Ghana Floods: Èèyàn méje pàdánú ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ẹ̀kún omi

Ojo arọọrọda ti gbẹmi eeyan meje niluu Accra tii ṣe olu ilu orilẹ-ede Ghana.

Lalẹ ọjọ Aiku lojo ọhun bẹrẹ ti o si rọ fun wakati mẹta gbako.

Nibi ti ajọ to n ri si ọrọ pajawiri lorilẹ-ede Ghana (NADMDO) ti n doola ẹmi awọn eeyan ni wọn ti ri oku eeyan mẹrin lagbegbe Ashaiman, bẹẹ ni wọn tun ri omiran lagbegbe Odorna.

Igbakeji adari ajọ to n ri si ọrọ iṣẹlẹ pajawiri, Seji Saji to ba BBC sọrọ, fidi rẹ mulẹ pe awọn ri oku eeyan mẹrin to ku ninu ọkọ awọn ologun lagbegbe Adjei-Kojo.

O ṣalaye pe awọn eeyan naa sa wọ inu ọkọ ologun lati sa asala fun ẹmi wọn ni, ṣugbọn eyi ko da iku wọn duro.

Iroyin kan tiẹ sọ pe ina mọnamona gbe awọn kan ninu awọn eeyan to ku nigba ti awọn mii si rì somi.

Ṣugbọn ajọ NADMDO ni iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ẹkun omi naa.