David Oyedepo pe Biodun Fatoyinbo si ìsìn Shiloh, ọmọ Nìíjíríà fárígá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin ọdun kan, awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria tun ti hu ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fikan gbajugbaja pasitọ ijọ COZA, Biodun Fatoyinbo, sita.

Eyi ko ṣẹyin bi iroyin ṣe jade sori ayelujara pe Fatoyinbo yoo ṣe iṣẹ iranṣẹ ninu eto Shiloh to n lọ lọwọ ninu ijọ Living Faith 'Winners Chapel', to jẹ ti Pasitọ David Oyedepo.

Ọdọọdun ni akanṣe isin Shiloh ma n waye ninu ijọ Winners, oriṣiriṣi awọn pasitọ ati akọrin si lo ma n ṣe iṣẹ iranṣẹ nibẹ.

Iroyin sọ pe Pasitọ Oyedepo lo kede lasiko eto isin kan ni Ọjọbọ, pe Biodun Fatoyinbo yoo farahan ninu isin Shiloh, gẹgẹ bi alejo pataki.

Ikede yii si ni ko ba awọn ọmọ Naijiria kan lara mu loju opo Twitter.

Eyi si mu ki wọn o tun bẹrẹ si ni ṣọ ọrọ nipa ẹsun ifipabanilopọ ti ayaworan, to tun jẹ iyawo gbajugbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola, fikan Fatoyinbo.

Ọdun 2019 ni Busola Dakolo jade si gbangba pẹlu ẹsun pe Pasitọ Biodun fi ipa ba oun lopọ ninu ile awọn obi oun nilu Ilorin, ni ọdun diẹ sẹyin.

Ọrọ naa da awuyewuye silẹ. Koda, ọpọ eeyan lo ṣe iwọde lọ si awọn ẹka ile ijọsin COZA nilu Abuja, Eko, ati Port Harcourt.

Wọn n fẹ ki Fatoyinbo fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi Pasitọ Agba ijọ naa.

Ṣugbọn, Fatoyinbo kọ lati ṣe bẹ ẹ.

O sọ pe irọ ni ẹsun ti Busola fi kan oun. Ọrọ naa ṣi wa nile ẹjọ bayii nilu Abuja.

Lọtẹ yii, ohun ti ọpọ eeyan n sọ lori Twitter ni pe Fatoyinbo ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ, ko yẹ ni ẹni to yẹ ki wọn o pe si iru isin bi i Shiloh.

Nibo ni orisun iroyin naa ti wa?

Ẹni to ṣe e ṣe ko pilẹ ọrọ naa lori Twitter, Bowale @Son_of_a_O, sọ pe oun n wo isin Shiloh lori ayelujara ni alẹ Ọjọru.

Ṣugbọn, o ya oun lẹnu nigba ti Pasitọ Oyedepo pe Biodun Fatoyinbo sori pẹpẹ, lati ba ijọ sọrọ.

Igbesẹ yii lo mu ki oun fi opin si wiwo isin naa.

Ẹlomii, @MrLewinOkotie, sọ pe "Biodun Fatoyinbo mura daadaa, to si joko si aaye ti wọn ya sọtọ fun awọn pasitọ ni Shiloh.

Koda, Biṣọọpu Abioye tun kede rẹ gẹgẹ bi ara awọn pasitọ to wa fun isin naa."

O ni ko si ẹṣẹ ti Ọlọrun kii dariji, abi?

@Hermosa_Reinaa ni tiẹ sọ pe bi Fatoyinbo ṣe jẹ alejo pataki ni Shiloh jẹ ara idi ti oun ko ṣe fẹ ẹ ni nkankan ṣe pẹlu ẹsin Kristiẹni ni Naijiria.

Ṣugbọn, eero awọn eeyan kan yatọ.

Fun Ogbe Enhakkore @MyNameIsOgbe, o ni oun mọ pe bi wọn ṣe yẹ Fatoyinbo si, ni shiloh, bi ọpọ eeyan ninu.

O ni amọ, ibinu naa tumọ si pe wọn ko ni oye bi ẹsin Kristiẹni ṣe ri ni.

O lo apejuwe iṣẹlẹ obinrin oni pansaga kan, ti Jesu doola ninu Bibeli, lọwọ awọn to fẹ sọ ọ ni okuta pa.

O ni idariji ẹṣẹ ni koko pataki ẹsin Christiẹni.

"Bi a ṣe n ba Fatoyinbo wi, ẹ jẹ ko a yẹ ara wa naa wo, boya a ko ni ẹṣẹ kankan."