You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Darius Ishaku, olùdíjè PDP wọlé padà sípò gómìnà ní Taraba

    Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu PDP, to tun jẹ gomina ipinlẹ Taraba, Darius Ishaku, ni ajọ eleto idibo ti kede pe o moke ninu ibo gomina ti wn di lọjọ Satide.

    Ishaku lo ni ibo 520,432, to si moke ni ijọba ibilẹ mejila ninu ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ naa.

    Alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu APC, to se ipo keji ninu ibo naa, Alhaji Sani Abubakar Danladi lo ni ibo 362,735, to si rọwọmu nijọba ibilẹ mẹrin pere.

    Nigba to n kede esi ibo naa, ni olu ileesẹ ajọ Inec to wa nilu Jalingo, Ọjọgbọn Shehu Iya ni niwọn igba to j pe gomina Ishaku lo gba iye ibo to pọ julọ, oun lo bori ibo naa.

  2. Èrú ni INEC fẹ́ ṣe ní Kano àti ìpínlẹ̀ márùn ún míì tí ìbò kò ti parí- PDP

    Ẹgbẹ oṣelu alako PDP ti sọ pe, eru ati jibiti ni ajọ eleto idibo INEC fẹ ṣe lẹyin ti ajọ naa kede wi pe, eto idibo gomina nipinlẹ mẹfa kaakiri orilẹede Naijiria ko tii yanju.

    Ajọ INEC kede lọjọ Aje pe idibo gomina ni ipinlẹ Kano, Sokoto, Benue, Bauchi, Adamawa ati Plateau ko tii kẹsẹ jari.

    jọ INEC tiẹ ti kọkọ so eto idibo gomina nipinlẹ Rivers rọ nitori laasigbo to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa.

    Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu PDP fẹsun kan alaga ajọ INEC Ọjọgbọn Mamood Yakubu pe, ohun ti ẹgbẹ APC ni ki o ṣe, gan an lo n ṣe.

  3. INEC kéde Ihedioha gẹ́gẹ́ bíi gómínà ìpínlẹ̀ Imo

    Ajọ eleto idibo INEC ti kede Igbakeji olori Ile Igbimọ Aṣoju-ṣofin nigba kan ri, Emeka Ihedioha to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP gẹ́gẹ́ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo gomina Ipinlẹ Imo.

    Ẹni to se ipo keji ni Uche Nwosu ti ẹgbẹ oṣelu AA, iyẹn àna gomina ipinlẹ naa Rochas Okorocha.

    Ibo naa fa awuyewuye to pọ ti awọn eniyan si bẹnu atẹ lu bi Okorocha ṣe fa àna rẹ kalẹ lati rọpo rẹ.

    Ihedioha ni ibo 273,404 ti Nwosu si ni ibo 190,364.

  4. "Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún"

    Awọn alátìlẹyìn Sanwo-Olu ló wòye bẹ́ẹ̀ lásìkò tí Sanwo-Olu lọ kí Bọla Tinubu nílé rẹ̀.

    Wọ́n tun ni Saraki ati Amosun to fẹ se bi Tinubu ni ipinlẹ Kwara ati Ogun, ni wọn mu ofo.

    Awọn alatilẹyin Sanwo-Olu naa ni, awọn ko ara awọn jọ lati maa se atilẹyin fun gomina tilu sẹsẹ dibo yan naa, niwọn igba ti Oloye Tinubu ti to sẹyin rẹ.

  5. Ọlọ́run fẹ́ ká ní afẹ́fẹ́ rere padà l‘Ọyọ ni Seyi Makinde fi wọlé - Ladọja, Ṣeyi Makinde lọ kí Ladọja lẹ́yìn tó yege ìbò

    Yooba ni taa ba se ni loore, ọpẹ laa du.

    Eyi lo mu ki gomina tilu sẹsẹ dibo yan ni ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde, fi lọ sabẹwo idupẹ si gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Raṣidi Adewọlu Ladọja.

