Ààrùn coronavirus tó ràn mí jẹ́ kí n mọ̀ pé àlààfo díẹ̀ ló wà láàrin ikú àti ìyè - Lola Alao

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja oṣerebinrin, Lola Alao sọ pe ina aarun coronavirus ran mọ oun, ṣugbọn oun ti gbadun bayii.

Ninu ọrọ kan to kọ sori ayelujara Insatgram rẹ lo ti sọ pe ọpẹlọpẹ Ọlọrun, to ra oun pada.

O ni "aisan naa wọ mi lara de inu egungun mi, debi pe mi o le gboorun ohunkohun. "

O ni ẹru ba oun debi pupọ, nitori pe oun ni awọn ọmọ ti oun n tọju.

"Mi o ro pe ẹnikẹni fẹ ẹ ni imọlara boṣe ri, lati wa ni ibudo iyasọtọ, lai ri awọn ẹbi rẹ.

"Mi o mọ nkan ti ẹ ti gbọ nipa Covid-19 o, ṣugbọn mo n sọ fun yin loni pe, o buru ju bi ẹ ṣe le ro lọ."

O fikun ọrọ rẹ pe ki awọn ololufẹ oun o ma a ranti pe aarun naa ṣi wa, lai fi ṣe pe awọn eeyan kan ko bikita mọ.

"Alaafo kekere lo wa larin iku ati iye. Ẹ jọwọ, ẹ ma a huwa daadaa si gbogbo eeyan to wa ni ayika yin."