You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mamman Daura: Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ìbátàn Buhari tó ń bá a gbé l'Abuja
Iwadii ti ile iṣẹ iroyin BBC ṣe fihan pe Mamman Daura ko ni ipo oṣelu kankan to di mu lorilẹede Naijiria bo tilẹ jẹ pe ibatan rẹ ni.
Iwadii naa jẹ ko di mimọ pe ọmọ ẹgbọn Buhari ni Daura jẹ ti Buhari si ta a lọrẹ ile ti wọn n pe ni Glass House ninu Aso Rock l'Abuja.
Fidio kan to fihan bi iyawo aarẹ, Aisha Buhari ṣe n fariga pe wọ́n tilẹkun mọ oun ninu ile ijọba to wa l'Abuja pẹlu bi awọn aṣọna si ṣe wa ninu ile ṣi n tu ọrọ sita kaakiri itakun ayelujara.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Hausa, iyaafin Buhari ni lootọ oun lo wa ninu fidio naa toun n fi ibinu sọrọ.
Ninu fidio ọhun, Aisha Buhari n pariwo pe ki ẹbi Daura ko kuro ni ile ti wọn fun wọn gbe ninu Aso Rock.
Ṣugbọn o ni fọnran naa kii ṣe ti ọdun yii rara ninu eyi to ti n fesi si awọn ẹbi Daura pe wọn ko jẹ ki oun wọ inu 'ile onidigi' (Glass house villa), Fatima si lo ya fidio naa.
- Ìgbà Marún-un ti Aisha Buhari ti tako ìjọba Buhari
- Aisha Buhari ké gbàjare pé ètò ìjọba Buhari kò ṣànfàní f'óbìrin
- Èmi kò sí nílé, ọkọ́ mi ló leè sọ bóyá lóòtọ́ọ́ ló fẹ́ gbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha fèsì
- Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára
- Daura kò tan mọ́ Buhari àmọ́ òun àti ọmọ rẹ̀ ti fẹ́ ba ẹbí mi jẹ́ - Aisha figbe ta
"O ya fidio ọhun niwaju awọn ẹṣọ mi ati gbogbo awọn to wa nibẹ to si n fi mi rẹrin", ohun ti Aisha sọ fun BBC ree.
Ọmọ Mamman Daura ni Fatima Daura to jẹ ọmọ ẹgbọn aarẹ Buhari. Oun naa ba BBC sọrọ pe oun loun ya fidio naa lọdun 2017.
Nigba ti wọn bi i pe ki lo de ti wọn o jẹ ki Aisha wọ inu ile, o fesi o ni nigba ti aarẹ Buhari wọle ibo to de Aso Rock lo fun baba oun Mamman Buhari ni ile ti wọn n pe ni Glass House idi si niyii ti awọn ko fi jẹ ki Aisha wọle.
Ta gan ni Mamman Daura?
Mamman Daura ko kan ki n ṣe korikosun aarẹ Naijiria, ọmọ ẹgbọn Muhammadu Buhari lo jẹ bi o tilẹ jẹ pe o gba ọdun mẹta lọwọ aarẹ tori ọmọ ẹgbọn rẹ ọkunrin ni.
Ninu iwe kan 'Muhammadu Buhari: The Challengesof Leadership in nigeria.' Ọjọgbn ilẹ Amẹrika John Paden tẹnu bọ ibaṣepọ to wa laarin Buhari ati Daura o si ni o ti pẹ ti wọn ti jọ n ṣe nkan papọ.
Ninu ọrọ lo ti gba aarẹ Buhari niyanju lati mu ẹkọ rẹ lọkunkundun.
Mamman Daura ka ile iwe girama ni Okene Provincial School pari lọdun 1956.
Ọkan lara awọn agba oniṣẹ iroyin ni Daura to di alabojuto iwe iroyin 'New Nigeria' lẹyin oṣu diẹ to pari ikẹkọọgboye rẹ ni Trinity College, Dublin. Bakan naa o siṣẹ gẹgẹ oludari agba ile iṣẹ naa.
Ọpọlpọ iroyin lo jade pe ẹsẹ rẹ rinlẹ gan ni nigba akọkọ ti Buhari jẹ adari orilede Naijiria labẹ ijọba ologun lọdun 1983.
Bakan naa o tun ti ṣiṣẹ ni Banki apapọ ilẹ Afirika o si tun ṣi ile iṣ kan ti wọn ti n ṣe oriṣiriṣi iṣẹ Pako ni ilu Kaduna. O tun ti jẹ alaga Bank of Commerce and Industry eyi ti ko ṣiṣẹ mọ bayii.
O ṣiṣẹ pẹlu ile iṣẹ Daura Native Authority ko to dara pọ mọ ile iṣẹ to n ri si eto igbohunsafẹfẹ Naijiria (NBC) gẹgẹ bi igbakeji alamojuto eto.
Gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ oniroyin, afojusun rẹ nigba naa ni lati maa ṣe awọn iroyin to kan iha ariwa ati lati daabo bo ifẹ wọn.