Emir Of Zazzau: El-Rufai kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìdárò Emir Zazzau, Buhari, Babangida náà ń ṣèdárò

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iku doro, iku ṣeka, iku ṣe bẹẹ mu ẹni 're lọ. Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn eekan ilu mii n ṣedaro, Emir of Zazzau, HH Alh. Shehu Idris to jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọrin.

Ọjọ Aiku ni Emir naa wọ kaa ilẹ niluu Zaria nibi ti ẹgbẹlẹgbẹ eeyan ti pejọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun Emir Zazzau to di oloogbe.

Gomina Nasir El-Rufai lo fọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ nibi to ti ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ijọba yoo lọ si si ibi iṣẹ wọn lọjọ Aje ati ọjọ Iṣegun.

El-Rufai ni isinmi yoo wa lẹnu iṣẹ l'Ọjọbọ lati le kẹdun Alhaji Idris to papoda, bakan naa lo sọ pe wọn yoo gbe asia walẹ kaakiri ipinlẹ Kaduna fun imọyi Emir Zazzau to lọ.

Bakan naa ni Gomina El-Rufai sọ pe akanṣe adura yoo wa fun Emir to ku lọjọ kan naa.

Aarẹ Buhari sọ pe Emir to ku kopa ribiribi lati rii pe iṣọkan ati ibagbepọ alaafia wa laarin awọn ọmọ Naijiria.

Aarẹ ni gbogbo agbara ti Eledua fi jinki Alhaji Idris lo fi sin awọn eeyan rẹ ki ọlọjọ to de.

Ero pọ biba nibi isinku Emir ilu Zazzau, koda awọn oludaro kọ lati tẹle ilana itakete si ara ẹni nitori ajakalẹ aarun coronavirus.

Aya aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari naa wa lara awọn to n ṣedaro Emir Zazzua to lọ.

Aisha sọ loju opo Twitter rẹ pe Alhaji Idris ti ṣe tiẹ ninu idagbasoke awujọ ko o to dagbere faye.

Aisha gbadura pe ki Eleduwa dẹ ilẹ fun ẹni 're to lọ.

Aṣiwaju Bola Tinubu naa ko ṣai fi iṣẹ ibanikẹdun trẹ ranṣẹ si idile Emir Zazzau to filẹ ṣaṣọ bora.

Tinuubu sọ pe Alhaji Idris kii ṣe ẹlẹyamẹya, bẹẹ si ni o kopa ribiribi ninu iṣọkan orilẹede Naijiria ki o to jade laye.

Olori orilẹede Naijiria nigba kan ri, ajagun fẹyinti, Ibrahim Babangida naa kẹdun pẹlu gomina ipinlẹ Kaduna lori iku Emir Zazzau.

Babangida ni Emir Zazzau gbiyanju lati rii pe ipinllẹ Kaduna wa ni iṣọkan pẹlu ọgbọn inu ti Eleduwa fi kẹ ẹ.