You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sotitobire: Mọ̀lẹ́bí ọmọ ọdún kan tó pòórá ní ṣọ́ọ̀ṣì figbe ta
Ọjọ́ kẹ́wàá oṣù ìkọ́kànlá ló ṣẹlẹ̀. Iṣẹlẹ aburu ti ko ye ni yii waye ni ilu akure ni ipinlẹ Ondo.
Modupe Kolawole to jẹ iya ọmọkunrin ọdun kan toun funra rẹ din ni ẹni ọgbọn ọdun figbe ta pe ki ijọba gba oun tori ko lẹni kankan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ilé ìwòsàn kan rèé tó ń fi àtùpà gbẹ̀bí aláboyún
- Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún yìí kò tíì lè bọ́ lọ́wọ́ ìséde - Ìjọba àpapọ̀
- Ìrìnà ọkọ̀ akérò àti ọkọ̀ òfurufú bẹ̀rẹ̀ padà jákèjádò Nàìjíríà!
- Òfin ìjọba de ọdún eégún ìlú Ibadan,eégún Olóòlù kò ni kọ́ja agboolé rẹ̀!
- Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?
O ṣalaye pe inu oṣù kẹfa lawọn ṣẹṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sí ìjọ́ tí iṣẹlẹ laabi yii ti waye.
Ninu fọnran aworan yii, iya Gold salaye bi ko ṣe ki n fẹ fi ọmọ rẹ silẹ ati bi awọn ẹṣọ ijọ ṣe ni o yẹ ko maa gbe ọmọ rẹ lọ si yara ti wọn n ko awọn ọmọ wẹwẹ si.
Bakan naa, lo tun sọ nipa bo ṣe pada gbe ọmọ naa lọ si yara awọn ọmọ wẹwẹ ati bo se wa di ohun to n kọ ni lẹnu lati sọ bi ọmọ ọdun kan ti ko tii le rin tabi sọrọ ṣe poora.
Iya Gold jẹ ko ye wa pe, ohun to n kọ oun lominu ni idi to fi jẹ pe ọmọ toun lo di awati, laarin awọn ọmọ to pọ ti wọn fẹrẹ to igba lọwọ awọn olukọ ọmọde ijọ naa.