayere ko tii ṣẹlẹ pe ki wọn lọ pa eeyan sinu ile rẹ, " a o tilẹ layaa rẹ rara".
Kabiyesi ni lai tilẹ kii ṣe ọba gan, gẹgẹ bii ẹlẹran ara, inu oun ko dun si i rara.
Ẹwẹ, Alayere jẹ ko di mimọ fun BBC Yoruba pe awọn ọlọpaa ti fi ọwọ ofin mu eeyan mẹta ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Igbesẹ wo lawọn alaṣẹ ilu ti gbe?
Nigba ti a bi Alayere pe ki ni ilu gaan ti wa ṣe lori ọrọ yii. Ọba Olubo ni ni kete ti oun gbọ ọrọ naa, ni ilana ibilẹ oun ti pe ipade lọkunrin lobinrin gbogbo awọn ijoye oun ti awọn si ti n gbe igbesẹ.
Bo tilẹ pe o ni ijọba ti gbe igbesẹ "ko to le di pe awa naa gbe igbesẹ, a gbudọ jẹ ki ijọba parii titiwọn ṣugbọn awa naa n ṣe eyi ti a lee ṣe laarin ilu".
Kabiyesi ni igbesẹ ti awọn n gbe, oun ko lee sọ ọ sita ṣugbọn o gbagbọ pe ati ti ijọba ati tawọn, gbogbo rẹ lo maa yọri si rere.
Ọba Olubo sọ nipa iru eeyan ti Imaamu ti wn pa iyawo rẹ yii jẹ pe dajudaju ki wọn to lee fi eeyan si iru ipo yẹn, o gbudọ jẹ eeyan daadaa torinaa o ni oun mọ wipe eeyan to dara ni Imaamu agba naa jẹ niluu.