You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kankara Abduction: Ohun ìbànújẹ́ ni bí wọ́n ṣe jí akẹ̀kọ̀ọ́ t'o le ni 300 gbé - Tinubu
Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori akitiyan rẹ lati doola ẹmi awọn akẹkọọ ti awọn agbebọn ji gbe ni Kankara.
Tinubu lo fi ọrọ naa lede ninu atejade kan loju opo Twitter rẹ.
O ni "bi awọn agbebọn ṣe ya bo ile iwe lọsan gangan ti wọn si ji awọn akẹkọọ to le ni ọọdunrun gbe jẹ ohun ibanujẹ ati eyii ti ko yẹ ka fi ọwọ yẹpẹrẹ mu".
- Wo ìdí tí ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣe ti àbúrò rẹ̀ ọmọ ọdun kan àbọ̀ sínú kàǹga
- Ọsẹ́ tí ọkọ̀ aképo tó gbiná lẹ́bàá Otedola Estate l'Eko ṣe rèé
- Òṣèré tíátà Yorùbá yìí la orí mọ́lẹ̀ nígbà tó ń ṣe sinimá lọ́wọ́
- Ọmọ Risikat olójú búlúù méjèéjì jẹ̀bùn oríire àti ìfà ńlá
- Ta ni obìnrin tó fẹ́ bá Dino Melaye ṣe ìgbéyàwó lọ́jọ́ kejì Kérésì?
Tinubu fi kun un pe o jẹ ohun idunu pe wọn tete doola ẹmi awọn ọmọ ile iwe naa lai fi akoko ṣofo.
O ni "igbesẹ naa fi han pe Aarẹ Buhari ni afojusun ati ipinnu lati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ ati lati kapa awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ati janduku to n da Naijiria ru."
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa tun gboriyin fun gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Bello Masari atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun fun ojuṣe wọn lati doola ẹmi awọn akẹkọọ naa.
O fi kun pe akoko ti to fun ijọba Naijiria lati ṣe atunto eto abo rẹ to dẹnu kọlẹ.
Tinubu ni "a ni lati ṣe atunṣẹ si eto abo wa, awọn ọmọ ogun naa si ni lati ni afojusun tuntun lati dabo bo awọn ọmọ ile iwe ati awujọ wa lapapọ."
O pari ọọ rẹ pe ko le si idagbasoke lawujọ ibi ti ibẹrubojo ati abo ti ko peye wa.
Ẹ má bínú pé mo kọ́kọ́ ní akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́wàá péré ni wọn kó nílé ìwé Kankara - Garba Shehu
Agbẹnusọ fun aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria, fun aṣiṣe rẹ lẹyin to kọkọ kede pe awọn akẹkọọ mẹwaa pere ni awọn agbebọn ji gbe ni Kankara.
Nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni awọn janduku agbebọn kan dede ya bo ileewe GSS to wa ni Kankara, ni ipinlẹ Katsina, ti wọn si ji awọn ọmọ naa gbe ki wọn to tu wọn silẹ lọjọbọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ Risikat olójú búlúù méjèéjì jẹ̀bùn oríire àti ìfà ńlá
- Àìmọ̀kan ló mú mi hu ìwà tí mo hù kọjá sẹ́yìn, Jonathan dárí jì mí - Dino Melaye
- Ẹ́ tú èékánná lọ́rùn Sowore, ẹ kò ní ẹ̀rí láti ba ṣẹjọ́ - Ẹgbẹ́ Amòfin Amẹ́ríkà
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- "Buhari, o kò ṣe bẹbẹ kankan láì jẹ́ pé o gba Leah Sharibu náà sílẹ̀"
- Wo àwọn nǹkan to tún nílò NIN fún yàtọ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ síìmù
- Ilé aṣòfin àgbà yọ gómìnà nípò, ẹni tó fi owó ìlú rán ọmọ lọ sí Amẹ́ríkà
- Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin
Ko pe ti iṣẹlẹ naa waye ti Shehu sọ fun ileeṣẹ iroyin BBC pe, awọn akẹkọọ mẹwaa pere ni awọn agbebọn naa ji gbe, bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Katsina ni awọn akẹkọọ to to ojilelọọdunrun ati mẹrin, 344 lo poora.
