You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kílódé tí ìjọba Nàíjíríà kò fòpin sí lílo ike rọ́bà lẹ́ẹ̀kan?
Ajọ to n risi ọrọ oju ọjọ ti ni ọpọlọpọ ipenija lo wa ninu ki orilẹ-ede kọ lati maa lo ike nigba gbogbo lati daabo bo ayika.
Atâyi Babs to jẹ adari Ajọ 'Climate and Sustainable Development Network' ti ni ida aadọrun eniyan lo n lo ike rọba lai si pe wọn maa tun un lo nigba miran lati dawọ ẹkun omi duro lagbaye.
Ninu ọrọ rẹ, Babs ni iwadii lati Ajọ Ocean Conservancy f han pe ike rọba yoo pọ ju ẹja lọ ninu okun ni ọdun 2050.
O ni awọn n ra ike rọba miliọnu kan lagbaye ni isẹju aaya kan, ti awọn si n lo to triliọnu marun un ike rọba lọdọọdun.
Atâyi Babs fi kun un wi pe ijọba apapọ Naijiria ni isẹ pupọ lati se, lati ri i wi pe opin de ba lilo ike rọba ni awọn igberiko, ẹsẹ kuku ati awọn ilu nla nla.
Adari Ajọ 'Climate and Sustainable Development Network' ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ni ilẹ Afirika bii Côte d'Ivoire, Cameroon, Mauritania, Tunisia, Kenya, Uganda, Rwanda, Tanzania, Morocco ati South Africa lo ti gba lati f'opin si lilo ike rọba ati ipenija rẹ.