    Nigba to n ki Makinde kaabọ, Ladọja fọwọ idaniloju sọya fawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ pe, idagbasoke yoo ba gbogbo ẹka igbe aye ọmọniyan lasiko ijọba Seyi makinde.

    Ladọja ni origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọyọ ni yoo gboorun isejọba rere Makinde, ti wọn ko si ni maa gan owo le awọn ijọba ibilẹ lọwọ mọ.

  6. Kò sí nkan tí mo fẹ́ ẹ̀ ṣe, Mo bá Abiọdun yọ̀ pé ó borí - Kashamu

    Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Buruji Kashamu, lo sọ ọrọ yii lasiko to ṣe abẹwo sile ẹni to jawe olubori ninu idibo naa, Dapọ Abiọdun ti ẹgbẹ osẹlu APC.

    "O tọ si lati jawe olubori."

    "O ti bori, o ti bori naa."

    To ba jẹ pe lootọ la ni ifẹ ipinlẹ wa, nkan to ku fun awọn to ku ni lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ lati mu ipinlẹ wa goke agba.

    O ṣapejuwe Dapọ gẹgẹ bi ẹni to ni iriri to to lati ṣe gomina ipinlẹ Ogun.

  7. Ajimọbi kí Seyi Makinde kú oríire

    Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiola Ajimọbi ti ki gomina ti ilu sẹsẹ dibo yan, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ku oriire pe o jawe olubori ninu idibo gomina to kọja.

    Ajimọbi tun rọ gomina tilu sẹsẹ dibo yan ọhun lati bẹrẹ si ni gbaradi fun isẹ nla to wa niwaju rẹ, ko si gbagbe gbogbo awọn ohun to sẹlẹ lasiko idibo, bẹẹ lo ni ko rọ awọn alatilẹyin rẹ lati dẹkun sisọ awọn ọrọ to lee tun da wahala silẹ nipinlẹ Ọyọ.

    "Lati ọdun mẹjọ sẹyin, a ri daju pe ofin fẹsẹ mulẹ, ti idagbasoke ati agbega si ba ipinlẹ Ọyọ lati ipasẹ awọn aseyọri to fojuhan, gẹgẹ bawọn mẹkunnu labẹle ati awujọ agbaye ti n sọ."

    "Ni bayii ti mo n ki ọ ku oriire, mo gbadura pe wa se aseye ti alakan n se epo, mo si rọ ọ pe ko gbajumọ awọn eto idagbasoke ti mo ti se ni ẹka ipeese alaafia, eto aabo ẹmi ati dukia ti awọn araalu ti jẹ anfaani rẹ lati ọ̀dun mẹjọ sẹyin."

  8. Tambuwal fẹ́ gbé INEC lọ sílé ẹjọ́ nítorí èsì ìdìbò, Tambuwal ní bí INEC ṣe kéde pé ìbò kò yanjú ní ìpínlẹ̀ Sokoto kò bá òfin mu

    Nitori ikede ti ajọ INEC ṣe pe eto idibo ni ipinlẹ Sokoto ko yanju, gomina ipinlẹ naa, to tun jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo gomina nibẹ, Aminu Tambuwal ti n leri ati gbe ajọ INEC lọ si ile ẹjọ.

    Aminu Tambuwa ṣalaye eleyi lasiko to fi n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Sokoto ni ọjọ aje.

    O ni awawi ti ajọ INEC gbe kalẹ fun kikede pe idibo naa ko yanju ku diẹ kaato nitori ko si agbekalẹ ofin lati fi tii lẹyin.

  9. INEC yóò fún àwọn aṣòfin àpapọ̀ tuntun ní ìwé ẹ̀rí

    Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC yoo fun awọn aṣofin apapọ-Sẹnetọ ati awọn ọmọ aṣoju-aṣofin ti wọn dibo yan ni ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019 ni iwe ẹri wọn ni ọjọbọ.