Ṣugbọn lẹyin ti ijọba doola ẹmi awọn ọmọ ile iwe naa, ti iye awọn akẹkọọ to le ni ọọdunrun si gba idande, ni Shehu ko ọrọ rẹ jẹ pe aṣiṣe ni oun ṣe nipa iye awọn akẹkọọ ti oun fi lede ṣaaju.
Gẹgẹ bo ṣe sọ loju opo Twitter rẹ, o ni "mo tọrọ aforiji pe mo sọ pe awọn ọmọ ile iwe mẹwa pere ni wọn ji gbe ni Kankara, ọrọ ti mo sọ ṣaaju kii ṣe ọna lati fi ẹnu tẹnbẹlu iṣẹlẹ naa."
"Ọrọ ti mo sọ jẹ iroyin to wa ni ikawọ mi ni asiko naa. Ẹ jọwọ ẹ dariji mi lori ọrọ yii, bi a ṣe n wa ọna ki orilẹ-ede wa le ni itẹsiwaju. Ẹ ṣe pupọ."
Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti foju ganni awọn akẹkọọ naa lẹyin ti wọn moribọ ni igbekun awọn to ji wọn gbe.
Ninu ọrọ rẹ si awọn ọmọ ile iwe ọhun, Buhari ni ki wọn mu ẹkọ imọ ẹrọ lọkunkundun nitori ẹni to ba ni imọ ẹrọ ni yoo ni anfaani lati ri iṣẹ lọjọ iwaju.
"Buhari, o kò ṣe bẹbẹ kankan láì jẹ́ pé o gba Leah Sharibu náà sílẹ̀"
Ariwo ààrẹ Buhari ṣe bẹbẹ ni ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń pa láti ọjọ tí ìròyìn ti tàn pé, ìjọba ti rí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Kankara nípìnlẹ̀ Katsina gbà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Sùgbọ́n, wọ́n ni ó kù, ó kù ni ìbọ́n ń ró lọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ ló ti gba ojú òpó twitter kan báyìí pé, àwọn ọmọbìnrin Chibok tó kù ńkọ́?
Wọn n beere pe níbo ní Leah Sharibu, ti wọ́n jígbé lásìkò ti àwọn ọmọ Dapchi ti wọ́n sì kọ̀ láti tu sílẹ̀ nítorí, ó kọ̀ láti ju ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀sìn krìstẹ́nì nù.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- Wo àwọn nǹkan to tún nílò NIN fún yàtọ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ síìmù
- Ilé aṣòfin àgbà yọ gómìnà nípò, ẹni tó fi owó ìlú rán ọmọ lọ sí Amẹ́ríkà
- Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin
- Ẹ̀ẹ̀kan láàrin ọjọ́ méjì là ń jẹun ní ìgbèkùn, ìyà jẹ wá - Akẹ́kọ̀ọ́ Kankara ṣàlàyé
- Sé Boko Haram ń pẹ̀ka kiri Nàíjíríà ní ìjínigbé ṣe burú báyìí?
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Ẹ̀sìn kò fàjà! Obìnrin Mùsùlùmí ṣe ilé àlúfà ní ọ̀ṣọ́ fún Kérésìmesì
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
Orúkọ Leah Sharibu ló ń léwajú lójú òpó twitter, tí olókúlùkù sì ń gbà ìjọba nimọ̀ràn láti lo àwọn Miyetti Allah ti wọ́n lò láti bá agbegbọn sọ̀rọ̀ fún ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ Kankara náà ni kó yanjú ti Leah Sharibu.
