You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seun Kuti: Seun, ọmọ Fela, lóòtọ́ lóun yìnbọn níbi yánpọnyánrin pẹ̀láwọn tó wa ọkọ̀ dí ilé òun, àtipé bó jẹ́ ìjọba àpapọ̀ ló ṣ'àìtọ́ nílé òun ìbọn á sọ
Seun Kuti, ọmọ agba ojẹ olorin Fẹla Kuti ti ṣalye faraye gbọ pe nipa wahala to ṣẹlẹ ni agbegbe rẹ lalẹ ọjọ Satide to fa yanpọnyanrin.
O ni lootọ lawọn yinbọn nibi yanpọnyanrin naa ṣugbọn awọn to ti ika bọ oun lẹnu lo mu ki oun faraya.
Ni owurọ ọjọ Aiku ni iroyin jade pe Seun da wahala silẹ nibi apejẹ kan lagbegbe Ikẹja to si tun fa ibọn yọ.
Seun kuti ni lootọ loun n gbe ni agbegbe kan ti wọn pe ni Akin Oshiyẹmi lagbegbe Ikẹja ti oun si ti wa nibẹ fun bi ọdun mọkanla bayii.
O ni awọn eeyan kan ti n dokoowo ile itura si adugbo wọn ni wọn n fa inira fun oun atawọn aladugbo oun.
Seun ni awọn eeyan kan lo bẹrẹ apejẹ alariwo nla kan ni adugbo oun lati owurọ bi agogo mẹsan abs owurọ, ti wọn ko si dawọ rẹ duro di aṣalẹ.
Ṣeun ni bakan naa ni awọn to wa nibi apejẹ naa wa ọkọ di gbogbo ile ti awọn to n gbe ladugbo naa ko si ri aye ati wọle tabi jade.
O ni nigba ti oun fẹ jade kuro nile loun rii pe wọn ti gbe ọkọ di oun ti oun si ti n wa awọn to wa ọkọ di oun mọle ti onitọun si yọju to n pe ki oun ṣimẹdọ loun ba fi igbaju daa lohun.
O ni awọn alamojuto abo nibi ayẹyẹ taraalu n pe ni bouncers ni wọn kọkọ wa ba oun to si n halẹ pe oun yoo da sẹria fun oun lo fa wahala.
Ọmọ agba olorin naa ṣalaye pe lootọ ni awọn ṣina ibọn bolẹ, oun o si sa fun ẹnikẹni o nitori pe adugbo oun loun wa, ẹnikẹni to ba si ṣe aṣemaṣe, awa maa da sẹria to tọ fun un ni.
Seun ni bo ba jẹ ijọba apapọ gan lo wa si ile oun lati wa da wahala silẹ, tabi mu oun lai gba iwe aṣẹ, ohun maa ṣina ibọn bolẹ funwọn ni.