    Atẹjade kan ti ajọ INEC fi sita loju opo twitter rẹ ṣalaye pe eto naa yoo waye ni gbọngan International Conference Center to wa nilu Abuja.

  10. INEC pàṣẹ kí ọlọ́pàá mú àwọn òṣìṣẹ̀ rẹ̀ méjì ní Imo, Àṣẹ náà wáyé nítorí ìwà aṣemáṣe

    Ere itage to n waye nibi ibudo ikobojọ fun ibo gomina ni ipinlẹ Imo ko tii dawọ duro o.

    Ere itage naa tun ba ibomiran yọ ni ọjọ aje nigba ti ajọ INEC paṣẹ ki awọn agbofinro mu ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ, Kelechi Ezirim to jẹ alamojuto eto idibo fun ijọba ibilẹ Ohaji Egbema ni ipinlẹ Imo.

    Ohun to ṣokunfa aṣẹ yii ni iwa aṣemaṣe to idibo to waye nibẹ.

    Bakan naa ni wọn tun paṣẹ ki awọn agbofinro mu Chris Ogbuadu to to jẹ olori awọn oṣiṣẹ ajọ INEC ni ijọba ibilẹ naa.

  11. Iléèṣẹ́ ológun ní òun kò mọ nípa bí ìdìbò se lọ ní Rivers

    Ileeṣẹ ologun sọ pe irọ ni awọn iroyin kan to n jade pe oun lọwọ si bi nkan ko ṣe rọgbọ ninu eto idibo ipinlẹ Rivers.

  12. "À ń fẹ́ kí ara rọ̀ wá l‘Ogun láyé Dapọ Abiọdun"

    Ọpọ awọn olugbe ipinlẹ Ogun to ba BBC Yoruba sọrọ ni ki Dapọ Abiọdun ti wọn sẹsẹ dibo yan yara ri daju pe ko si jagidijagan nipinlẹ naa.

    Bakan naa ni awọn ọlọkada n fẹ ki adinku ba owo iforukọsilẹ ti wọn n san fun ijọba.

  13. Ijò àti ayọ̀ l'àwọn ọmọ Yorùbá fi gba èsì ìbò gómìnà ní Nasarawa

    Ijó rèé lẹ́sẹ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa ní bí wọ́n ṣe ń ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú Abdullahi Sule ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí Gómìnà nínú ìdìbò.

  14. Pius Adesanmi ní kò bá rọ́pò Wole Soyinka tí kò bá kú - ọmọ Naijiríà

    Gbógbo ọmọ Nàìjíríà nílé àti lẹ̀yìn odi tó jẹ́ ọ̀rẹ́ àti alábaṣiṣẹ́pọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n Pius Adebola Adesanmi tó jẹ́ Ọlọ́run nípe, lásìkò ti bàálù boeing 737 X8 tó ń lọ si Narobi lọ́jọ́ àikú, ọjọ Kẹ́wàá oṣù Kẹ́ta ọdun 2019 já, lẹ̀yìn ìṣẹ́jú mẹ́fà to gbera.

    Gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀jọ̀gbọ́n Adesanmi pẹlu BBC Yoruba sàlàyé pé, oloogbe naa jẹ ẹni ti a n pe ni olùfẹ ọmọ ènìyàn, ẹni to fẹ́ràn ará ìlú ti kìí fi ti ẹya ṣe.

    Ní àgbo àwọn ọmọwe, wọn ni ọjọgban Adesanmi ni wọn woye pé yóò ropò ọjọgbọ́n Wole Soyinka, nígbà ti wọn ba lọ ibi àgbà ń rè.

  15. El-Rufai wọlé gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna fún sáà kejì

    Nasir El-Rufai ti ẹgbẹ oṣelu APC jawe olubori ninu idibo gomina ipinlẹ Kaduna.

