You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yollywood: Àwọn èèyàn fèsì pé Kemi ń díbọ́n ni, tórí ọ̀rọ̀ ọkùnrin ni
Gbajugbaja oṣere fiimu yoruba, Kemi Afolabi ti ke gbajare pe arabinrin kan n lepa ẹmi oun lati pa.
Ọrọ naa di fa ki n fa a laarin Kemi ati ẹni kan to pe orukọ rẹ ni Gloria Johson tori pe Kemi ni o fi nọmba kan dẹru ba oun.
O sọ ninu fidio to fi soju opo instagram pe "orukọ rẹ ni Gloria Johnson o n dẹru ba mi lọpọlọpọ igba".
Kemi Afolabi tete fi ẹsun kan Gloria loju opo instagram rẹ pẹlu fidio Gloria to fi sita ati nọmba to ni o fi n pe oun.
Ẹwẹ, lara awọn idahun ti Kemi gba lori ọrọ to fi sita ni ti obinrin kan to ṣalaye pe Kemi kan n dibọn bii pe ọwọ rẹ mọ ni.
O ni gbogbo lalakunfẹfẹ ariwo Kemi Afolabi yii ko ṣẹyin ija to ṣẹlẹ laarin Kemi ati ọrẹbinrin oun, Gloria lori ọrọ oṣerekunrin, Gida.
Amarachi to ta ko Kemi sọ fun pe odidi iyawo ile ni to tun wa n fi ọrọ sita pẹlu ẹni to dagba ju lọ.
O ni o tun wa n fẹ ẹ loju lori ẹrọ ayelujara bẹẹ si ni awọn eeyan ko mọ pe tori Gida lo ṣe n ṣe eyi.
Gloria pe ọrẹ rẹ , Gida lori foonu, afi to di pe Kemi lo gbe foonu to si bẹrẹ si ni s fun Gloria pe ko fi ọkunrin rẹ lọrun silẹ to si fesi pe ki o dẹkun gbogbo radarada yẹn ki o ye ṣe bi ọmọde.
Amarachi ni alainitiju ni Kemi Afolabi o ni oun kaanu ẹni to ṣe e ni abiyamọ.