Ode/Isinigbo land Crisis: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kéde òfin konile-o-gbele ní Ode ati Ishinigbo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ofin konile-o-gbele oni wakati mẹrinlelogun ni ilu Ode ati Ishinigbo, to wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Akure.

Igbele naa ti wọn ni yoo bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ ni ijọba ipinlẹ Ondo kede lẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ laarin ilu memeji lati nnka bi ọsẹ kan sẹyin.

Ninu atẹjade ti kọmiṣọna ọrọ to n lọ, Donald Ojogo fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni gomina Rotimi Akeredolu ti dari awọn agbofinro lati bẹrẹ iwadii lori ohun to fa iṣẹlẹ naa.

Atẹjade ọhun fi kun pe wọn ti bẹrẹ ti n tọpasẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu rogbodiyan naa.

Bakan naa lo ni wọn ti paṣẹ fun awọn agbofinro lati ri daju pe ofin konile-o-gbele naa mulẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Ode ati Ishinigbo nikan ni ofin ọhun wa fun, Ojogo sọ pe ko ni si kalọ kabọ awọn eeyan ni ilu mejeji titi di igba ti ijọba yoo tun kede igbesẹ tuntun lori ọrọ ọhun.

Jàǹdùkú ìlú méjéèjì jó ààfin ọba àti ọkọ̀ níná

Ibi ti a ba pe ni ori, ẹnikan kii fi ibẹ tẹlẹ ni Yoruba n wi, bẹẹ si ni wọn ni Ọba lo ba lori ohun gbogbo.

Amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn ọba alaye nilu Ode ati Isinigbo ti wọn mule tira wọn nijọba ibilẹ Ariwa Akure nipinlẹ Ondo.

Idi ni pe awọn ilu mejeeji lo n doju ija kọ ara wọn nitori aawọ ilẹ, ti ọrọ naa si ti dogun dọdẹ, koda, wọn ti gbe ara wọn lọ sile ẹjọ pẹlu.

Sugbọn kaka ki wọn duro de idajọ ileẹjọ, se ni wọn doju akọtun ija kọ ara wọn bẹrẹ lati ọsẹ to kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọba ilu Ode lo ni oun lo ni ilẹ kan to wa ni agbegbe Isinigbo tawọn eeyan ti kọle le lori, to si ni ki wọn wa sanwo fun ilẹ naa.

Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye fun awọn akọroyin, Ajagunode tilu Ode, Ọba Sunday Boboye ni oun ti gba idajọ lori ilẹ naa lọdun 2017 ati 2019, tawọn eeyan Isinigbo ko si gbe igbesẹ lati tako idajọ ọhun nile ẹjọ Kotẹmilọrun.

O ni dipo eyi, se ni awọn ọdọ ilu Isinigbo wa ka oun mọle lọsẹ to kọja pẹlu ohun ija oloro.

O ni deede aago mejila oru ni wọn gunlẹ si aafin oun lati kọlu oun, ori ogiri aafin si ni oun ati olori oun meji gba salọ.

"O to awọn janduku mẹwa ti wọn ya bo aafin mi pẹlu awọn ohun ija oloro, ti wsn si n beere pe nibo ni Kabiyesi wa?

Wọn ba gbogbo aafin mi jẹ patapata, ta si ti ko wa si aafin tuntun bayii amọ alẹ ọjọ Aje tun ni wọn tun ya wa ba wa lẹẹkan si.

Ajagunode fikun pe igba karun tawọn janduku naa yoo wa ka oun mọ aafin ree lati igba ti aawọ ilẹ naa ti bẹrẹ. "

Asọ kansoso lo ku fun mi laye lọrun bayii, wọn ti jo gbogbo dukia mi, to fi mọ awọn ọkọ ayọkẹlẹ mi ati eyi ti mo sẹsẹ ra ni osu mẹta sẹyin."

O fikun pe oun ti fi ọrọ naa to ijọba atawọn agbofinro leti nipa awọn ikslu ojoojumọ yii, oun si n fẹ ki wọn gba oun ati ẹbi oun ki oun ma baa ku lojiji.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ yii, Igbakeji akọwe fun agbegbe Isinigbo, Ọmọọba Joseph Akinsilu naa fi ẹsun kan Ajagunode pe o ko awọn janduku wa si aafin ọba awọn lati kọlu.

O ni isẹlẹ naa waye mọjumọ ọjọ Ẹti oni, ti Ọba awọn si wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

"Ọba wa wa ni coma bayii, wọn ti jo aafin atawọn ọkọ ọba wa, ti ọba wa si n gbọn, koda ile ti wọn bajẹ ni agbegbe wa le ni ọgọjọ, to fi mọ ile temi gan alara."

Akinsilu salaye pe Ajagunode lo kọkọ gbe awọn lọ sile ẹjọ lori ilẹ ti awọn ti kọle le lori, to si ni kawọn wa san ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lori ilẹ naa.

"Bi o tilẹ jẹ pe a ko jẹbi bọ lati ile ẹjọ, se ni Boboye tun tun ẹjọ pe nile ẹjọ naa dipo ko pe ẹjọ kotẹmilọrun, a si n rọ ijọba ki wọn gba wa lọwọ rẹ.

Nigba ti BBC Yoruba kan sileesẹ ọlọpa ipinlẹ Ondo, Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Ondo, Leo Ikoro salaye pe lootọ ni ikọlu mejeeji naa waye ni ọsẹ to kọja ni aafin Ajagunode, ti ikọlu miran si tun waye mọjumọ ọjọ Ẹti ni aafin ọba Isinigbo.

O wa fọwọ gbaya pe ileesẹ ọlọpaa yoo se iwadii to yẹ nipa awọn ikọlu yii, ti wọn si tun ti n saayan lati ri pe alaafia pada si agbegbe mejeeji naa.