You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oluwo: Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá sọ̀rọ̀ takò mí
Oluwo ti Ilu Iwo, Ọba Rasheed Akanbi ti bu epe lu ẹnikẹni to ba da a lẹbi lori bi igbeyawo rẹ ati olori tẹlẹri, Chanel Chin.
Ojú òpó Instagram ni Oluwo ti Ìlú Iwo ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn kan ṣe dá a lẹ́bi lórí bí ìgbéyàwó rẹ̀ pẹlu olori naa ṣe túká.
Eyi ko sẹyin bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu ọba naa lori ẹrọ ayelujara lori bi o ṣe tu igbeyawo naa ka pẹlu Chanel Chin.
Oluwo ni oun gbiyanju titi oun ninu igbeyawo naa, ati wi pe ki iya to jẹ oun jẹ ẹnikẹni to ba da oun lẹbi. O ni bi oun ba ṣe ibi ninu idapọ to ṣẹṣẹ tu ka yii, ki Ọlrun da oun lẹjọ ṣugbọn bi oun ba jẹ olododo ki Ọlọrun jẹ ki oun pẹ titi lae.
Laipẹ yii Oluwo ti Ilu Iwo, Ọba Rasheed Akanbi jajatuka pẹlu iyawo rẹ ti awọn mejeeji si taun si ara wọn lori ẹrọ ayelujara.