Nigerian doctor shoots wife: Dr Benjamin Okigbo pa ìyàwó rẹ̀, pokùnso lẹ́yìn tó gbìyànjú láti pa ọmọ

Ileeṣẹ ọlọpaa Sugar Land nilu Texas Amẹrika ti kede ibẹrẹ iwadii ohun to mu ki dokita ọmọ Naijiria Benjamin Okigbo pa ara rẹ ati iyawo rẹ.

Lara ohun ti iwadii naa fi han bayi ni pe dokita yi fun iyawo rẹ lọrun pa ni.

A tun gbọ pe Ben Okigbo gbiyanju lati pa awọn ọmọ rẹ ẹni ọdun mọkanlelogun ṣaaju ki o to pokun so.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa Sugar Land gbe jade, wọn ni awọn ọmọ rẹ mori bọ ti wọn ko si fara pa rara.

''A n tọ pinpin iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi iṣekupani ati igbẹmi ara ẹni'' ni ohun ti awọn ọlọpaa sọ.

Ajọ to n mojuto ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okere ṣapejuwe iku dokita yi ati iyawo rẹ to fi Houston ṣe ibujogbe gẹgẹ bi ''ohun to fọwọ kan ni lẹmi.''

Ninu atẹjade, alaga ajọ yi, sọ pe awọn n ba awọn mọlẹbi kẹdun iku wọn paapa julọ awọn ọmọ wọn.

NIDCOM sọ pe awọn yoo maa fọkan tẹle iwadii ọlọpaa bo ba ṣe n lọ.

Kini ohun taa mọ nipa iku dokita to pa ara rẹ ati iyawo rẹ yi?

Nkan bi ago mẹwa owurọ kọja iṣẹju marun un lawọn eeyan ri oku Dokita Ben ati iyawo rẹ ni adugbo wọn Greatwood Subdivision, Brookstone Lane.

Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria lo jabọ bayi.

"Ọkan ninu awọn ọmọ wọn lo pe ọlọpaa lori ago 911 nigba to fura si pe ija n waye laarin awọn obi rẹ. Nigba tawọn agbofinro yoo fi de wọn ba awọn oku wn ninu ile''.

"O jọ bi iṣekupani ati igbẹmi araẹni ṣugbọn a ko tii ri aridaju'' ni ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa Sugar Land sọ.

Ninu ọrọ kan to wa loju opo Facebook, ile ijọsin Episcopal Church of Epiphany ni Houston sọ pe''Ẹyin ọrẹ wa, ohun to n banin ninujẹ lọdun 2020 ṣebi ẹni pọ si''

"ohun ibanuj lo jẹ lati fi to yin leti pe Ben ati Theresa Okigboku laarọ yi nile wọn to wa ni Sugar Land [Texas].''

O fi kun pe "Iroyin yi bawa lọkan jẹ paapa awa mọlẹbi Epiphany to fi mọ awọn eeyan wa lati Naijiria to ṣe pe Ben ati Theresa lapa ni igbesi aye wọn''

Ileeṣẹ ọlọpaa Sugar Land sọ pe awọn ṣi n ṣe iwadii lori ọrọ naa.