BUSA19: Bí ètò ìgbéyàwó ààrẹ Buhari kò bá ṣe lọ rèé -àwọn ènìyàn Nàíjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oriṣiiriṣi aworan ati akọle to pani lẹrin lo ti kun ori ayelujara ni eyi ti awọn eniyan fi n ṣeto ipalẹmọ igbeyawo ofege ti wọn ni o yẹ ko waye laarin Aarẹ Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq.

Ṣaaju ni iroyin ẹlẹjẹ ti gba ori ayelujara pe eto igbeyawo naa yoo waye laarin minista tuntun fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede ati aarẹ Naijiria.

Ṣugbọn lẹyin pe gbogbo nkan to n jade lati ọdọ awọn ti ọrọ kan fihan pe irọ to jina si ootọ ni iroyin ẹlẹjẹ naa; sibẹsibẹ ayelujara ti kun fun oriṣiriṣi aworan ati akọle to fihan pe apanilẹrin ni awọn eniyan Naijiria.

Wo diẹ lara akọle ati awọn aworan apanilẹrin to wa lori ayelujara:

Lóòni ni ayẹyẹ ìgbéyàwó ààrẹ Buhari ni'lù Abuja ni eyi ti ero ti n de si Abuja:

Ní bayìí àwọn èèkan ilú, àwọn olóṣèlú àwọn ọmọ Naijiria jákejádo lo ti si nń gúnlẹ̀ sí ìlú Abuja.

Nínú ètò ti yóò wáye ni mọsàlási Jimoh nílùú Abuja lásìkò irún Jimoh toni ní wọn ti maa so wọn pọ.

Láìpẹ́ yìí ìròyìn kan déedé bẹ̀rẹ̀ si ni ja rainrain lójú opó twitter pe ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàijíríà Muhammadu Buhari yóò fẹ́ ìyàwó tuntun sáàfin.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn yìí ko fẹ́sẹ̀ múlẹ, ti ko si si oun a ri gbámu kankan níbẹ̀, ọ̀pọ ọmọ Naijiria ti pari bi gbogbo ǹkan yóò ṣe lọ leto leto.

Oko iyawo ti n mura bayii:

Láti ori ìwé ìpè àlejo tó si mo adari ètò ounjé, àti adari ounjẹ ní wọ́n ti fóju wọ́n han bàyìí:

Nínú ètò ti yóò wáye ni mọsàlási Jimoh nílùú Abuja lásìkò irún Jimoh toni ní wọn ti maa so wọn pọ.

Awọn alejo miran ti awọn eniyan n ṣe awada pe o ti de sibi eto naa ni:

Ayẹyẹ yiìí ko yọ Trump silẹ bi o se fí ohun ránsẹ pé òun ko ni le raye wá.

Àwọn tí ìbàdan, ní ìpínlẹ̀ Oyo, Porthacourt àti Imo

Ọkọ ìyàwọ ti de nínú ọkọ bọginin rẹ̀ ti àwọn alábarin àti olólùfẹ́ rẹ̀ si n wọ́ tẹ̀le.

Wọn ni asọ ti yóò lé wọ òde ìgbéyawo náà ni Pepper-dem àtio wailers White

Ìyá Micho àti awọn alágbàse míràn lo soju nibi iyẹyẹ náà

Alaga idúro fú ìdíle ayẹyẹ igbeyawo náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni pẹrẹwu

Gbogbo elere fún ayẹyẹ naa ooo

Awọn asọna fun ayẹyẹ igbeyawo naa

Minisita fun ere idaraya tẹlẹ ni odẹ aperin ti yóò pese gbogbẹlan ti wan nilo.

Awọn ọmọ Naijiria ba fi fidio bi igbeyawo naa ṣe lọ sita pe:

E seun ti ẹ wa, ẹbun àmurele rèé fun gbogbo awọn ti wan wa fun ayẹyẹ igbéyawo yìí:

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Èmi kò fẹ́ Aàrẹ Buhari o- Sadiya Umar Farouq

Lati bii ọjọ mẹta kan ni iroyin ti gba ori ayelujara kan pe Aarẹ Muhammadu Buhari to n tukọ Naijiria fẹ gbe iyawo miran le Ayisha aya rẹ.

Nigba ti Ileeṣẹ BBC kan si awọn ti ọrọ kan naa ni wọn fidiẹ mulẹ pe iroyin ẹlẹjẹ ni o.

Eni ti a ba sọrọ ni ọdọ Hajiya Sadiya Umar Farouq to jẹ minista tuntun tijọba Buhari yan fun ileeṣẹ ijọba apapọ tuntun ni Abuja ni Hajiya Sadiya wa ni Geneva bayii ni eyi to fihan pe irọ pata to jina si otitọ ni ọrọ naa.

Oṣu kẹjọ, Ọdun 2019 lo di Minisita fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede yii Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari fẹ́ yàn sípò minista.

Kini ootọ inu Fidio ti Ayisha ti n binu to n tan lori ayelujara bayii?

Nigba ti BBC bere nipa fidio to ṣafihan Ayisha to n binu lori ayelujara, pe:

" ........ Kini o de ti o fi n ti lẹkun?....... A ni o le nigba awọn ọmọ ogun ni Aso Rock yatọ si igba ọlọpaa to n ṣọ wa.....O to gẹ........ awọn oponu dede...."

Bakan naa ni ẹni ti BBC ba sọrọ nile iṣẹ aarẹ to ni ki a ma darukọ oun ṣalaye pe irọ to jina si ootọ ni pe wọn dé aya aarẹ Buhari, Aisha mọ́lé ninu Aso Rock.

Ọkan lara awọn oluranlọwọ Aisha Buhari ti BBC ba sọrọ naa ṣalaye pe fidio naa ti pẹ.

O ni fidio naa kii ṣe ohun to n ṣẹlẹ bayii rara.

Ati pe irọ ni ohun ti wọn n sọ lori ayelujara pe Aisha de pẹlu ibinu si Aso Rock ni ana.

Nipari o ni Ayisha Buhari ti lọ si London lati bii oṣu mẹrin sẹyin ni eyi ti o ni nitootọ ni irinajo yii ti n fa wahala diẹdiẹ laarin aarẹ Buhari ati Aisha aya rẹ.

Sadiya Umar Farouq ti wọn pori ẹ ninu ọrọ yii paapaa ni oun ko si ni Naijiria lasiko yii nitori o ti ba ọrọ bi yoo ṣe dara lọ si Geneva lati bii ọjọ melo sẹyin.