Murder In Ibarapa: Aborode tó tún jẹ́ olóṣèlú kàgbákò ikú òjijì lọ́nà oko

Agbébọn tún gbẹ̀mí àgbẹ̀ míì lọ́nà oko lágbègbè Ibarapa

Awọn agbebọn ṣekupa oludije fun ile igbimọ aṣojo-ṣofin agba l'Abuja nigba kan ri labẹ asai ẹgbẹ oṣelu Accord, Ọmọwe Fatai Aborode

Ọmọwe Aborode to jẹ oludari ileeṣẹ Kunfayakun Green Treasures Ltd ni a gbọ pe awọn afurasi ti irisi wọn jọ tawọn Fulani darandaran yinbọn pa lẹba oko rẹ, lọna ilu Apodun ni Igangan, ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa.

Ọjọ Ẹti ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 2020 yii ni deedee aago mẹrin irọlẹ ni iroyin sọ pe wọn pa oloṣelu ọhun lori alupupu, lẹyin to kuro ni oko rẹ pẹlu ẹni ti o ba n mojuto oko naa.

Amọ, ẹni ti wọn jọ wa lori alapupu mori bọ lọwọ awọn janduku afẹmiṣofo naa.

Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ naa ṣalaye pe, wọn gbe oloṣelu ọhun digba digba lọ si ile iwosan ṣugbọn ẹlẹmi ti gba a.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, SP Olugbenga Fadeyi ti fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

SP Fadeyi ṣalaye ninu atẹjade to fi sita laarọ ọjọ Abamẹta pe awọn agbebọn lo ṣekupa oloṣelu naa lẹyin ti wọn ja a lole tan.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣe awari awọn ọdaran naa to ti sa lọ.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti awọn agbẹ ṣe ipade tan lori ati wa ojutu si iṣẹlẹ iṣekupani awọn Fulani darandaran niluu Ibadan.