You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Senate Hearing: Iléeṣẹ́ epo rọ̀bì ná ₦14.4m lórí báíró, ₦46m lórí ìwé, ₦56m fún tónà
Ọrọ di agbọdamiẹnu lasiko tawọn ọmọ igbimọ tẹẹkoto lori aṣuwọn owo ilu nile aṣofin agba n gbọ ọrọ lẹnu oluyẹweowo wo agba lorilẹede Naijiria.
Abọ iwadi ti oluyẹ́we owo wo agba gbe wa siwaju igbimọ ile lo sisọ loju rẹ pe miliọnu mẹrindinlọgọfa Naira (₦116m), ni ileeṣẹ to n mojuto epo rọbi na lati fi ra bairo, iwe ati ohun elo itẹwe laarin ọdun kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àádọ́ta Náírà tí báńkì ń yọ nínú owó ìpamọ́ oníbàárà kò tọ̀nà - Iléejọ́
- Agbébọn tún gbẹ̀mí àgbẹ̀ míì lọ́nà oko lágbègbè Ibarapa
- Sanwo-Olu, El-Rufai fara pamọ́ torí COVID-19 lẹ́ẹ̀kejì
- Àwọn agbófinró Nàíjíríà yóò rojọ́ níwájú iléẹjọ́ àgbáyé ICC
- Wo ìgbéyàwó olówó iyebíye tí awakọ̀ Kabúkabú ti jẹ̀bùn ọkọ N3.4m
O yannana rẹ siwaju pe, ninu owo naa, miliọnu mẹrinla abọ naira ni wọn na lori bairo ikọwe nikan, miliọnu mẹrindinlaadọta naira ni wọn fi tẹ iwe alakọle Letterhead ileeṣẹ naa, ti wọn si fi miliọnu mẹrindinlọgọta naira ra awọn ohun elo fun ẹrọ itẹwe (Photocopy) ileeṣẹ naa.
Oluyẹweowo wo agba naa fi kun un pe, nṣe ni wọn wa pin inawo naa si wẹwẹ kaakiri awọn agbaṣẹṣe mẹrin, lati rii pe iṣẹ agbaṣe to kan ọkọọkan wọn ko ju miliọnu marun naira ti ofin fun oludari agba ileeṣẹ ijọba lagbara lati buwọlu lọ.
Bakan naa lo ni ọrọ ri fun inawo lori iwe alakọle ti wọn na miliọnu mẹrindinlaadọta le lori, eyi to ni wọn pin fun ileeṣẹ agbaṣẹṣe mọkanla ti ọkọọkan wọn si gba miliọnu marun naira.
Amọṣa, aṣoju ileeṣẹ epo rọbi ni ijọba apapọ, Godwin Akubo, ni wọn gbe igbesẹ naa jade lati tete mojuto ohun to n jẹ awọn ipin kọọkan to wa labẹ ileeṣẹ naa ni.
O fi kun un pe ilana gbogbo to tọ labẹ ofin ni wọn tẹle.
- Kí ni abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Anthony Joshua fi n wu àwọn ọmọ Naijiria tí gbogbo wọn fẹ́ tan mọ́ ọ?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo kéde òfin konile-o-gbele ní Ode ati Ishinigbo lẹ̀yìn rògbòdìyàn tó wáyé níbẹ̀
- Wọ́n ti rí Ọ̀pá Àṣẹ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun tí àwọn jàndùkú jí gbé nípinlẹ̀ Eko o!
- Wo àwọn tó ti dákú bíi Maina níwájú ìjẹ́jọ́