You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
INEC: Yinka Ayefẹlẹ jẹ adari tootọ ni eto iroyin
Ajọ INEC ti ni gbajugbaja olorin, Yinka Ayefele jẹ adari tootọ ni eto iroyin, iṣẹ ṣise ati idagbasoke awujọ lorilẹede Naijiria.
Yinka Ayefele ni alaga ati adari ile iṣẹ Iroyin Fresh FM ni ilu Ibadan.
Ajọ INEC sọ eyi lasiko ti wọn fi oye aṣoju ajọ naa da Yinka Ayefele lọla láti ẹnu igbakeji ẹka to n risi idanilẹkọ lori kaadi idibo, Abilekọ Lakunuya Dorothy Bello ni olu ilu Naijiria, Abuja.
Pẹlu oye yii, ajọ naa ni ireti wi pe Ayefele yoo lo ipo rẹ lati mu ibugboro ba iroyin tootọ lasiko idibo gbogbogbo ti ọdun 2019.