    El-Rufai ni akojọpọ ibo 1,045,427, nigba ti oludije Peoples Democratic Party (PDP) ni 814,168.

  16. Àwọn aráàlú fárígá nítorí èsì ìdìbò ní Port Harcourt

    Niṣe ni awọn araalu bọ si aarin igboro lati fi ẹhonu han si bi ajọ INEc ṣe da kika ati kikede esi ibo duro nipinlẹ naa.

    INEC ṣe eyi nitori rogbodiyan to n waye nibẹ.

    Orin ti wọn fi sẹnu ni pe ki ajọ INEC pari idibo k'alaafia le jọba.

  17. Bíi ogun Àgbẹ̀kọ́yà ni ìbò Ọyọ rí, mo dúpẹ́ pé mo borí - Makinde

    Oludije fun ibo gomina nipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, lasiko to n sọ ọrọ akọsọ rẹ fawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, dupẹ pupọ lọwọ wọn fun atilẹyin ti wọn fun oun.

    Makinde ni ibo naa le pupọ bii ogun Agbẹkọya lo ri, amọ oun dupẹ pe Ọlọrun gbe oun jẹri ibo naa.

    Gomina ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Ọyọ naa wa seleri lati mu ki aye dẹrun fawọn olugbe ipinlẹ Ọyọ, pẹlu afikun pe awọn eeyan ti ko dibo fun oun gan yoo ri ere ijọba jẹ.

    Bakan naa lo tun kẹdun pẹlu awọn eeyan to padanu mọlẹbi wọn lasiko eto idibo to kọja, paapa ẹbi Asofin Temitọpẹ Ọlatoye, ti wọn n pe ni Sugar.

    Makinde ni iku gbogbo eeyan ti wọn sọ ẹmi wọn nu lasiko ibo to kọja ko ni ja sasan.

  18. Plateau, Adamawa, Bauchi àti Sokoto yoo ṣe atundi ibo

    Laarin ọjọ mọkanlelogun ni ajọ eleto idibo gbọdọ ṣeto idibo awọn ipinlẹ yii pari.

  19. Kíni ìdí ti àjọ elétò ìdìbò yóò fi sọ pé ìbò ìhà ibikan kò lóju?

    Lówòrs ọjọ́ ajé ni àjọ elétò ìdìbò kéde pé àwọn èsì ìdìbò láwọn ìjọba ìpínlẹ̀ kan kò fẹ́nu gún ibì kan pàtó nítorí náà kò sí èsì ìbò.

    Plateau, Bauchi, Adamawa àti Sokoto ní àwọn ìpínlẹ̀ ti kò fẹnukò.

    Sùgbọ́n kíni àwọn ìdí ti ajọ INEC ṣe le sọ èyí?

    Gẹ́gẹ́ bii òfin ṣe sọ, àjọ INEC lé kéde ìdìbò kò fẹnukò ní ibi ti ìdìbò ti wọn wọgile bá ti pọ̀ ju ìyàtọ̀ ti eni ti ti ìbò rẹ̀ bá pọ́ julọ sí ẹni ti ó ń tẹ̀le lọ.

    Iwe òfin kan náà ló tún sọ pé, ó gbọds pé ọja méje lkyìn ìkéde yìí kí wọn to ṣetò ìdìbò míràn ní ìpínlẹ̀ náà..

    Sùgbọ́n bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ lórilẹ̀ èdè Nàìjíríà ní wàrà ńsesa ni ìdìbò ń lọ níbi ti wọn se ń ṣe àkójọpọ̀ ìbò àkọ́kọ́.

  20. Ijo ati orin ọpẹ lẹnu àwọn ololufẹ Seyi Makinde ni Ibadan

    Kete ti ajọ INEC kede pé Seyi Makinde lo jawe olubori ninu idibo gomina ni Ibadan ni ariwọ ayọ nla ti sọ lọọde oludije PDP naa.