You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìpànìyàn l'Eko: Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ ikú fún ọkùnrin tó pa ìyàwó rẹ̀
Ile ẹjọ giga ti da ẹjọ iku fun ọkunrin kan, Lekan Shonde to lu iyawo rẹ Ronkẹ pa, ni bii ọdun mẹta sẹyin.
Onidajo Agba, Josephine Oyefeso lasiko to n se idajọ naa ni Ọjọ Ẹti sọ wi pe o jẹbi ẹsun ẹyọkan ti ijọba ipinlẹ Eko fi kan an.
Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ni gbogbo ẹri fihan wi pe lootọọ ni Lekan Shonde pa iyawo rẹ Ronke.
Ọdun mẹta sẹyin ni iroyin gbe e wi pe ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaadọta kan ti lu iyawo rẹ pa ni ile wọn ni agbeegbe ẹgbẹda-idinmu ni ipinlẹ Eko.
Wọn ni ọkunrin naa ti ilẹkun mọ oku iyawo rẹ pẹlu awọn ọmọ meji ko to di wi pe ọmọ ọdọ wọn wa lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.