Katsina: Ó di ìgbàkẹ́tà l'óṣù kan tí àṣírí ilé ìmúni nígbèkùn yóò tú síta ní àríwá Nàìjíríà

Pa lẹẹkini,pa lẹẹkeji, o ti di igba ẹlẹkẹta laarin oṣu kan bayi ti awọn ọlọpaa Naijiria tu awọn ti wọn de ni igbekun silẹ lariwa Naijiria.

Nilu Katsina ni itusilẹ to ṣẹṣẹ waye yi ti ṣẹlẹ.

Awọn meji ti asiri wọn tu sita tẹlẹ waye ni Kaduna ati ilu Daura to jẹ ilu aarẹ Muhammadu Buhari.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Katsina,Gambo Isa, fidi ọrọ itusilẹ ẹlẹẹkẹta yi mulẹ ṣugbọn o k lati s iye eeyan ti wọn doola nibẹ.

Amọ ṣa awọn akọroyin ni o ṣeeṣe ki wọn to ọkunrin ẹẹdẹgbẹta ti wọn tu silẹ nibẹ.

Awọn ile kewu ati ile ọmọ alaigbọran pọ nilẹ ariwa ti wọn si jẹ ipenija latari bi ko ti ṣe si ofin to n dari wọn.

Ọrọ yi mu ki awọn eeyan ke si ijọ́ba lati wa wọrọkọ fi ṣada lori awọn to n dari ile imuni nigbekun wn yi.

Aarẹ Buhari ti paṣẹ ki awọn agbofinro gbe igbesẹ to y lori awn aaye imuni nigbekun wọn yi nibi ti a gbọ pe wọn ba awọn eeyan laṣepọ ni tipa.

Ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju re e

Awọn Ọlọpa ilẹ Nigeria ti ṣalaye pe, ko din ni ọọdunrun eniyan ti wọn de ni igbekun ni ojuko ibi igbekun miiran ni ajọ naa ti tu silẹ bayii.

Ojuko ibi igbekun yii ni wọn ri ni Ilu Daura, ti o jẹ ilu olori orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti wọn pe ni ile iwe ṣugbọn ti ko ri bẹẹ.

Alukoro ajọ Ọlọpaa ni Ipinlẹ naa, Gambo Isa ṣalaye pe ọpọ awọn ti wọn ri yii ni ọmọde ti wọn fi okun de ọwọ ati ẹsẹ wọn, ti wọn si n ba wọn ni aṣepọ.

Lara awọn ti wọn de ni igbekun yii ṣalaye itu ti wọn fi wọn pa ti o ti mu ọpọ sa kuro ti o si ṣokunfa riri ti awọn eniyan fi ṣakiyesi wọn.

Awọn Ọlọpaa ṣalaye pe pupọ ninu awọn wọnyii lo jẹ ọmọ kekere bii ọdun meje, pelu pe ni Ilu Kaduna, iru eyi naa ṣẹlẹ ni oṣu kẹsan ti wọn tu ọpọ silẹ.

Wọn ni ile iwe ikẹkọ kehu ni wọn maa n pe ṣugbọn ti o jẹ pe irọ funfun balau ni.

Ọlọpaa fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn akọọlẹ ile iwe naa fihan pe, o le ni Ọọdunrun akẹkọọ to wa ni ile iwe naa ti wọn ko ju ọmọ ọdun meje lọ.

Latari ifiya jẹni yii lo mu ki awọn akẹkọọ ile iwe naa fi ẹhonu han ti ọpọ si fẹsẹ fẹ.

Ọpọ ni egbo oju ibi ti wọn ti fi ṣeeni de lẹsẹ wa ni bẹ ṣugbọn ti Ẹẹtadinlaadọrin eniyan ṣi wa ninu igbekun nigba ti Ọlọpaa de ile iwe naa.

Bayii awọn eniyan naa ti n gba iwosan ni ile iwosan Ijọba ti wọn si ti mu wọn mọ awọn ebi wọn

O ti di eemeji ti iru eyi n ṣẹlẹ laarin Oṣu kan ni Orilẹ ede Naijiria.