Bishop Oyedepo: Ifedayo Olarinde tó ń jẹ́ Daddy Freeze tọrọ àforíjì pé o sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gbin sí David Oyedepo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oludari ẹgbẹ Free the Sheeple Movement ati Free Nation in Christ, Ifedayo Olarinde, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si DaddyFreeze, sọ pe oun tọrọ aforiji lori ọrọ kan ti oun sọ si oludasilẹ ijọ Living Faith Church (Winner's Chapel), Biṣọpu David Oyedepo.

Freeze sọ ninu fidio kan to fi si ori Instagram rẹ pe aforiji ti oun tọrọ ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe pe akiyesi oun si fidio kan ti oun fi sita ni bi ọdun mẹta sẹyin, lasiko ti oun n sọ ero oun lori awọn iṣẹlẹ kan to waye nigba naa.

O ni "mo n bẹbẹ nitori awọn ọrọ ti mo sọ nigba naa ati fun ọrọ abuku to ta ba Biṣọpu David Oyedepo ninu fidio naa".

"Mi o ni i lero lati ri Biṣọpu naa fin, tabi kan an ni abuku, ti mo si kabamọ itumọ ti awọn kan fi n tumọ fidio naa."

Ninu fidio naa, Freeze sọ pe ọmọ ale ni ẹnikẹni to ba sọ pe Jesu lọwọ nigba aye rẹ. Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ pasitọ to n sọrọ si, o pe ẹni naa ni "apari adiyẹ", to si sọrọ bi ẹni naa ṣe ma n sọrọ.

O ṣalaye pe lasiko yii, ọna ti oun n gba sọrọ lori awọn ilana ati eto ẹsin Kristiẹni ti kuro ni ti atako tabi sisọ ọrọ binu. Ti oun si ti n fi ẹsẹ Bibeli ṣe atilẹyin fun nkan ti oun ba sọ.

O ni ṣugbọn oun gbagbọ pe o yẹ ki awọn Kristiẹni o ma a fi aaye gba awọn ilana tabi akiyesi tuntun to ba n jade ni ibamu pẹlu ẹkọ Bibeli yatọ si eyi to ti wa tẹlẹ ti ko si ẹni to le sọrọ tako o.

Ọjọ ti pẹ ti ẹnu ti ma n kun Freeze nitori awọn ọrọ atako to ma n sọ nipa ẹsin Kristiẹni, paapa nipa idamẹwa ati ọrẹ. Eyi ti kii ba awọn Kristiẹni kan lara mu.

Laipẹ yii si ni Pasitọ kan, Pasitọ Paul Enenche sọrọ lori bi Freeze ṣe sọrs abuku si Oyedepo.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara, Pasitọ Enenche ni ko tọ si Freeze lati ma a sọ iru ọrọ bẹ ẹ, nigba ti oun fun'ra rẹ ko ni igbeyawo to duro, tabi iṣẹ lọwọ. Bakan naa lo pe e ni aja digbolugi.

Tí mo bá kú lónìí, Pásítọ̀ Ibiyeomie ló pa mi - Daddy Freeze kébòòsí

Lẹ́yìn ti orí ayélujara gbóná janjan lọjọ Aje lórí gbómisí-omí-otó láàrin Ifedayo Olarinde tí gbogbo ènìyàn mọ̀ si Daddy Freeze àti Pásítọ̀ Ibiyeomie, Daddy Freeze ti fèsì sí ọ̀rọ̀ pásítọ̀ náà.

Ọ̀pọ̀ tilẹ̀ fẹ́ yọ ẹ̀ṣẹ́ sí ara wọ́n lórí ayelujara lórí bóya, Daddy Freeze lo jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ to kọ si Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo tàbí ọ̀rọ̀ tí Pásítọ̀ Ibiyeomie sọ náà ti pọ̀ju, gẹ́gẹ́ bi ènìyàn Ọlọ́run.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sùgbọ́n ní lọjọ Isẹgun ni Daddy Freeze náà tún fún òjíṣẹ́ Ọlọrun náà ni èsi nípa ìdúkòkò ikú mọ́ni, ti pásítọ̀ náà gbé sórí ayelujára.

Daddy Freeze ni, ìdúkokò ikú mọ́ni jẹ́ ẹṣẹ̀ si ẹ̀tọ́ ìgbé ayé ọmọnikeji, ti òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà si takòó gidigidi.

Ifedayo ni "Jẹ́ ki o wà nínú àkọsílẹ̀ pé tí òhunkóhun bá ṣẹ̀lẹ̀ sí mi lónìí, ẹ ti mọ̀ ẹni ti ó wà nídi rẹ̀.

Ó ti tó wákàtì mẹ́rìnlélógun ti Ibiyeomie ti sọ̀rọ̀ ìdúkokò yìí, àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà kò sì ṣe ǹkankan si"

Ó wa pé àwọn ọmọ Naijiria pe, ṣe bi wọ́n yóò kan ṣe maa wò ọ̀rọ̀ yìí ko lọ bẹ́ẹ̀ rèé, nítorí pé Ibiyeomie jẹ́ èèyàn ńla?"

