#sackFestusAdedayo: Àwọn ọmọ Naijiria kẹ̀yìn si ìyànsípò Festus Adedayo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba lati yan Festus Adedayo gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ feto iroyin fun Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Ahmed Lawan.

Ori ẹrọ ikansiraẹni Twitter n gbona jainjain ni, lati igba ti orukọ Festus Adedayo ti jade wi pe, yoo ba Lawan sisẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ awọn to fesi pẹlu oju opo #sackFestusAdedayo sọ wi pe, arakunrin naa ko ni ẹtọ si ipo naa, nitori o pẹlu awọn alariwisi to ma n kọ iroyin buburu nipa Aarẹ Muhammadu Buhari ati isejọba rẹ, paapa saaju ati lẹyin ibo to kọja.

Awọn ẹlomiran ni, ohun to buru jai ni ki Aarẹ Ile Igbimọ Asofin fi awọn to sisẹ takuntakun fun un lasiko idibo silẹ, lati lọ mu ẹlomiran to tako ẹgbẹ oselu APC.

Nitorinaa ni wọn se ni awọn kọ jalẹ wi pe, ijọba ko gbọdọ fun Festus Adedayo ni ipo kankan.

Awọn miran tilẹ fi awon iroyin ti Adedayọ ti kọ fun awọn ile isẹ iroyin kọọkan han, nibi to ti tako isejọba ẹgbẹ APC to wa lode.

Amọ, lero ti awọn eeyan kan, ijọba ni asẹ lati se ohun to ba wu u, nitori awọn to wa ni ẹgbẹ oselu APC naa jẹ alailotọ, nitori naa ni wọn se lọ mu Festus Adedayo.

Bakan naa ni ẹlomiran gbe e jade wi pe, ko si ohun to jọọ wi pe wọn fẹ fi Festus Adedayo si ipo kankan, ati wi pe Ile Igbimọ Asofin ti gbe orukọ awọn to fẹ ba Lawan sisẹ jade, ti orukọ Adedayọ si ti poora nibẹ.

Amọ lasiko ti a pe FestusAdedayọ, pe ko wa sọ bii ọrọ naa se ri, ko gbe ẹrọ ilewọ rẹ.