Àwọn míràn tilẹ̀ sọ pé, ijọba lo ọ̀rọ̀ àwọn ọdọ́mọkurìn Kankara láti gbayì kúnra wọn ní, nítori tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé ti wọ́n ko ti gba àwọn ọmọ Chibok àti Dapchi tókù wálé.
Wọ́n ni àfi ti Leah Sharibu ba dari wálé ni ìjọba tó ṣe ǹkan tó tọ́.
@Dami nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìjọba tó lọ dóòlà àwọn ọmọ tó le ni ọ̀ọ̀dúnrun, kò gba Leah silẹ.
O wa n beere pe kí ni ìdí ti wọ́n kò fi ti gba Leah Sharibu kalẹ̀ títí di àsìkò yìí?
Ẹ̀ẹ̀kan láàrin ọjọ́ méjì là ń jẹun ní ìgbèkùn, ìyà jẹ wá - Akẹ́kọ̀ọ́ Kankara ṣàlàyé
Ọkan lara awọn akẹkọọ ti wn sẹsẹ tu silẹ ti salaye fawọn akọroyin pe "ẹẹkan laarin ọjọ meji ni awọn n jẹun ni igbekun ajinigbe".
O sọ ọrọ yii lasiko ti gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari tẹwọgba wọn lẹyin ti wọn gba ominira.
Ọmọkunrin naa fi kun ọrọ rẹ pe, ara oun ko ya, nitori pe awọn jẹ iya pupọ ninu igbo ti wọn ko wọn si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Ẹ̀sìn kò fàjà! Obìnrin Mùsùlùmí ṣe ilé àlúfà ní ọ̀ṣọ́ fún Kérésìmesì
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
- Ọ̀fẹ́ ló bá dé, Boko Haram kọ́ ló jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé, a kò san kọ́bọ̀ fún ìdáǹdè wọn - Masari
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Oladimeji?
- Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo
- Ìtura ìgbà díẹ̀ ni bọ́dà tí ìjọba ṣí padà, kò lóòre nínú - Onímọ̀ ọrọ̀ ajé
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
Ọkan lara wọn tun ṣalaye pe ibi ti awọn n sun si, naa ni wọn ti n ṣe igbọnsẹ.
Owurọ ọjọ Ẹti ni awọn akẹkọọ ile ẹkọ GSSS, Kankara, nipinlẹ Katsina, to le ni ọọdunrun ọhun gunlẹ si ilu Katsina.
Ipinlẹ Zamfara ni wọn sun ni alẹ Ọjọbọ lẹyin ti wọn gba idande lọwọ awọn ajinigbe naa, lẹyin ọjọ mẹfa ni akata wọn.
Awọn alaṣẹ sọ pe inu igbo nla kan ni ipinlẹ Zamfara ni wọn ti gba ominira, awọn oṣiṣẹ eleto aabo lo ko wọn pada si Katsina lowurọ ọjọ Ẹti.
Akọroyin BBC to wa ni ile ijọba ipinlẹ Katsina lọwọlọwọ, Khalifa Shehu Dokaji, sọ pe, ọpọlọpọ ọkọ bọọsi ni wọn fi ko awọn ọmọ naa pada.
O ṣalaye pe ile itura ni awọn ọmọ naa yoo kọkọ duro si, nibi ti wọn o ti wẹ, jẹun, sinmi, ki dokita to ṣe ayẹwo ara wọn.
Gomina ipinlẹ Katsina to tẹwọgba awọn ọmọ naa, Aminu Bello Masari, ki awọn ọmọ naa ku ajabọ, to si ṣapejuwe nkan to ṣẹlẹ si wọn gẹgẹ bi sababi.
Bakan naa ni amugbalẹgbẹ fun gomina, Muhammad Funtua sọ fun BBC pe eto ti wa nilẹ pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo yọju si awọn ọmọ naa lọjọ Ẹti.