Police officer raiding illegal cockfight : Àlàyé rèé bí ọlọ́pàá ṣé kàgbákò ikú gbígbóná lọ́wọ́ àkùkọ

Hmmmn. Eledua ma jẹ ka rinrin arinfẹsẹkọ. Agba adura ma ni.

Ọrọ yii difa farakunrin ọlọpaa ilẹ Phillipines kan ti akukọ tawọn eeyan fi n ja ṣeku pa.

O ya yin lẹnu pe akukọ ṣe iku pa ọlọpaa abi? Ododo kuku ni iṣẹlẹ yii to si waye lagbegbe ariwa Samar.

Abẹ ti wọn so mọ akukọ naa lẹsẹ lo bẹ kasan arakunrin Christine Bolok nigba tawọn ọlọpaa fẹ lọ mu awọn to n fi akukọ ja.

Ẹjẹ bẹrẹ si ni tu jade lara rẹ lẹyin ti abẹ bẹ ẹ lẹsẹ.

O pọ debi pe wọn sare gbe e lọ si ile iwosan ṣugbọn o gbẹmi mi ki wọn to de ibẹ.

Fifi akukọ ja jẹ nkan ti ijọba fofin de lasiko Coronavirus yi.

Lọpọ igba awọn to n fi akukọ ja a maa so abẹ to mu mọ awọn akukọ lẹsẹ.

Akukọ to ba le fi abẹ ti wọn so mọ ọ lẹsẹ yi bẹ ikeji rẹ lo jawe olubori ninu idije yi.

Ọpọ owo lawọn eeyan a si maa fi ta tẹtẹ lori irufẹ ija akukọ yi ni ilẹ Phillipines.

Ọga ọlọpaa lagbegbe ti iṣẹlẹ yi ti waye,Arnel Apud sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe iṣẹlẹ naa fọwọkanilẹmi to si ni ''o kọja ohun ti eeyan le ṣalaye''

''O jẹ iyalẹnu fun mi nigba ti wọn kọkọ fi to mi leti. Igba akọkọ ree ti maa ri iru iṣẹlẹ bayi lati nkan bi ọdun marundinlọgbọn ti mo ti wa lẹnu iṣẹ yi''

O sọ bakan naa pe oun ti fi ikini ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi ọlọpaa to padanu ẹmi rẹ yi.

Eeyan mẹta, akukọ meje ati awọn nkan ija mii to fi mọ owo ilẹ Phillipines to to dọla mọkanla lọlọpaa ri gba nigba ti wọn yabo ibi ti wọn ti n fi akukọ ja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: