ECOWAS: Aàrẹ Ghana, Nana Akufo-Addo ti di aàrẹ ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan ilẹ̀ adúláwọ̀ tuntun

Ajọ orilẹ-ede iwọ oorun ilẹ Adulawọ, Economic Community of West Afircan State ti yan Aarẹ ilẹ Ghana, Nana Akufo-Addo lati ma tukọ ajọ ECOWAS bayii.

Wọn yan aarẹ yii nibi ipade to n waye ni Niamey to jẹ olu ilu orilẹ-ede Niger loni ọjọ Aje.

Ipade ẹlẹẹkẹtadinlọgọta iru rẹ lo n lọ lọwọ.

Aarẹ Ghana lo n gba a lọwọ aarẹ Muhammadou Issoufou tó jẹ aarẹ ilẹ Niger.

Awọn ipenija to wa niwaju aarẹ Akufo Addo bayii:

Nipi apero naa ni wọn ti sọrọ nipa ipenija to wa niwaju ajọ yii lasiko yii pe:

  • Owo ti gbogbo orilẹ-ede yii yoo maa na papọ ti yoo jẹ irufẹ kan naa.
  • Iran ajọ ECOWAS di ọdun 2050 to gbọdọ wa si imuṣẹ.
  • Wahala igbesunmọmi to n di baraku ni awọn orilẹ-ede wọnyii
  • Iṣoro eto oṣelu to ṣẹlẹ lorilẹ-ede Mali laipẹ ati bi awọn ologun ṣe da sii ni eyi to fẹ da iṣejọba awa ara wa ru nibẹ.
  • Eto idibo to m bọ lọna ni awọn orilẹ-ede bii Burkina Faso, Cote d'Ivoire, Ghana ati Niger ki gbogbo rẹ lọ ni rọwọ-rọsẹ lai mu ẹmi ara ilu dani.