Aso Villa: Wàhàlà kankan kò rúgbó nílé Ààrẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iroyin ti jade pe aarẹ orilẹede Naijiria Muhammadu Buhari ko ni arun ko si rin ni igberi ewu kankan to ni ṣe pẹlu ajakalẹ arun tabi iroyin to n tan kalẹ nipa iṣẹlẹ to waye laarin awọn ẹṣọ ile aarẹ eyi ti wọn n ṣewadii rẹ lọwọlọwọ.

Ileeṣẹ aarẹ sọ pe awọn ni imọlara ọpọ ohun tawọn araalu n sọ lori iṣẹlẹ to waye laipẹ yii laarin awọn olugbe ile aarẹ l'Abuja.

Agbẹnusọ fun aarẹ, Garba Shehu salaye loju opo Twitter rẹ pe ita ẹnu ibode ile aarẹ gan ni ọrọ yii ti ṣẹlẹ.

"Awọn ẹṣọ aarẹ atawọn ti ẹnu ibode gba ẹkọ to yẹ nipa amulo ohun elo ijagun ati bi wọn ṣe n lo o bi wọn ba si ṣe aṣiṣe, awọn adari wọn mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe.

Ọgbẹni Garba ni niwọn igba ti wọn ti paṣẹ ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ to iyalẹnu ti awọn ọlọpaa yii, aarẹ Buhari ti ṣe ni ibamu pẹlu ofin.

Agbẹnusọ aarẹ ni iṣẹlẹ kekere yii lawọn eeyan wa rari mọ ti wọn sọ di babara ti wọn si n sọrọ si ijọba ati aarẹ Buhari.

Fun idi eyi, aarẹ Buhari ti ni ki wọn jẹ ki ofin ṣe iṣẹ rẹ lẹkunrẹrẹ.

Aisha Buhari vs Police : Ọgá Ọlọ́pàá kọ̀ láti tú àwọn ẹ̀ṣọ́ ìyàwó Ààrẹ sílẹ̀

Ọga agba awọn ọlọpaa Naijiria ti kọ lati da iyawo aarẹ Naijiria, Aisha Buhari lohun lati igba to ti fun pe si i lọjọ ẹti pe ko tu awọn ẹṣọ rẹ silẹ lahamọ ọlọpaa.

Eyi n ṣẹlẹ latari bi iroyin ṣe ni iyawo ati awọn ọmọ aarẹ ṣe gbogun ti akọwe pataki si aarẹ Yusuf Sabiu ọmọ ẹgbọn aarẹ ti wọn fun ni alajẹ Tunde.

Awọn iwe iroyin kan jabọ pe titi di ago mẹrin irọlẹ ọjọ abamẹta, wọn ṣi wa lahamọ ọlọpaa.

Wọn ni ara ile aarẹ kan lo ta awọn lolobo pe Tunde ṣẹṣẹ de lati ipinlẹ mii ni, o ṣabẹwo si oludari ileeṣẹ ipọnpọ NNPC, Maikanti Baru to ṣẹṣẹ ku nipasẹ COVID-19. Wọn ni o tun ṣabẹwo sawọn ibomii.

Dipo ko lọ ya ara rẹ sọtọ gẹgẹ bi ofin, wọn ṣe lo pinnu lati dari si Aso Rock to si mọ pe oun jẹ ọkan lara awọn to maa n sunmọ aarẹ.

Ọrọ yii lo da bii pe o fa sababi ọrọ gan ti iyawo aarẹ fi soju opo Twitter rẹ pe o yẹ ki ọwọ ofin tẹ ẹni to ba rufin ma rin lasiko isede yii.

"Aarẹ Buhari ti sunmọ ọgọrin ọdun o si le wa ni bebe aisan to ba n ran.

A ni ki Tunde ma wọle afigba to fipa wọle to tun fi ọlọpa mu awọn ẹṣọ Aisha ti ko fẹ ko wọle". Awọn kan ni o ti fẹ maa ni iru ibaṣepọ to wa larin aarẹ ati olori awọn oṣiṣẹ aarẹ tẹlẹ, Abba Kyari.

Ẹwẹ, Aisha ni ki wọn tu awọn ẹṣọ oun silẹ ki wọn ma ṣi wọn silẹ si arun Coronavirus.

Ìgbà Marún-un ti Aisha Buhari ti tako ìjọba Buhari

Aisha vs Garba Sheu: Igba Marún-un ti Aisha Buhari ti tako ìjọba Buhari

Nidile mọlẹbi akọkọ orileede Naijiria,nkan ko fẹ ṣẹnu ree.

Bi eeyan ba ti n fi ọkan tẹle iṣẹlẹ agbo oṣelu yoo ti ṣe akiyesi pe iyawo aarẹ Naijiria Aisha Buhari ko fi tinufẹdọ dunnu si awọn to n ṣe ijọba pẹlu ọkọ rẹ.

