NNPC: Buhari yan Kyari ní olùdarí tuntun fún àjọ NNPC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ile iṣẹ to n risi ọrọ epo rọbi ni Naijiria, NNPC ti gba adari tuntun.

Mele Kolo Kyari ni aarẹ Buhari yan lati rọpo Maikanti Baru to ti n dari ajọ naa tẹlẹ.

Ajọ elepo rọbi Naijiria ti fidi ọrọ naa mulẹ nigba ti wọn gbee si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn.

Ajọ NNPC ni aṣoju ẹka miran meje ni aarẹ Buhari tun yan sipo yatọ si Kyari.

Ati pe ọjọ keje, oṣu keje ni awọn alakoso tuntun wọnyii a bẹrẹ iṣẹ.

Ọpọ lo n foju sọna lori ohun to maa yatọ lori ọrọ epo rọbi ni Naijiria lẹyin ti wọn ba gba iṣẹ tan.