Ifedayo ni ki olùṣọ́ àguntan náà tọrọ àforijì lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ìròyìn to bẹ̀nu àtẹ́ lù, tó si fí iṣẹ́ wọ́n wọ́lẹ̀ tuurutu.

Eruku ìjà sọ lálá lórí ayelujára láàrin Bíṣọ́ọ́bù méjì àti Daddy Freeze

Saaju ni ati mu iroyin wa fun yin wi pe ija ṣẹlẹ lori ayelujara laarin pasitọ ijọ meji ati Daddy Freeze.

Awọn mẹtẹẹta naa ni Bisọọbu David Oyedepo, ti see alakoso agba fun ijọ Winners pẹlu gbajugbaja onwoye awujọ kan, Ifedayo Olarinde ti ọpọ eeyan mọ si Daddy Freeze.

Ẹni kẹta ni gbajumọ Bisọọbu David Ibiyeomie, to ni ọmọ Oyedepo ni oun ninu isẹ Oluwa.

Igba akọkọ si kọ ree ti aawọ n waye laarin Daddy freeze ati David Oyedepo, paapaa lori ọrọ kawọn ọmọlẹyin Kristi maa san idamẹwa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ohun to fa aawọ ni iwaasu kan ti Oyedepo ju soju opo Twitter rẹ lori ọrọ igbeyawo lo sọ nipa pataki ki aya maa bọwọ fun ọkọ rẹ.

Oyedepo ni ara ojuse iyawo ni ko tẹriba fun ọkọ patapata, gbogbo ohun to ba si dawọle yoo yọri si rere.

O ni obinrin ti ko ba tẹriba fun ọkọ rẹ lodi si ofin Ọlọrun ọba, iru obinrin bẹẹ ko baa jẹ ojisẹ Ọlọrun.

Amọ nigba to n fesi si abẹ ọrọ ti Oyedepo sọ naa, Daddy Freeze ni itẹriba funra ẹni ko gbọdọ mọ lọdọ obinrin nikan, amọ o wa laarin awọn mejeeji.

O ni tọkọtaya ni wọn gbọdọ dijọ tẹriba fun ara wọn, ti ile yoo ba toro.

Amọ ọkunrin kan @jesusemmanuel_ty47, to farahan bii ọmọlẹyin David oyedepo, wa da Daddy Freeze lohun labẹ ọrọ to sọ naa bayii:

"Ẹ wo ọkunrin ti igbeyawo rẹ fori sanpọn to n gba ọkunrin ti igbeyawo rẹ ti le ni ọgbọn ọdun nimọran. Ẹyin ọmọ Naijiria maa n pa eeyan lẹrin sa."

Ọrọ yii lo bọ si apo ibinu Daddy Freeze, to si fesi pada fun ọkunrin naa pe:

"Ẹ wo ẹni to n ja fun Pasitọ rẹ, o yẹ ko mọ pe ki eeyan lo ọgbọn ọdun ninu igbeyawo ko tumọ si pe igbeyawo naa se aseyọri.

Ọpọ igbeyawo awọn asaaju ẹsin kan n fara da igbeyawo wọn ni, wọn ko gbadun rẹ, tori pe mo si kuna lẹẹkan ko tumọ si pe n ko ni saseyọri lasiko yii, inu mi dun lasiko yii ju ti tẹlẹ lọ."

Sugbọn awọn oko ọrọ ti Daddy Freeze fi ransẹ si gbajugbaja ojisẹ Ọlọrun naa lo fa ibinu ojisẹ Ọlọrun miran yọ, eyiun Ibiyeomie.

Ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa ni Ibiyeomie ti faraya, to si n ju oko ọrọ pada si Daddy Freeze pe ko ni ẹtọ lati tabuku Oyedepo, tii se baba oun ninu Oluwa.

N ko le gba ko maa tabuku baba mi Oyedepo, se o ni baba bi? To ba ni baba bi, to ba ni, mu baba rẹ jade.

Irisi rẹ gan jọ tawọn ara Somalia, iwọ to lee to ile rẹ, o ko niyawo ninu ile, o wa n tabuku baba mi, bi gbogbo eeyan ko ba sọrọ, maa sọrọ, maa si fa onitọun ya pẹrẹpẹrẹ."

Fidio naa, ti Ibiyeomie se lori pẹpẹ iwaasu lọjọ Aiku ni ọpọ eeyan n pin kiri lori ayelujara, ti wọn si n sọrọ le lori.

Bi awọn eeyan kan se pọn sẹyin oun ti Daddy Freeze sọ, lawọn miran n ta koo, ti wọn si n gbe sẹyin Oyedepo ati Ibiyeomie.