You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yinka Ayefele di bàbá ìbẹta
Gbajugbaja olorin ni to tun jẹ oludaleeṣẹ redio silẹ, Yinka Ayefẹlẹ ti di baba ibẹta bayii.
Gẹgẹ bii iroyin ti o n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo, loni ni Yinka Ayefẹlẹ tu iroyin ayọ yii fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio rẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe laipẹ yi ni iroyin kan ti kọkọ jade pe iyawo onkọrin yii bimọ ṣugbọn ti oun pẹlu tete bọ si igboro lati salaye pe iyawo oun ko tii bimọẸ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, n kò bí ìbẹta - Yinka Ayefẹlẹ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ rẹ to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe ori oju opo ikansiraẹni Whatsapp to jẹ tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Redio rẹ lo ti tu iroyin ayọ naa fun awọn oṣiṣẹ rẹ loni.
Bakan naa ni Yinka Ayefẹlẹ funrarẹ ti kede rẹ loju opo Facebook rẹ pe orin ijo ọmọ mo ji fowurọ mi jo ti oun kọ ninu awo orin oun kan lọjọ ọjọsi ti di otitọ bayii.