Shiloh 2020: Oyedepo ní òun kò le tòṣì láéláé! Ẹni tó bá ń bínú kàn ń bínú lásán ni

Oludasilẹ ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners, Biṣọọbu David Oyedepo tun ti sọ pe oun ko le toṣi laelae!

Biṣọọbu Oyedepo sọrọ yii nigba ti o n waasu nibi akanṣe eto ọlọdọọdun ijọ Winners, Shiloh 2020 niluu Ota, ipinlẹ Ogun.

Biṣọọbu Oyedepo ni majẹmu ti Ọlọrun ti la kalẹ ninu iwe mimọ ti oun n tẹle ko le jẹ ki oṣi mọ ile oun laelae.

O ṣalaye pe niwọn igba ti orun ba n yọ loke ti ilẹ si n su u, majẹmu to sọ oun di ọlọrọ ko le yipada laelae.

Biṣọọbu Oyedepo ni Ọlọrun sọ fun oun pe ilọrọ ninu Oluwa kii ṣe ileri, kii sii ṣe ọrọ adura ati aawẹ. Ti eeyan ko ba ko ipa tirẹ, Ọlọrun naa ko ni ṣe ohun kan.''

''Nigba naa ni mo ke Yeeeehhh! Mo o le toṣi laelae. Ẹni to ba fẹ lọrọ ninu Oluwa ko gbọdọ fi idamẹwa ati ififunni ṣere,'' Oyedepo lo sọ bẹẹ.

Ọlọrun tun sọ ohun miiran fun mi lẹyin ti mo ka iwe ti Kenneth ati Gloria Copeland lori ilọrọ ninu Oluwa tan.

Oyedepo ni: ''O sọ fun mi pe bi Oun ṣe maa n ṣi ferese ọrun si awọn eeyan naa ni Oun maa ṣi ferese ọrun sori ileeṣẹ.

Apẹẹrẹ iru rẹ to wa ninu Bibeli ni Abarahamu to san idamẹwaa lori gbogbo ohun to ko bọ lati oju ogun.

Biṣọọbu Oyedepo ni lati igba naa ni ijọ Winners ti bẹrẹ si ni san idamẹwaa eyi ti o si n jẹ ki ferese ọrun maa tubọ ṣi sori ijọ naa sii.

Ìjọ 10,000 tuntun ni a dá sílẹ̀ láì gba owó ọrẹ lọ́wọ́ ọmọ ìjọ lásìkò àrùn Coronavirus- Oyedepo

Oluṣọ agutan agba ijọ Living Faith, pasitọ David Oyedepo ti ṣi aṣọ loju eegun pe bo tilẹ jẹ arun Covid-19 ba gbogbo agbaye finra lọdun 2020, ẹka ẹgbẹrun mẹwaa tuntun ni ijọ naa ṣi lai gba kọbọ lọwọ ọmọ ijọ kankan.

Oyedepo lo sọ ọrọ naa lọjọ Abamẹta to jẹ aṣekagba ipade adura Shiloh, eyii to maa n waye lọdọdun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "bo tilẹ jẹ pe arun naa n dun mọhuru mọhuru, ẹgbẹrun mẹwaa ẹka tuntun ni ijọ yii ṣi lai gba owo ọrẹ kankan, a o fi oju imu eṣu danrin."

Nigba to n sọrọ ṣaaju nipa arun Covid-19, Oyedepe sọ pe oun ko gbagbọ pe Covid-19 kan wa nibi kankan .

O ni "ti wọn ba bere lọwọ mi nipa Covid-19, esi mi ko ju pe, Covid-19 wa, bẹẹ ni ko si."

"Ẹni to ba gbagbọ ninu Covid-19 ni arun naa yoo ran, ẹni ti ko ba gbagbọ ninu rẹ ko ni lugbadi arun naa."

Lẹyin naa lo sọ siwaju si pe ọpọ eeyan lo ti ri iwosan gba lọwọ arun Covid-19 ninu ijọ oun.