Oluwo: Èmi l'ọba lórí òrìṣà, oṣó àti ajẹ́, Olorì tuntun tó ń bọ̀ lẹ́tikẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọba Abdulrasheed Akanbi, Oluwo mti ilẹ Iwo ti ṣalaye ni kikun fun BBC Yoruba idi ti o fi paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo oriṣa kuru laafin Iwo.

Oluwo sọ pe oun ni aṣoju Olodumare ni aafin ilẹ Iwo, nitori naa oun ko le maa bọ oriṣa tabi fi ori balẹ fun oriṣa ni aafin.

Ọba Akanbi ni oun ni alaṣẹ lori oriṣa, o ni oun kii ṣe ekeji oriṣa nitori Eledumare loun n ṣoju nisin yii.

''Emi ni ọkọ oṣo, emi ni ọkọ ajẹ, emi ni ọba to ba lori ohun gbogbo ni ilẹ Iwo, nitori naa mi o le tun maa bọ oriṣa laafin,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.

Oluwo ni ile isẹnbaye ni o yẹ ki awọn oriṣa wa nitori nnkan ti yatọ si ti aye ọjọun nigba ti wọn bẹrẹ si ni bọ awọn oriṣa naa.

Lori bo ya wọn ṣe etutu ki wọn to ko awọn oriṣa naa kuro laafin, Oluwo ni ko si etutu kankan nitori ṣiṣe etutu tumọ si ibọriṣa eyi t'oun ko le ṣe.

Oluwo ni ''Ọba kii pe meji laafin, mi o le jẹ ọba ki n tun maa fori balẹ fun nnkan mii laafin.''

O ni niwọn igba ti oun ṣi wa lori itẹ gẹgẹ bi Oluwo ti ilẹ Iwo, ko si ẹni ti yoo bọ oriṣa laafin Iwo.

Oluwo ko ṣai sọ nipa Olori mii to n bọ laafin Iwo lẹyin ti o ti kọ Olori tẹlẹ, Chanel Chin silẹ.

''Olori mii ti yoo rọpo Chanel Chin ti wa ni ṣẹpẹ ṣẹpẹ bayii, eleyi lẹtikẹ,'' Oluwo lo ṣalaye bẹẹ.

Oluwo ni Olori to n bọ lọna ''lẹtikẹ, nla ni eleyi, o ja gbogbo 'scale' patapata.''

Oba Akanbi ni ikan nla ni Olori to n bọ, o ni o lagbara gan an.

Ìdí tí mo fi gbàdúrà ìyàwó bíi Chanel Chin fáwọn tó d'ẹ̀bi ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ rù mí rèé - Oluwo

Oluwo ni oun n fẹ olori ti yoo nifẹ awọn eeyan Iwo ni, ti o si ṣetan lati sin wọn gẹgẹ bi oun ti oun jẹ ọba ti n ṣe.

''Olori temi gbọdọ de ade. Olori to n de ade laafin ko gbọdọ jẹ ọdalẹ,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.

Ọba Akanbi ni nnkan lo wa lọkan Chin to fi n ka gbogbo ohun to n ṣẹlẹ laafin nigba to wa nibẹ.

Oluwo of Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi tun ti sọ oko ọrọ lori iyapa to waye laarin rẹ ati Olori rẹ tẹlẹ, Chanel Chin.

Oluwo ṣalaye idi to fi gbadura iru iyawo bi Chanel Chin fawọn to n bu ẹnu ẹtẹ lu lori ọrọ naa.

Ọba Abdulrasheed Akanbi ni lati ọjọ akọkọ ti Chin to wọ aafin Iwo lo ti bẹrẹ si ni ka gbogbo ohun to n ṣẹlẹ laafin silẹ.

''Ṣe ifẹ niyẹn?'' Oluwo lo beere ibeere yii.

O ni ko yẹ ki iyawo jẹ ko maa ṣe bi ọtẹlẹmuyẹ fun ọkọ rẹ.

Oluwo ni ''emi ti mu iyẹn kuro ninu aye mi, mo ti kọ ọ silẹ.''

''Adura ti mo n gba fawọn to dami lẹbi lori ọrọ naa ni pe ki Eleduwa fun awọn ati ọmọ wọn ni iru iyawo bii ti Chin.

Oluwo tun sọ pe o lodi ki Ọba alaye maa bọ oriṣa laafin, nitori naa, ko ṣeeṣe fun oun lati maa bọ oriṣa.

O ṣalaye pe ọba alaye n ba Eleduwa jẹ orukọ papọ, idi niyii ti ko fi gbọdọ maa fori balẹ fun oriṣa kankan.

Oluwo ni niṣe lo yẹ ki atunṣe ilana ode oni ba awọn ọdun isẹnbaye nilẹ Yoruba ki o le di ohun tawọn maa fi owo wo.

Ọba Akanbi ni eeyan ko le maa ta epo si ojubọ ki o si maa reti awọn eeyan lati wa woran.

Ninu itan ilẹ Yoruba, aafin Iwo lasiko temi ni awọn ẹleṣin musulumi ati kristẹni wa gbadura laafin fun igba akọkọ.

O ni ko ṣeesẹ ki musulumi wa lọ gbadura nibi ti ko ba jẹ mimọ, bakan naa lawọn ọmọ lẹyin kristẹni.

Oluwo ni eleyi ṣẹlẹ nitori ko si awọn ooṣa kankan mọ laafin.

''Emi ni mo paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo oriṣa to wa laafin Iwo kuro nigba ti mo jọba tan,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.

O ni ọba meji ko le wa laafin papọ, ati pe oun jẹ aṣoju Eleduwa to da gbogbo aye.

Oluwo ni Olodumare lo ni aafin, ki ṣe awọn oriṣa nitori naa eeyan ko le sin ọlọrun pẹlu mamoni.

Ọba Akanbi ni lootọọ ni oriṣa bibọ wa ninu itan Yoruba ṣugbọn o yẹ ki wọn ti ko gbogbo awọn oriṣa yii sinu ile iko nnkan iṣẹnbaye si bayii.