Bi ko ba ma tako ọkọ rẹ to jẹ aarẹ yoo ma bẹnu atẹ lu awọn amugbalegbe kan to ni wọn ko jẹ ki aarẹ Buhari ṣe ijọba rẹ bo ti ṣe yẹ.

Pẹlu bi ohun ati Garba Sheu ṣe tun tahun sirawọn yi, a ni ki a se akojọpọ iye igba ti Aisha Buhari ti tako ijọba ọkọ rẹ.

Ni meni meji,awọn ti a le ranti ni wọn yi:

"Ìgbìmọ ẹlẹ́ni méji ló ń dari ọkọ mi"

Ní ibi ìpàdé àpérò kan nilu Abuja ní Aisha ti pe awọn ọmọ Naijíríà nija láti kọju ìjà si àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méji si mẹ́ta tó n dari ìjọba Muhammadu Buhari ni lòdì si àwọn ènìyàn Nàìjíríà.

Aisha ni kò dara to pe kí ènìyàn tó le ni mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dogún dibo yan ọkọ òun wọle ki àwọn ènìyàn meji dondo si gba ìjọba láti keyin awọn naa si ààrẹ.

O pe àwọn okunrin Nàìjíríà nija láti dide ki wọ́n ba wọn ja.

Sááju àsìkò yìí ni Aisha Buhari ti ba BBC Hausa sọ̀rọ̀ lọdun 2016 pe àwọn kan lo ń dari ọkọ òun nilé ìjọba.

"Bí ẹgbẹ́ òsèlú APC ṣe ń seto ìdìbò Abẹ́lé kò tó rárá"

Lárá ǹkan ti o tún dá awuyewuye sílẹ̀ ní bi aya ààrẹ ṣe kọlu alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole.

Aisha ni ìwà àìtọ ló n hù nínú ẹgbẹ́ pàápàá julọ lóri ètò ẹgbẹ́.

O ni alága ẹgbẹ́ ń farun iwaju pọ̀ mọ ti ìpàkọ́ fún gbogbo àwọn ọmọ égbẹ́, èyí sì ló ń dá yánpón-yanrin silẹ̀ ninu ẹgbẹ́ APC.

Ọ̀rọ̀ yìí jẹyọ nígbà ti àbúrò aya ààrẹ gbégbà ìbò ìdìbò abẹ́lé fún ìpò Gomina ni ìpínlẹ̀ Adamawa sùgbọ́n ti kò wọle.

"Ó ṣeéṣe ki n ma ti ọkọ mi lẹ́yìn nínú ìdìbò tó n bọ"

Ṣáájú ìdìbò ọdun 2019 ní aya ààrẹ orilẹ̀-èdè Naijíríà sọ pé ó ṣeese láti má fọ̀wọ̀sowọpọ lóri ìdìbò 2019.

Aisha Buhari sọ èyí di mímọ̀ lásiko tó ń ba BBC sọ̀rọ̀, ó ni ọ̀pọ̀ àwọn mínísítà tó n ba ọ̀kọ òun ṣiṣẹ́ ni kò damọ.

Ó fi kùn un pé onírúuru awuyewuye ni òun ti n gbọ ti eti òun sì ti kún lóri ọ̀rọ náà.

Ọ̀rọ̀ yìí dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ aríyanjiyan sílẹ̀ lórí ẹ̀rọ twitter

"Àwọn obinrin Kano kò jànfàní owó amúlúdùn fún àwọn toosi jùlọ"

Láìpẹ yìí ni ìyàwó ààrẹ tún bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lú èto ìjọba Muhammadu Buhari lóri pínpín owó ẹdẹ́gbẹ̀ta bílíọ̀nú náírà tó wà fún àwọn tó tòsì jùlọ pàápàá jùlọ ni ìhà Arewa.

Èyí jẹ alébu sí ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari ti ọ̀pọ̀ àwọ̀n eníyan bẹ̀rẹ̀ si ni gbàá bí ẹni gab igba oti.

"Miò faramọ́ ìyànsípò Festus Adedayo"

Lánàá òde yìí ni Aisha tún fi ohun rẹ̀ síta lóri ìyànsípò agbẹ́nusọ fún ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin agbà Ahmed Lawan tó fẹ yan Festus Adedayo sípò.

Gẹ́gẹ́ bi ìṣe rẹ̀ aya ààrẹ gbá ojú òpó twitter rẹ̀ lọ láti pa òhun pọ pẹ̀lú àwan ọmọ égbẹ òṣèlú APC tó kù láti tako Festus Adedayo pé kò ṣesṣe ki ènìyàn maa tèlé ìjọba ti kò ni ìgbàgbọ ninu rẹ̀.

Eyi lo ti bi eso ti aarẹ ile igbimọ aṣofin ti fi yọ Festus Adedayọ nipoKò dùn mí pé mo sọ̀rọ̀ tako Buhari -Adedayo Festus