You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yinka Ayefele: Aláàánú kan fi kẹ̀kẹ́ tuntun ta akọrin Tungba lọ́rẹ
Gbajugbaja olorin juju nni, Yinka Ayefele ti le e naro bayii lori ẹsẹ rẹ to ba wu u.
Eyi ko si ṣẹyin kẹkẹ igbalode kan to ni awọn eroja irọrun to ṣe e yi si ọtun ati osi, oke ati ilẹ, ibi to ba si wu eeyan, lo le e yi kẹkẹ naa si.
Yinka Ayefele, lo kede pe o ti rọrun fun oun bayii lati rin pẹlu kẹkẹ tuntun naa loju opo Instagram rẹ lọjọ Ẹti.
O fikun pe ẹlẹyinju aanu kan, to pe orukọ rẹ ni Hon Obama Oludare Akande lo fun oun ni kẹkẹ tuntun naa fun oun lati orileede Amẹrika.
Ayefele ni "Mo le duro kọrin nibikibi bayii pẹlu kẹkẹ tuntun naa, 'action' bẹrẹ bayii, mo dupẹ pupọ lọwọ Dare Obama."
Akọrin Tungba naa fikun pe "irọrun de ba mi gidi bayii pẹlu kẹkẹ tuntun naa, Dare Obama tun ti fun mi ni ireti lati rin pada,."
O wa gbadura fun Alaanu naa pe ko ni mọ inira nile aye rẹ.
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ tí ìrìnàjò bàálù sílẹ̀ òkèèrè yóò bẹ̀rẹ̀ padà síwájú
- 'Mi o fọ́wọ́ sí bí ọmọ mi, Kiddwaya ṣe lọ fún BBNaija - Terry Waya
- Ọlọ́pàá Funso ló fi ààyè sílẹ̀ fún mi láti sá kúrò ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Mokola - Sunday Shodipe
- Kìí ṣe torí ìbèérè ni mo ṣe bẹ́ Fani-Kayode, àwọn akẹẹgbẹ́ mi ló kó mi láyà jẹ - Eyo Charles
Bẹẹ ba gbagbe, o ti le ni ogun ọdun ti gbajumọ akọrin ẹmi naa ti padanu ọ̀pá ẹyin rẹ, ti ko si lee rin mọ nitori ijamba ọkọ to waye.