Seyi Makinde ṣèlérí owó oṣù kẹtàlá fáwọn òṣìṣẹ́ Amotekun l' Oyo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Alaga ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju ti ṣalaye pe, awọn osisẹ ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Õyọ yoo gba owo oṣu.

Eyi si lo tako igbagbọ awọn eeyan kan pe ikọ naa ko ni gba owo oṣu.

Nigba to n dahun awọn ibeere lori eto ileeṣẹ redio kan ni ilu Ibadan, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju sisọ loju ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ṣalaye pe, Gomina Seyi Makinde ti pasẹ fun awọn alaṣẹ ikọ naa lati ṣe eto gbogbo nipa riri daju pe, eto to fun awọn oṣiṣẹ ikọ Amotekun lati gba owo oṣu wọn, ki ọdun Keresimesi to waye.

Bakan naa lo fi kun un pe, ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo san owo oṣu kẹtala fun awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ.

Alaga ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ tun ṣalaye pe awọn ọmọ ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Õyọ yoo gba owo oṣu.

Kò bá àṣà wa mu kí obìnrin máa kó ọmú síta! ẹ̀ báà bú mi di ọ̀la - Ọ̀gá Amotekun l'Osun

A ò gbé Amotekun kalẹ̀ láti máa yọjú sí ọ̀rọ̀ tí kò sí lábẹ́ òfin àgbékalẹ̀ rẹ̀

Ajọ to n ṣakoso ikọ alaabo nilẹ Yoruba, Amotekun, DAWN Commission, ti ni aṣigbọ ni awọn eeyan gbọ ọrọ ti ọga ikọ Amotekun ni ipinlẹ Osun sọ.

O jẹ ko di mimọ pe irọ ni awọn ri ọrọ naa si ati gbigbe ọrọ ti ko tọ sori afẹfẹ paapaa bo ṣe bẹrẹ si ni tan ka torinaa awọn ti gbe ọrọ tawọn jade lori rẹ.

"Iṣẹ ati ojuṣe amotẹkun lawọn ipinlẹ Guusu-Iwọ Oorun Naijiria tii ṣe ilẹ Yoruba ti wa ninu alakalẹ ofin to ti agbekalẹ rẹ lẹyin ireti siwa pe wọn yoo ṣe ni ibamu pẹlu ofin naa lai foju di ẹtọ ẹnikẹni".

Ajọ DAWN ṣalaye wipe ihuwasi aṣa ati ede awọn to n gbe lẹkun Guusu-Iwọ Oorun yatọ si idi ti wọn if gbe ikọ Amotekun kalẹ.

"Lati ri aridaju ẹtọ ati sọ̀rọ̀ sita, didaabo bo ẹmi awọn eeyan ati lapapọ, imugbooro ilẹ̀ Yoruba, la fi da ikọ Amotkun silẹ".

Wọn ni nitorinaa, awọn yalaṣ to tọ lawn ipinlẹ yoo koro oju si aibọwọ fun ẹtọ awn araalu eyi ti ik Amotẹkun kankan ba ṣe si wọn.

Àwọn ohun tó bá lè fa ìwà ọ̀daràn bíi aṣọ ìwọ̀kuwọ̀ ló yẹ ká ti ọwọ́ rẹẹ̀ baṣọ - Amotekun Osun

Ọga agba ikọ Amotekun ni ipinlẹ Osun, Amitolu Shittu ti sọ pe o yẹ ki awọn ẹṣọ alabo dẹkun bi awọn ọdọbinrinṣe ṣe maa n wọ aṣọ to ṣi ara silẹ lawujọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwerọ kan, o ni awọn iwa bii ki obinrin maa wọ aṣọ to ṣi ara silẹ le fa awọn iwa ọdaran bii ifipabanilkopọ ati ijinigbe.

O ni oun n fẹ ki wọn gbẹsẹle iwa ti ko ba aṣa ilẹ Yoruba mu bii wiwọ aṣọ ti ko bo aya.

