Yoruba Film: Ṣe odìwọ̀n ẹ̀fẹ̀ Mr Latin pẹ̀lú àwọn apanilẹ́rìín mìí

Gbogbo ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ni ayẹyẹ ọjọ ibi molumọọka apanilẹrin oṣere, Bolaji Amusan.

Ẹ o le wa a ti, bi wọn ba pe gbogbo awọn apanilẹrin jankan jankan laarin awọn oṣere Yoruba. Bolaju Amusan ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin gbajugbaja.

Gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere yoruba ni Naijiria, TAMPAN, kii ṣe ana ni Bolaji Amusan goke agba ninu ere Yoruba.

Ẹ lee maa mọ awọn nkan melo wọnyii nipa oṣere Mr Latin.

  • Ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 1966 ni wọn bi Bolaji Amusan ni ilu Gbọngan.
  • Ọdun 1988 lo bẹrẹ si ni fara han ninu ere Yoruba.
  • Ilu Abeokuta lo tẹdo si lorilẹede Naijiria ati ilu Durban nibi ti iyawo atawọn ọmọ rẹ n gbe.
  • Fiimu tirẹ to kọkọ gbe jade ni "Ẹbun Igbeyawo" lọdun 1996 o si ti gbe ọpọlọpọ ere mii sita bii:

50-50 (1992)

Ebun Igbeyawo (1996)

Faworaja (1999)

Nnkan Olomoba (2000)

Talo n gbemu (2001)

Eegun Mogaji

Obajobalo

Mr President

Òfin mósè (2006)

Ile Itura (2007)

Baba Insurance (2009)

Ise onise (2009)

Baba Gomina

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun 2018 ni ẹgbẹ TAMPAN ṣe eto idibo lati yan awọn oloye ẹgbẹ tuntun ninu eyi ti Mr Latin ti jawe olubori gẹgẹ bii aarẹ.

Ọkan pataki lara awn to maa n fi ọgbọn ori ṣe ẹfẹ wọn ni Mr Latin jẹ lara awọn oṣere Yoruba oun naa si ni ajọ tirẹ Mr Latin TV ati Mr Latin Foundation.