Ooni Adeyeye: Ọmọ Nàìjíríà Mílíọ̀nù márùn ún yóò jànfàní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ látọ̀dọ̀ Arole Oodua ti Ile Ife

Arole Oodua to tun jẹ Ọọni ti Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ọjaja II ti ṣi aṣọ loju akanṣe eto iranwọ owo ileewe to pe akọle rẹ ni "Ooni of Ife Tertiary Tuition Fund" eyi ti wọn yoo fi doju kọ sisan lara owo ileewe akẹkọọ miliọnu marun jakejado awọn fasiti Naijiria.

Nigba to n ṣi aṣọ loju akanṣe eto naa ni aafin rẹ, Ile Oodua ni ilu Ile Ifẹ, Ọọni kede ipo aidaa ti ọrọ aje orilẹede yii wa eyi to si jẹ ohun to gbe oun ninu lati ṣeranwọ fun awọn akẹkọọ ki wọn lee pada sẹnu ẹkọ wọn tori o fi aidunu rẹ han si ipo ti ọpọlọpọ akẹkọọ ile ẹkọ giga wa.

Ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,000) o kere tan ni Arole Oodua ṣe leto fun miliọnu marun akẹkọọ fun ọdun mẹrin gbako o si ṣalaye pe eto iranwọ yii yoo maa gbe miliọnu marun mi lọdọọdun.

Ọọni to ṣalaye pe riro awọn ọdọ lagbara ti jẹ afojusun oun tipẹ ni ori tentele ipojude ni Naijiria joko le o bi wọn ko ba doju kọ iṣoro awọn akẹkọọ.

"Mo n ṣe agbekalẹ eto iranwọ fun ẹkọ yii lati ṣatilẹyin fun ohun ti ijọba n ṣe. Abo ko si fun wa rara bayi. A ni lati ge eto ode kuru ki a si koju mọ riro awọn ọdọ lagbara. O san lati duro sile tun orilẹede yii ṣe ju ki a maa sa kuro nilu lọ".

Ọọni fi kun un wipe "gbogbo wa la ni imọlara ibinu awọn ọdọ lasiko iwọde #EndSARS, a si gbudọ bẹrẹ si ni mu wọn kopa gidi bayii".

Bakan naa, Ọọni sọ pe Covid-19 ti sọ ọpọ ọdọ atawọnobi wọn di alainiṣẹ lọwọ atipe ifasẹyin ọrọ aje yii tun jẹ iṣoro mii to ṣakoba fun awọn ọdọ Naijiria.

Ṣaaju akoko yii, Ọọni ni oun ti n ṣeranwọ owo ileewe tẹlẹ to fi mọ ẹkọṣẹ ati riro ọdọ lagbara "ṣugbọn mo n ṣe eyi lati tun ko ọpọlọpọ awọn ti yoo janfani mọ wọn.

Lorii bi owo tabua yii yoo ṣe jade, Ọba Adeyeye ni ọlọdani atawọn ileeṣẹ nile ati loke okun lawọn yoo kan si fun aṣeyọri igbesẹ naa.

Lori iyanṣẹlodi ẹgbẹ ASUU, Ọọni fi aridaju han pe yoo wa sopin laipẹ tori awọn lọba lọba ti da si i.

Ọọni tun fi idaniloju rẹ han fun araalu pe ijọba ati ẹgbẹ ASUU ti fẹẹ pari yiyanju awọn ibi ti fa ki n faa wa lori ọrọ yii.