Adari Amotekun ọhun ni awọn eeyan wọṣọ ti ko bojumu nitori aye ti n dori kodo, awọn eeyan si ti n gbe ohun ti ko dara latugẹ ju aṣa ilẹ Yoruba lọ.

Shitu sọ pe "awọn ọmọ ti wọn bi laye ijọba awọn Babangida lo n da wa laamu bayii lorilẹ-ede Naijiria."

"Awọn lo n wọ aṣo iwọkuwọ, awọn lo n ṣe Yahoo, awọn naa lo n digunjale."

O ṣalaye pe bi awọn eeyan ṣe n wọ aṣọ laye ode ni jẹ iwa atọhunrinwa, eyii to lodi si aṣa Yoruba.

O ni ohun ti ko dara ni ki baba maa ba ọmọ rẹ lajọpọ, bakan naa ni ko bojumu ki obinrin maa ba obinrin bii tirẹ ṣere ifẹ tabi ki ọkunrin maa ni ibalopọ pẹlu ọkunrin akẹgbẹ rẹ.

Ẹwẹ, nigba to da si ọrọ naa, ajọ to n ri si agbekalẹ ikọ Amotekun, Dawn Commission ti sọ pe, idi ti wọn ṣe gbe ikọ Amotekun kalẹ ni lati pana iwa ọdaran lawujọ, kii ṣẹ lati da si ọrọ miran ti ko jọ mọ iwa ọdaran.

Àwọn ọ̀dọ́ oníwọ̀kuwọ̀ àtàwọn tó ń tàbùkù èdè Yorùbá ti wọ gàù

Amọtẹkun de! Gbogbo ẹyin oniwa ibajẹ nilẹ Yoruba, ẹ bila!

Ẹṣọ alaabo nilẹ Yoruba, Amọtẹkun nipinle Osun ti Kede faye gbọ pe ohun ko ni faye gba aṣọ iwọkuwọ ati titabuku ede Yoruba nipinlẹ naa.

Ọga awọn ẹṣọ Amọtẹkun l'Osun, Amitolu Shittu ló ṣi aṣọ loju eegun ọrọ yii.

Ọgbẹni Shittu ṣalaye pe awọn ọdọ tí aje iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori yoo jẹ iyán wọn niṣu kete ti Amọtẹkun ba gberasọ tan loṣu kẹta ọdun 2021.

Ninu ọrọ rẹ, Ọga ẹṣọ Amọtẹkun sọ pe lootọọ ni iwe ofin ilẹ Naijiria fawọn eeyan lanfaani lati ba ẹgbẹ k'ẹgbẹ to ba wu wọn ṣe, amọ "ko fún àwọn ọdọ lagbara lati maa wọ iwọkuwọ tabi tabuku ede Yoruba.

Ikede ti ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọsun fi sita yii wa ni ibamu pẹlu bi awọn ọlọpaa Shariah, Hisbah lapa Ariwa Naijiria ṣe n ṣiṣẹ.

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu igbesẹ awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ipinlẹ Ọsun lori ayelujara.

Wọn ni ẹṣọ Amọtẹkun ti n ṣe ohun tí ìjọba ko ran wọn.

Ohun ti ẹṣọ Amọtẹkun wa fun mi lati maa ṣe iranwọ fawọn agbofinro lori ati dẹkun iwa ibajẹ lawọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba.

O si tun wà nínú ofin ti wọn fi da Amotekun silẹ pe ẹnikẹni ninu awọn ẹṣọ Amọtẹkun to ba dunkoko mọ araalu yoo foju wina ofin.

Sẹnẹtọ Shehu Sani ninu ọrọ ti ni ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun ba fi iṣẹ eto aabo ilu silẹ bẹrẹ sí ni dọdẹ awọn to n wọ iwọkuwọ kiri, a jẹ wi pe orúkọ wọn ti di "Hisbahtekun" nìyẹn.

Ọpọ eeyan mii naa lo fariga lori ayelujara pe Amọtẹkun ti fẹ maa ṣe ju ara rẹ lọ.