Ileẹjọ f'ofin de ṣiṣe ọdun oro laigba'ṣẹ nipinlẹ Ogun

Ile ẹjọ giga kan to n joko nijọba ibilẹ Ipokia nipinlẹ Ogun ti ni bi awọn oloro ṣe n pa ofin konileogbele fun awọn araalu Ipokia ko b'ofin mu.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ kan ti ẹgbẹ ọmọlẹyin kristi (CAN), ati awujọ awọn musulumi ni ilu Ipokia pe lati tako ọdun oro, onidajọ Sikiru Owodunni sọ fun awọn oloro pe wọn ko ni ẹtọ kankan labẹ ofin lati paṣẹ konileogbele fun awọn olugbe Ipokia, Idi-Iroko, Ihunbo, Ifonyintedo, Ogosa, Koko, Ilaṣhe, Ibatefin, Agosasa, Oniru ati Mede.

Ṣaaju ni agbẹjọro fun awọn olupẹjọ, Kayode Samson ati David Folalu ti sọ fun ile ẹjọ wipe awọn ti wọn fi ẹsun kan maa n ṣe ọdun oro wọn ninu igbo laarin oru.

Wọn tẹsiwaju ninu ọrọ wọn pe niṣe ni awọn ọlọdun oro yii nawọ ayẹyẹ wọn de aarin gbungbun awọn ilu yii, ti wọn si n ti itori bẹ paṣẹ konileogbele lọsan gangan fun awọn ara ilu.

Bakanna ni wọn ni igbesẹ yii nṣe idiwọ fun okoowo, ileewe, ile ijọsin, to fi mọ ileeṣẹ ijọba.

Lakotan igbẹjọ naa, Owodunni pa laṣẹ pe aarin oru titi di aago mẹẹrin idaji ni wọn gbọdọ maa ṣe ọdun oro tabi gbe ẹbọ kankan, iyẹn ti awọn alaṣẹ toyẹ ba buwọlu.

Ẹwẹ, ile ẹjọ naa tun ni, wọn yoo ni ki awọn olukopa ninu eto naa fi ọwọ si iwe pe alaafia yoo jọba lasiko ti wọn ba n ṣe ọdun wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: